Ẹ́kísódù 24:1-18
24 Ó sì wí fún Mósè pé: “Gòkè lọ sọ́dọ̀ Jèhófà, ìwọ àti Áárónì, Nádábù àti Ábíhù+ àti àádọ́rin+ lára àwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì, kí ẹ sì tẹrí ba láti òkèèrè.
2 Kí Mósè nìkan sì sún mọ́ Jèhófà; ṣùgbọ́n àwọn kò gbọ́dọ̀ sún mọ́ tòsí, kí àwọn ènìyàn náà má sì gòkè lọ pẹ̀lú rẹ̀.”+
3 Lẹ́yìn náà, Mósè dé, ó sì ṣèròyìn gbogbo ọ̀rọ̀ Jèhófà àti gbogbo ìpinnu ìdájọ́+ fún àwọn ènìyàn náà, gbogbo àwọn ènìyàn náà sì dáhùn ní ohùn kan, wọ́n sì wí pé: “Gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ ni àwa múra tán láti ṣe.”+
4 Nítorí náà, Mósè ṣe àkọsílẹ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ Jèhófà.+ Lẹ́yìn náà, ó dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ó sì mọ pẹpẹ kan sí ẹsẹ̀ òkè ńlá náà àti ọwọ̀n méjìlá tí ó bá ẹ̀yà méjìlá Ísírẹ́lì ṣe rẹ́gí.+
5 Lẹ́yìn ìyẹn, ó rán àwọn ọ̀dọ́kùnrin nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì rú àwọn ọrẹ ẹbọ sísun, wọ́n sì fi àwọn akọ màlúù rúbọ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ, gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹbọ ìdàpọ̀+ sí Jèhófà.
6 Lẹ́yìn náà, Mósè mú ìdajì ẹ̀jẹ̀ náà, ó sì fi í sínú àwọn àwokòtò,+ ó sì wọ́n ìdajì ẹ̀jẹ̀ náà sára pẹpẹ.+
7 Níkẹyìn, ó mú ìwé májẹ̀mú,+ ó sì kà á ní etí àwọn ènìyàn náà.+ Nígbà náà, wọ́n wí pé: “Gbogbo ohun tí Jèhófà sọ ni àwa múra tán láti ṣe, a ó sì jẹ́ onígbọràn.”+
8 Nítorí náà, Mósè mú ẹ̀jẹ̀ náà, ó sì wọ́n ọn sára àwọn ènìyàn naa,+ ó sì wí pé: “Ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú+ náà rèé tí Jèhófà bá yín dá ní ti gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.”
9 Mósè àti Áárónì, Nádábù àti Ábíhù àti àádọ́rin lára àwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí gòkè lọ,
10 wọ́n sì rí Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+ Abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀ sì ni ohun kan wà tí ó dà bí iṣẹ́ ọnà òkúta sàfáyà palaba-palaba àti ohun tí ó dà bí ọ̀run gan-an ní ti ìmọ́gaara.+
11 Òun kò sì na ọwọ́ rẹ̀ lòdì sí àwọn sàràkí ọkùnrin lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ ṣùgbọ́n wọ́n rí ìran Ọlọ́run tòótọ́,+ wọ́n sì jẹ, wọ́n sì mu.+
12 Wàyí o, Jèhófà wí fún Mósè pé: “Gòkè wá sọ́dọ̀ mi lórí òkè ńlá, kí o sì dúró sí ibẹ̀, nítorí mo fẹ́ fún ọ ní àwọn wàláà òkúta àti òfin àti àṣẹ tí èmi yóò kọ láti kọ́ wọn.”+
13 Nítorí náà, Mósè àti Jóṣúà òjíṣẹ́ rẹ̀ dìde, Mósè sì gòkè lọ sórí òkè ńlá Ọlọ́run tòótọ́.+
14 Ṣùgbọ́n àwọn àgbà ọkùnrin ni ó wí fún pé: “Ẹ dúró dè wá ní ibí yìí títí a ó fi padà sọ́dọ̀ yín.+ Sì wò ó! Áárónì àti Húrì+ wà pẹ̀lú yín. Ẹnì yòówù tí ó bá ní ẹjọ́ lábẹ́ òfin, kí ó tọ̀ wọ́n lọ.”+
15 Nípa báyìí, Mósè gòkè lọ sórí òkè ńlá bí àwọsánmà ti bo òkè ńlá náà.+
16 Ògo Jèhófà+ sì ń bá a lọ láti wà lórí Òkè Ńlá Sínáì,+ àwọsánmà sì ń bá a lọ láti bò ó fún ọjọ́ mẹ́fà. Nígbà tí ó ṣe, ní ọjọ́ keje, ó pe Mósè láti àárín àwọsánmà náà wá.+
17 Ní ojú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ìrí ògo Jèhófà sì dà bí iná tí ń jẹni run+ ní orí òkè ńlá náà.
18 Nígbà náà, Mósè wọ àárín àwọsánmà náà, ó sì gòkè lọ sórí òkè ńlá náà.+ Mósè sì ń bá a lọ láti wà ní òkè ńlá náà fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru.+

