Ẹ́kísódù 34:1-35

34  Lẹ́yìn náà, Jèhófà wí fún Mósè pé: “Gbẹ́ wàláà òkúta méjì fún ara rẹ bí ti àkọ́kọ́,+ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó fara hàn lórí àwọn wàláà àkọ́kọ́,+ èyí tí ìwọ fọ́ túútúú,+ ni èmi yóò sì kọ sórí àwọn wàláà náà.  Sì múra sílẹ̀ de òwúrọ̀, nítorí ìwọ yóò gòkè lọ ní òwúrọ̀ sí Òkè Ńlá Sínáì, kí o sì dúró níwájú mi níbẹ̀ ní orí òkè ńlá náà.+  Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ bá ọ gòkè lọ, àti pé, bákan náà, kí a má ṣe rí ẹnikẹ́ni mìíràn ní gbogbo òkè ńlá náà.+ Jù bẹ́ẹ̀ lọ, agbo ẹran tàbí ọ̀wọ́ ẹran kankan kò gbọ́dọ̀ jẹ koríko ní iwájú òkè ńlá yẹn.”+  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Mósè gbẹ́ wàláà òkúta méjì bí ti àkọ́kọ́, ó sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ó sì gòkè lọ sí Òkè Ńlá Sínáì, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún un, ó sì mú wàláà òkúta méjì náà lọ́wọ́.  Jèhófà sì sọ̀ kalẹ̀ wá+ nínú àwọsánmà, ó sì dúró tì í níbẹ̀, ó sì polongo orúkọ Jèhófà.+  Jèhófà sì kọjá níwájú rẹ̀ ní pípolongo pé: “Jèhófà, Jèhófà, Ọlọ́run aláàánú+ àti olóore ọ̀fẹ́,+ ó ń lọ́ra láti bínú,+ ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́+ àti òtítọ́,+  ó ń pa inú-rere-onífẹ̀ẹ́ mọ́ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún,+ ó ń dárí ìṣìnà àti ìrélànàkọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ jì,+ ṣùgbọ́n lọ́nàkọnà, kì í dáni sí láìjẹni-níyà,+ ó ń mú ìyà wá sórí àwọn ọmọ àti sórí àwọn ọmọ-ọmọ, sórí ìran kẹta àti sórí ìran kẹrin nítorí ìṣìnà àwọn baba.”+  Lójú-ẹsẹ̀, Mósè yára tẹrí ba mọ́lẹ̀, ó sì wólẹ̀.+  Lẹ́yìn náà, ó wí pé: “Wàyí o, bí mo bá rí ojú rere ní ojú rẹ, Jèhófà, jọ̀wọ́, jẹ́ kí Jèhófà máa bá wa lọ láàárín wa,+ nítorí pé wọ́n jẹ́ ọlọ́rùn-líle,+ kí o sì dárí ìṣìnà wa àti ẹ̀ṣẹ̀ wa jì,+ kí o sì mú wa gẹ́gẹ́ bí ohun ìní rẹ.”+ 10  Ẹ̀wẹ̀, òun wí pé: “Kíyè sí i, èmi yóò dá májẹ̀mú kan: Níwájú gbogbo ènìyàn rẹ ni èmi yóò ti ṣe àwọn ohun àgbàyanu tí a kò tíì dá rí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tàbí láàárín gbogbo orílẹ̀-èdè;+ gbogbo ènìyàn tí o wà ní àárín wọn yóò sì rí iṣẹ́ Jèhófà ní tòótọ́, nítorí pé ohun amúnikún-fún-ẹ̀rù ni èmi yóò ṣe fún ọ.+ 11  “Ní tìrẹ, pa ohun tí mo ń pa láṣẹ fún ọ lónìí mọ́.+ Kíyè sí i, èmi yóò lé àwọn Ámórì àti àwọn ọmọ Kénáánì àti àwọn ọmọ Hétì àti àwọn Pérísì àti àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì+ jáde kúrò níwájú rẹ. 12  Ṣọ́ ara rẹ kí o má ṣe bá àwọn olùgbé ilẹ̀ tí ìwọ ń lọ+ dá májẹ̀mú, kí ó má bàa di ìdẹkùn ní àárín rẹ.+ 13  Ṣùgbọ́n kí ẹ bi àwọn pẹpẹ wọn wó, kí ẹ sì fọ́ àwọn ọwọ̀n ọlọ́wọ̀ wọn túútúú, kí ẹ sì gé àwọn òpó ọlọ́wọ̀ wọn lulẹ̀.+ 14  Nítorí ìwọ kò gbọ́dọ̀ wólẹ̀ fún ọlọ́run mìíràn,+ nítorí Jèhófà, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Owú, Ọlọ́run owú ni;+ 15  kí ìwọ má bàa bá àwọn olùgbé ilẹ̀ náà dá májẹ̀mú, nítorí ó dájú pé wọn yóò ní ìbádàpọ̀ oníṣekúṣe pẹ̀lú àwọn ọlọ́run wọn,+ wọn yóò sì rúbọ sí àwọn ọlọ́run wọn,+ dájúdájú, ẹnì kan yóò sì ké sí ọ, ó sì dájú pé ìwọ yóò jẹ lára ẹbọ rẹ̀.+ 16  Lẹ́yìn náà, ìwọ yóò mú lára àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin rẹ,+ dájúdájú, àwọn ọmọbìnrin wọn yóò sì ní ìbádàpọ̀ oníṣekúṣe pẹ̀lú àwọn ọlọ́run wọn, wọn yóò sì mú kí àwọn ọmọkùnrin rẹ ní ìbádàpọ̀ oníṣekúṣe pẹ̀lú àwọn ọlọ́run wọn.+ 17  “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe àwọn ọlọ́run òrìṣà dídà fún ara rẹ.+ 18  “Àjọyọ̀ àkàrà aláìwú ni kí o pa mọ́.+ Ìwọ yóò jẹ àkàrà aláìwú, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti pàṣẹ fún ọ, fún ọjọ́ méje ní àkókò tí a yàn kalẹ̀ ní oṣù Ábíbù,+ nítorí pé oṣù Ábíbù ni o jáde kúrò ní Íjíbítì. 19  “Ohun gbogbo tí ó bá kọ́kọ́ ṣí ilé ọlẹ̀ jẹ́ tèmi,+ àti pé, ní ti gbogbo ẹran ọ̀sìn rẹ, akọ tí ó jẹ́ àkọ́bí nínú àwọn akọ màlúù àti àwọn àgùntàn.+ 20  Àkọ́bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni kí o sì fi àgùntàn tún rà padà.+ Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá ní tún un rà padà, nígbà náà, kí o ṣẹ́ ọrùn rẹ̀. Olúkúlùkù àkọ́bí nínú àwọn ọmọkùnrin rẹ ni kí ìwọ tún rà padà.+ Wọn kò sì gbọ́dọ̀ fara hàn níwájú mi lọ́wọ́ òfo.+ 21  “Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò fi ṣe òpò, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ keje, ìwọ yóò pa sábáàtì mọ́.+ Nígbà ìtúlẹ̀ àti ìkórè, ìwọ yóò pa sábáàtì mọ́.+ 22  “Ìwọ yóò sì máa bá a lọ ní ṣíṣe àjọyọ̀ àwọn ọ̀sẹ̀ rẹ pẹ̀lú àkọ́pọ́n èso ìkórè àlìkámà,+ àti àjọyọ̀ ìkórèwọlé nígbà tí ọdún bá yí po.+ 23  “Ìgbà mẹ́ta lọ́dún ni kí olúkúlùkù ọkùnrin tí ó jẹ́ tìrẹ fara hàn+ níwájú Olúwa tòótọ́, Jèhófà, Ọlọ́run Ísírẹ́lì. 24  Nítorí èmi yóò lé àwọn orílẹ̀-èdè kúrò níwájú rẹ,+ èmi yóò sì mú ìpínlẹ̀ rẹ láyè tí ó gbòòrò;+ ojú ẹnikẹ́ni kì yóò sì wọ ilẹ̀ rẹ nígbà tí ìwọ bá ń gòkè lọ láti rí ojú Jèhófà Ọlọ́run ní ìgbà mẹ́ta lọ́dún.+ 25  “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ pa ẹ̀jẹ̀ ẹbọ mi pẹ̀lú ohun tí ó ní ìwúkàrà.+ Ẹbọ àjọyọ̀ ìrékọjá kò sì gbọ́dọ̀ wà láti òru títí di òwúrọ̀.+ 26  “Èyí tí ó dára jù lọ nínú àkọ́pọ́n èso+ ilẹ̀ rẹ ni ìwọ yóò mú wá sí ilé Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+ “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ se ọmọ ẹran nínú wàrà ìyá rẹ̀.”+ 27  Jèhófà sì ń bá a lọ láti wí fún Mósè pé: “Kọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sílẹ̀ fún ara rẹ,+ nítorí ní ìbámú pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni mo bá ìwọ àti Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú.”+ 28  Ó sì ń bá a lọ láti wà níbẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru. Kò jẹ oùnjẹ, kò sì mu omi.+ Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ ọ̀rọ̀ májẹ̀mú náà sára àwọn wàláà náà, Ọ̀rọ̀ Mẹ́wàá náà.+ 29  Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí Mósè sọ̀ kalẹ̀ láti orí Òkè Ńlá Sínáì, wàláà méjì ti Gbólóhùn Ẹ̀rí wà ní ọwọ́ Mósè nígbà tí ó sọ̀ kalẹ̀ láti orí òkè ńlá náà,+ Mósè kò sì mọ̀ pé awọ ojú òun ń mú ìtànṣán jáde nítorí bíbá tí ó bá a sọ̀rọ̀.+ 30  Nígbà tí Áárónì àti gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì rí Mósè, họ́wù, wò ó! awọ ojú rẹ̀ mú ìtànṣán jáde, wọ́n sì fòyà láti sún mọ́ ọn.+ 31  Mósè sì bẹ̀rẹ̀ sí pè wọ́n. Nítorí náà, Áárónì àti gbogbo ìjòyè nínú àpéjọ náà padà sọ́dọ̀ rẹ̀, Mósè sì bẹ̀rẹ̀ sí bá wọn sọ̀rọ̀. 32  Kéte lẹ́yìn ìyẹn, gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì sún mọ́ ọn, gbogbo ohun tí Jèhófà bá a sọ lórí Òkè Ńlá Sínáì+ ni ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pa láṣẹ fún wọn. 33  Nígbà tí Mósè bá parí bíbá wọn sọ̀rọ̀, òun a fi ìbòjú bo ojú rẹ̀.+ 34  Ṣùgbọ́n nígbà tí Mósè bá wọlé síwájú Jèhófà láti bá a sọ̀rọ̀, òun a mú ìbòjú kúrò títí yóò fi jáde kúrò.+ Òun a sì jáde lọ, a sì sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa ohun tí a pa láṣẹ fún un.+ 35  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì rí ojú Mósè, pé awọ ojú Mósè mú ìtànṣán jáde;+ Mósè sì fi ìbòjú náà bo ojú rẹ̀ padà títí ó fi wọlé lọ bá a sọ̀rọ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé