Ẹ́kísódù 3:1-22

3  Mósè sì di olùṣọ́ àgùntàn fún agbo ẹran Jẹ́tírò,+ àlùfáà Mídíánì, ẹni tí òun jẹ́ ọkọ ọmọ rẹ̀.+ Bí ó ti ń da agbo ẹran náà lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn aginjù, nígbà tí ó ṣe, ó dé Hórébù,+ òkè ńlá Ọlọ́run tòótọ́.+  Nígbà náà ni áńgẹ́lì Jèhófà fara hàn án nínú ọwọ́ iná ní àárín igi kékeré ẹlẹ́gùn-ún.+ Bí ó ti ń wò ó, họ́wù, kíyè sí i, iná ń jó nínú igi kékeré ẹlẹ́gùn-ún náà, síbẹ̀ igi kékeré ẹlẹ́gùn-ún náà kò sì jó.  Látàrí èyí, Mósè wí pé: “Jẹ́ kí n kúkú yà, kí n lè ṣàyẹ̀wò ohun àrà ńlá yìí, ní ti ìdí tí igi kékeré ẹlẹ́gùn-ún náà kò fi jó.”+  Nígbà tí Jèhófà rí i pé ó yà láti ṣàyẹ̀wò, lójú-ẹsẹ̀, Ọlọ́run pè é láti àárín igi kékeré ẹlẹ́gùn-ún náà wí pé: “Mósè! Mósè!” ó dáhùn pé: “Èmi nìyí.”+  Nígbà náà, ó wí pé: “Má ṣe sún mọ́ ìhín. Bọ́ sálúbàtà rẹ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ, nítorí pé ilẹ̀ mímọ́ ni ibi tí ìwọ dúró sí.”+  Ó sì ń bá a lọ láti wí pé: “Èmi ni Ọlọ́run baba rẹ, Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísákì àti Ọlọ́run Jékọ́bù.”+ Nígbà náà ni Mósè fi ojú rẹ̀ pa mọ́, nítorí pé àyà fò ó láti wo Ọlọ́run tòótọ́.  Jèhófà sì fi kún un pé: “Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, mo ti rí ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ àwọn ènìyàn mi tí ń bẹ ní Íjíbítì níṣẹ̀ẹ́, mo sì ti gbọ́ igbe ẹkún wọn nítorí àwọn tí ń kó wọn ṣiṣẹ́; nítorí tí mo mọ ìrora tí wọ́n ń jẹ ní àmọ̀dunjú.+  Èmi ń sọ̀ kalẹ̀ lọ láti dá wọn nídè kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì,+ kí n sì mú wọn gòkè wá láti ilẹ̀ yẹn sí ilẹ̀ kan tí ó dára tí ó sì ní àyè gbígbòòrò, sí ilẹ̀ kan tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin,+ sí àdúgbò àwọn ọmọ Kénáánì àti àwọn ọmọ Hétì àti àwọn Ámórì àti àwọn Pérísì àti àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì.+  Sì wò ó! nísinsìnyí, igbe ẹkún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti dé ọ̀dọ̀ mi, mo sì ti rí ìnilára tí àwọn ará Íjíbítì fi ń ni wọ́n lára.+ 10  Sì wá nísinsìnyí, jẹ́ kí n rán ọ sí Fáráò, kí o sì mú àwọn ènìyàn mi àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì.”+ 11  Bí ó ti wù kí ó rí, Mósè wí fún Ọlọ́run tòótọ́ pé: “Ta ni èmi tí èmi yóò fi lọ bá Fáráò, tí n ó sì fi mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì?”+ 12  Ó fèsì pé: “Nítorí pé èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ,+ èyí sì ni àmì fún ọ pé èmi ni ó rán ọ:+ Lẹ́yìn tí o bá ti mú àwọn ènìyàn náà jáde kúrò ní Íjíbítì, ẹ ó sin Ọlọ́run tòótọ́ lórí òkè ńlá yìí.”