Ẹ́kísódù 19:1-25

19  Ní oṣù kẹta lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ ní ọjọ́ kan náà, wọ́n dé aginjù Sínáì.+ 2  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣí kúrò ní Réfídímù,+ wọ́n sì wá sí aginjù Sínáì, wọ́n sì dó sí aginjù;+ Ísírẹ́lì sì dó síbẹ̀ ní iwájú òkè ńlá náà.+ 3  Mósè sì gòkè lọ bá Ọlọ́run tòótọ́, Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí pè é láti òkè ńlá náà+ wá, pé: “Èyí ni ohun tí ìwọ yóò wí fún ilé Jékọ́bù, tí ìwọ yóò sì sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, 4  ‘Ẹ̀yin fúnra yín ti rí ohun tí mo ṣe sí àwọn ará Íjíbítì,+ kí èmi lè gbé yín lórí ìyẹ́ apá àwọn idì, kí n sì mú yín wá sọ̀dọ̀ ara mi.+ 5  Wàyí o, bí ẹ̀yin yóò bá ṣègbọràn délẹ̀délẹ̀+ sí ohùn mi, tí ẹ ó sì pa májẹ̀mú mi mọ́ ní ti gidi,+ dájúdájú, nígbà náà, ẹ̀yin yóò di àkànṣe dúkìá mi nínú gbogbo àwọn ènìyàn yòókù,+ nítorí pé, gbogbo ilẹ̀ ayé jẹ́ tèmi.+ 6  Ẹ̀yin fúnra yín yóò sì di ìjọba àwọn àlùfáà àti orílẹ̀-èdè mímọ́+ fún mi.’ Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ tí ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.” 7  Nítorí náà, Mósè wá, ó sì pe àwọn àgbà ọkùnrin+ àwọn ènìyàn náà, ó sì gbé gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí Jèhófà pa láṣẹ fún un kalẹ̀ níwájú wọn.+ 8  Lẹ́yìn ìyẹn, gbogbo àwọn ènìyàn náà ní ìfìmọ̀ṣọ̀kan dáhùn, wọ́n sì wí pé: “Gbogbo ohun tí Jèhófà sọ ni àwa ti múra tán láti ṣe.”+ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Mósè mú ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn náà padà lọ bá Jèhófà.+ 9  Látàrí èyí, Jèhófà wí fún Mósè pé: “Wò ó! Èmi yóò wá sọ́dọ̀ rẹ nínú àwọsánmà ṣíṣú,+ kí àwọn ènìyàn náà bàa lè gbọ́ nígbà tí mo bá ń bá ọ sọ̀rọ̀,+ àti pé kí wọ́n lè ní ìgbàgbọ́ nínú ìwọ pẹ̀lú fún àkókò tí ó lọ kánrin.”+ Lẹ́yìn náà, Mósè ròyìn ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn náà fún Jèhófà. 10  Jèhófà sì ń bá a lọ láti wí fún Mósè pé: “Lọ bá àwọn ènìyàn náà, kí o sì sọ wọ́n di mímọ́ lónìí àti lọ́la, kí wọ́n sì fọ aṣọ àlàbora wọn.+ 11  Kí wọ́n sì wà ní sẹpẹ́ de ọjọ́ kẹta, nítorí pé ní ọjọ́ kẹta, Jèhófà yóò sọ̀ kalẹ̀ lójú gbogbo àwọn ènìyàn náà sórí Òkè Ńlá Sínáì.+ 12  Kí o sì pa ààlà fún àwọn ènìyàn náà yí ká, pé, ‘Ẹ ṣọ́ ara yín láti má ṣe gòkè lọ sórí òkè ńlá náà, kí ẹ má sì fara kan etí rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan òkè ńlá náà ni a ó fikú pa dájúdájú.+ 13  Ọwọ́ kankan kò gbọ́dọ̀ kan ẹni náà, nítorí pé sísọ ni a ó sọ ọ́ lókùúta tàbí gígún ni a óò gún un ní àgúnyọ. Yálà ẹranko ni tàbí ènìyàn, òun kì yóò wà láàyè.’+ Nígbà tí a bá fun ìwo àgbò,+ kí àwọn fúnra wọn gòkè wá sí òkè ńlá náà.” 14  Lẹ́yìn náà, Mósè sọ̀ kalẹ̀ láti orí òkè ńlá náà wá sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn náà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ àwọn ènìyàn náà di mímọ́; wọ́n sì ń fọ aṣọ àlàbora wọn.+ 15  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó wí fún àwọn ènìyàn náà pé: “Ẹ múra sílẹ̀+ ní ọjọ́ mẹ́ta. Kí ẹ̀yin ọkùnrin má ṣe sún mọ́ obìnrin.”+ 16  Ní ọjọ́ kẹta, nígbà tí ó di òwúrọ̀, ó sì ṣẹlẹ̀ pé ààrá sán, mànàmáná sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ,+ àti àwọsánmà ṣíṣú dùdù+ lórí òkè ńlá náà àti ìró ìwo adúnròkè lálá,+ tó bẹ́ẹ̀ tí gbogbo ènìyàn tí ó wà nínú ibùdó fi bẹ̀rẹ̀ sí wárìrì.+ 17  Wàyí o, Mósè mú àwọn ènìyàn náà jáde kúrò ní ibùdó láti pàdé Ọlọ́run tòótọ́, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí mú ìdúró wọn ní ìsàlẹ̀ òkè ńlá náà.+ 18  Òkè Ńlá Sínáì sì rú èéfín káríkárí,+ nítorí òtítọ́ náà pé Jèhófà sọ̀ kalẹ̀ sórí rẹ̀ nínú iná;+ èéfín rẹ̀ sì ń gòkè bí èéfín ẹbu,+ gbogbo òkè ńlá náà sì ń wárìrì gidigidi.+ 19  Nígbà tí ìró ìwo náà túbọ̀ ń dún kíkankíkan láìdáwọ́ dúró, Mósè bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀, Ọlọ́run tòótọ́ sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ohùn dá a lóhùn.+ 20  Nítorí náà, Jèhófà sọ̀ kalẹ̀ sórí Òkè Ńlá Sínáì, sí orí òkè ńlá náà. Nígbà náà ni Jèhófà pe Mósè wá sí orí òkè ńlá náà, Mósè sì gòkè lọ.+ 21  Wàyí o, Jèhófà wí fún Mósè pé: “Sọ̀ kalẹ̀, kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn náà, pé kí wọ́n má ṣe já wá sọ́dọ̀ Jèhófà láti bojú wò ó, tí ọ̀pọ̀ lára wọn yóò sì fi ṣubú.+ 22  Kí o sì jẹ́ kí àwọn àlùfáà pẹ̀lú tí wọ́n ń sún mọ́ Jèhófà déédéé sọ ara wọn di mímọ́,+ kí Jèhófà má bàa kọlù wọ́n.”+ 23  Látàrí èyí, Mósè wí fún Jèhófà pé: “Àwọn ènìyàn náà kò lè gòkè wá sí Òkè Ńlá Sínáì, nítorí pé ìwọ fúnra rẹ ti kìlọ̀ fún wa ṣáájú, pé, ‘Pa ààlà fún òkè ńlá náà, kí o sì ṣe é ní ọlọ́wọ̀.’”+ 24  Bí ó ti wù kí ó rí, Jèhófà wí fún un pé: “Lọ, sọ̀ kalẹ̀, kí o sì gòkè wá, ìwọ àti Áárónì pẹ̀lú rẹ; ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí àwọn àlùfáà àti àwọn ènìyàn náà já gòkè wá sọ́dọ̀ Jèhófà, kí ó má bàa kọlù wọ́n.”+ 25  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Mósè sọ̀ kalẹ̀ lọ bá àwọn ènìyàn náà, ó sì sọ fún wọn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé