Ámósì 3:1-15
3 “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí tí Jèhófà ti sọ nípa yín,+ ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì, nípa gbogbo ìdílé tí mo mú gòkè wá láti ilẹ̀ Íjíbítì,+ pé,
2 ‘Ẹ̀yin nìkan ni mo mọ̀+ nínú gbogbo ìdílé tí ń bẹ lórí ilẹ̀.+ Ìdí nìyẹn tí èmi yóò fi béèrè ìjíhìn lọ́wọ́ yín fún gbogbo ìṣìnà yín.+
3 “‘Àwọn méjì ha lè jọ rìn pọ̀ bí kò ṣe pé wọ́n ti pàdé nípasẹ̀ àdéhùn?+
4 Kìnnìún yóò ha ké ramúramù nínú igbó láìní ẹran ọdẹ lọ́wọ́?+ Ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ yóò ha fọhùn láti ibi ìfarapamọ́ rẹ̀ bí kò bá tíì mú nǹkan kan rárá?
5 Ẹyẹ ha lè kó sí pańpẹ́ lórí ilẹ̀ nígbà tí kò sí ìdẹkùn fún un?+ Pańpẹ́ ha lè ré kúrò lorí ilẹ̀ nígbà tí kò tíì mú nǹkan kan rárá?
6 Bí a bá fun ìwo nínú ìlú ńlá, àwọn ènìyàn kò ha ń wárìrì+ pẹ̀lú bí? Bí ìyọnu àjálù bá ṣẹlẹ̀ nínú ìlú ńlá, kì í ha ṣe Jèhófà ni ó tí gbé ìgbésẹ̀ pẹ̀lú bí?
7 Nítorí pé Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ kì yóò ṣe ohun kan láìjẹ́ pé ó ti ṣí ọ̀ràn àṣírí rẹ̀ payá fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì.+
8 Kìnnìún kan wà tí ó ti ké ramúramù!+ Ta ni kì yóò fòyà? Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ tìkára rẹ̀ ti sọ̀rọ̀! Ta ni kì yóò sọ tẹ́lẹ̀?’+
9 “‘Ẹ kéde rẹ̀ fáyé gbọ́ lórí àwọn ilé gogoro ibùgbé ní Áṣídódì àti lórí àwọn ilé gogoro ibùgbé ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ kí ẹ sì sọ pé: “Ẹ kóra jọpọ̀ lòdì sí òkè ńlá Samáríà,+ kí ẹ sì rí ọ̀pọ̀ rúgúdù tí ó wà ní àárín rẹ̀ àti jìbìtì lílù ní inú rẹ̀.+
10 Wọn kò sì mọ bí a ti ń ṣe ohun tí ó tọ́,”+ ni àsọjáde Jèhófà, “àwọn tí ń to ìwà ipá+ àti ìfiṣèjẹ jọ pa mọ́ sínú ilé gogoro ibùgbé wọn.”’
11 “Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘Elénìní kan wà àní yí ilẹ̀ náà ká,+ yóò sì mú kí okun rẹ rọlẹ̀ lára rẹ dájúdájú, a ó sì piyẹ́ àwọn ilé gogoro ibùgbé rẹ+ ní ti tòótọ́.’
12 “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Gan-an gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn tí ń já tete méjì tàbí abala etí+ kan gbà kúrò ní ẹnu kìnnìún, bẹ́ẹ̀ ni a ó ṣe já àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà, àwọn tí ń jókòó sórí àga ìrọ̀gbọ̀kú ọlọ́lá ńlá+ ní Samáríà àti sórí àga ìnàyìn ará Damásíkù.’+
13 “‘Ẹ gbọ́, kí ẹ sì jẹ́rìí+ ní ilé Jékọ́bù,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, Ọlọ́run àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun.
14 ‘Nítorí pé, ní ọjọ́ ti èmi yóò béèrè ìjíhìn+ fún àwọn ìdìtẹ̀ Ísírẹ́lì lọ́wọ́ rẹ̀, ni èmi yóò béèrè ìjíhìn lọ́wọ́ àwọn pẹpẹ Bẹ́tẹ́lì+ pẹ̀lú; àwọn ìwo pẹpẹ náà ni a ó sì ké kúrò dájúdájú, wọn yóò sì já bọ́ sílẹ̀.+
15 Dájúdájú, èmi yóò sì ṣá ilé ìgbà òtútù+ balẹ̀ ní àfikún sí ilé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn.’+
“‘Àwọn ilé eyín erin yóò sì ṣègbé,+ ọ̀pọ̀ ilé yóò sì wá sí òpin wọn dájúdájú,’+ ni àsọjáde Jèhófà.”