+ 13  Síbẹ̀síbẹ̀, Mósè wí fún Ọlọ́run tòótọ́ pé: “Ká ní mo wá dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí mo sì sọ fún wọn pé, ‘Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín ni ó rán mi sí yín,’ tí wọ́n sì sọ fún mi pé, ‘Kí ni orúkọ rẹ̀?’+ Kí ni èmi yóò sọ fún wọn?” 14  Látàrí èyí, Ọlọ́run sọ fún Mósè pé: “ÈMI YÓÒ JẸ́ OHUN TÍ ÈMI YÓÒ JẸ́.”+ Ó sì fi kún un pé: “Èyí ni ohun tí ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ‘ÈMI YÓÒ JẸ́ ti rán mi sí yín.’”+ 15  Nígbà náà ni Ọlọ́run sọ fún Mósè lẹ́ẹ̀kan sí i pé: “Èyí ni ohun tí ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ‘Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín, Ọlọ́run Ábúráhámù,+ Ọlọ́run Ísákì+ àti Ọlọ́run Jékọ́bù,+ ni ó rán mi sí yín.’ Èyí ni orúkọ mi fún àkókò tí ó lọ kánrin,+ èyí sì ni ìrántí mi láti ìran dé ìran.+ 16  Ìwọ lọ, kí o sì kó àwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì jọ, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín ti fara hàn mí,+ Ọlọ́run Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù, pé: “Dájúdájú, láìkùnà, èmi yóò fún ẹ̀yin àti ohun tí a ń ṣe sí yín ní Íjíbítì ní àfiyèsí.+ 17  Nítorí náà ni mo sì ṣe wí pé, èmi yóò mú yín kúrò nínú ìṣẹ́ni-níṣẹ̀ẹ́+ láti ọwọ́ àwọn ará Íjíbítì láti gòkè lọ sí ilẹ̀ àwọn ọmọ Kénáánì àti àwọn ọmọ Hétì àti àwọn Ámórì+ àti àwọn Pérísì àti àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì,+ sí ilẹ̀ kan tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin.”’+ 18  “Dájúdájú, wọn yóò sì fetí sí ohùn rẹ,+ ìwọ yóò sì wá, ìwọ àti àwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì, sọ́dọ̀ ọba Íjíbítì, ẹ ó sì wí fún un pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run àwọn Hébérù+ ti kàn sí wa,+ wàyí o, jọ̀wọ́, àwa fẹ́ lọ ìrìn àjò ọlọ́jọ́ mẹ́ta sí aginjù, a sì fẹ́ rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run wa.’+ 19  Èmi, àní èmi, sì mọ̀ dáadáa pé ọba Íjíbítì kì yóò gbà yín láyè láti lọ àyàfi nípa ọwọ́ líle.+ 20  Èmi yóò sì ní láti na ọwọ́ mi jáde,+ kí n sì kọlu Íjíbítì pẹ̀lú gbogbo ìṣe àgbàyanu mi tí èmi yóò ṣe ní àárín rẹ̀; lẹ́yìn ìyẹn, òun yóò sì rán yín jáde.+ 21  Dájúdájú, èmi yóò fi ojú rere fún àwọn ènìyàn yìí ní ojú àwọn ará Íjíbítì; dájúdájú, yóò sì ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí ẹ bá ń lọ, ẹ kì yóò lọ lọ́wọ́ òfo.+ 22  Olúkúlùkù obìnrin yóò sì béèrè àwọn ohun èlò fàdákà àti àwọn ohun èlò wúrà àti àwọn aṣọ àlàbora lọ́wọ́ aládùúgbò rẹ̀ àti lọ́wọ́ obìnrin tí ń ṣe àtìpó ní ilé rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì fi wọ́n sára àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin yín; ẹ̀yin yóò sì gba tọwọ́ àwọn ará Íjíbítì.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé