Ẹ́kísódù 30:1-38

30  “Kí o sì ṣe pẹpẹ kan gẹ́gẹ́ bí ibì kan fún sísun tùràrí;+ igi bọn-ọ̀n-ní ni kí o fi ṣe é.  Ìgbọ̀nwọ́ kan ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ kan ní fífẹ̀, kí ó jẹ́ igun mẹ́rin lọ́gbọọgba, kí gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì. Àwọn ìwo rẹ̀ yọ jáde lára rẹ̀.+  Kí o sì fi ògidì wúrà bò ó, òkè rẹ̀ àti àwọn ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ yí ká àti àwọn ìwo rẹ̀; kí o sì ṣe ìgbátí wúrà sí i yí ká.+  Ìwọ yóò sì tún ṣe òrùka wúrà méjì sí i. Ní ìsàlẹ̀ ìgbátí rẹ̀ lára méjì nínú àwọn ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ni ìwọ yóò ṣe wọ́n sí, ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ méjèèjì tí ó dojú kọra, nítorí wọn yóò jẹ́ ohun tí yóò di àwọn ọ̀pá náà mú, tí a ó fi máa gbé e.+  Kí o sì ṣe àwọn ọ̀pá igi bọn-ọ̀n-ní, kí o sì fi wúrà bò wọ́n.+  Kí o sì gbé e síwájú aṣọ ìkélé tí ó wà nítòsí àpótí gbólóhùn ẹ̀rí,+ níwájú ìbòrí tí ó wà lórí Gbólóhùn Ẹ̀rí, níbi tí èmi yóò ti máa pàdé rẹ.+  “Kí Áárónì sì mú tùràrí onílọ́fínńdà+ rú èéfín lórí rẹ̀.+ Ní òròòwúrọ̀, nígbà tí ó bá múra àwọn fìtílà sílẹ̀ fún lílò,+ òun yóò mú un rú èéfín.  Nígbà tí Áárónì bá sì tan àwọn fìtílà láàárín ìrọ̀lẹ́ méjèèjì, òun yóò mú un rú èéfín. Ó jẹ́ tùràrí ìgbà gbogbo níwájú Jèhófà ní ìran-ìran yín.  Ẹ kò gbọ́dọ̀ fi tùràrí tàbí ọrẹ ẹbọ sísun tàbí ọrẹ ẹbọ ọkà aláìbá-ìlànà-mu+ rúbọ lórí rẹ̀; ẹ kò sì gbọ́dọ̀ da ọrẹ ẹbọ ohun mímu sórí rẹ̀. 10  Kí Áárónì sì máa ṣe ètùtù lórí ìwo rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan lọ́dún.+ Òun yóò mú lára ẹ̀jẹ̀ ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀+ ti ètùtù náà ṣe ètùtù fún un lẹ́ẹ̀kan lọ́dún ní ìran-ìran yín. Mímọ́ jù lọ ni lójú Jèhófà.” 11  Jèhófà sì ń bá a lọ láti sọ fún Mósè, pé: 12  “Nígbàkigbà tí ìwọ bá ka iye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí kíka iye wọn,+ nígbà náà, kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn tìtorí ọkàn rẹ̀ fi ìràpadà fún Jèhófà nígbà tí a bá ń ka iye wọn,+ kí ìyọnu àjàkálẹ̀ kankan má bàa wá sórí wọn nígbà tí a bá ń ka iye wọn.+ 13  Èyí ni ohun tí gbogbo àwọn tí ó kọjá sínú àwọn tí a ka iye wọn yóò mú wá: ààbọ̀ ṣékélì gẹ́gẹ́ bí ṣékélì ibi mímọ́.+ Ogún òṣùwọ̀n gérà ni ṣékélì kan. Ààbọ̀ ṣékélì ni ọrẹ fún Jèhófà.+ 14  Olúkúlùkù ẹni tí ó kọjá sínú àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ láti ẹni ogún ọdún sókè yóò mú ọrẹ Jèhófà+ wá. 15  Ọlọ́rọ̀ kò gbọ́dọ̀ mú ohun tí ó pọ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ wá, ẹni rírẹlẹ̀ kò sì gbọ́dọ̀ mú ohun tí ó kéré sí ààbọ̀ ṣékélì+ wá, láti lè mú ọrẹ Jèhófà wá, kí a bàa lè ṣe ètùtù fún ọkàn yín.+ 16  Kí o sì gba owó fàdákà ètùtù lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí o sì mú un wá nítorí iṣẹ́ ìsìn àgọ́ ìpàdé,+ kí ó lè jẹ́ ìrántí níwájú Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, láti ṣe ètùtù fún ọkàn yín.” 17  Jèhófà sì sọ fún Mósè síwájú sí i, pé: 18  “Kí o fi bàbà ṣe bàsíà kan, kí o sì fi bàbà ṣe ẹsẹ̀ rẹ̀ fún wíwẹ̀,+ kí o sì gbé e sáàárín àgọ́ ìpàdé àti pẹpẹ, kí o sì bu omi sínú rẹ̀.+ 19  Kí Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì máa wẹ ọwọ́ wọn àti ẹsẹ̀ wọn níbẹ̀.+ 20  Nígbà tí wọ́n bá lọ sínú àgọ́ ìpàdé, wọn yóò fi omi wẹ̀, kí wọ́n má bàa kú, tàbí nígbà tí wọ́n bá sún mọ́ pẹpẹ láti ṣe ìránṣẹ́ láti lè mú ọrẹ ẹbọ àfinásun rú èéfín sí Jèhófà.+ 21  Kí wọ́n sì máa wẹ ọwọ́ wọn àti ẹsẹ̀ wọn, kí wọ́n má bàa kú,+ kí ó sì jẹ́ ìlànà fún wọn fún àkókò tí ó lọ kánrin, fún òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ jálẹ̀ ìran-ìran wọn.”+ 22  Jèhófà sì ń bá a lọ láti sọ fún Mósè, pé: 23  “Ní tìrẹ, mú lọ́fínńdà tí ó jẹ́ ààyò jù lọ+ fún ara rẹ: ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ìwọ̀n òjíá+ ní àwọn ẹ̀kán dídì, àti igi sínámónì+ dídùn ní ìdajì iye yẹn, àádọ́ta-lérúgba ìwọ̀n, àti àádọ́ta-lérúgba ìwọ̀n ewéko kálámọ́sì+ dídùn, 24  àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ìwọ̀n igi kaṣíà+ gẹ́gẹ́ bí ṣékélì ibi mímọ́,+ àti òróró ólífì òṣùwọ̀n hínì kan.+ 25  Lẹ́yìn náà, kí o fi í ṣe òróró mímọ́ àfiyanni, òróró ìkunra, àdàlù tí ó jẹ́ iṣẹ́ olùṣe òróró ìkunra.+ Yóò jẹ́ òróró mímọ́ àfiyanni.+ 26  “Kí o sì fòróró rẹ̀ yan àgọ́ ìpàdé+ àti àpótí gbólóhùn ẹ̀rí, 27  àti tábìlì àti gbogbo nǹkan èlò rẹ̀ àti ọ̀pá fìtílà àti àwọn nǹkan èlò rẹ̀ àti pẹpẹ tùràrí, 28  àti pẹpẹ ọrẹ ẹbọ sísun àti gbogbo nǹkan èlò rẹ̀ àti bàsíà àti ẹsẹ̀ rẹ̀. 29  Kí o sì sọ wọ́n di mímọ́ kí wọ́n lè di mímọ́ jù lọ+ ní ti gidi. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kàn wọ́n ní láti jẹ́ mímọ́.+ 30  Ìwọ yóò sì fòróró yan Áárónì+ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀,+ kí o sì sọ wọ́n di mímọ́ fún ṣíṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà fún mi.+ 31  “Ìwọ yóò sì sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, pé, ‘Èyí yóò máa bá a lọ láti jẹ́ òróró mímọ́ àfiyanni fún mi ní ìran-ìran yín.+ 32  Aráyé kò gbọ́dọ̀ fi pa ara, ẹ kò sì gbọ́dọ̀ fi èròjà rẹ̀ ṣe èyíkéyìí bí rẹ̀. Ohun mímọ́ ni. Kí ó máa bá a lọ láti jẹ́ ohun mímọ́ fún yín. 33  Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe òróró ìkunra bí rẹ̀, tí ó sì fi nínú rẹ̀ sára àjèjì ni a óò ké kúrò láàárín àwọn ènìyàn rẹ̀.’”+ 34  Jèhófà sì ń bá a lọ láti sọ fún Mósè pé: “Mú àwọn lọ́fínńdà+ fún ara rẹ: àwọn ẹ̀kán sítákítè àti ọ́níkà àti gábánọ́mù onílọ́fínńdà àti ògidì oje igi tùràrí.+ Ìpín kan náà ni kí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́. 35  Kí ìwọ sì fi í ṣe tùràrí,+ àdàlù èròjà atasánsán, iṣẹ́ olùṣe òróró ìkunra, tí a fi iyọ̀ sí,+ ògidì, ohun mímọ́. 36  Kí o sì gún lára rẹ̀ di ekuru lẹ́búlẹ́bú, kí o sì bù lára rẹ̀ síwájú Gbólóhùn Ẹ̀rí inú àgọ́ ìpàdé,+ níbi tí èmi yóò ti máa pàdé rẹ.+ Kí ó jẹ́ mímọ́ jù lọ lójú yín. 37  Àti pé tùràrí tí ìwọ yóò fi èròjà yìí ṣe, ni ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe fún ara yín.+ Kí ó máa bá a lọ fún ọ láti jẹ́ ohun mímọ́ lójú Jèhófà.+ 38  Ẹnì yòówù tí ó bá ṣe èyíkéyìí bí rẹ̀ láti gbádùn òórùn rẹ̀ ni a óò ké kúrò+ láàárín àwọn ènìyàn rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé