Àwọn Onídàájọ́ 18:1-31
18 Kò sí ọba ní Ísírẹ́lì ní ọjọ́ wọnnì.+ Ẹ̀yà àwọn ọmọ Dánì+ sì ń wá ogún fún ara rẹ̀ ní ọjọ́ wọnnì láti máa gbé níbẹ̀; nítorí pé títí di ọjọ́ yẹn, ogún kò tíì bọ́ sọ́wọ́ wọn láàárín àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì.+
2 Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, àwọn ọmọ Dánì rán ọkùnrin márùn-ún lára ìdílé wọn, àwọn ọkùnrin láti àárín wọn, àwọn ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ akíkanjú, jáde láti Sórà+ àti Éṣítáólì,+ láti ṣe amí+ ilẹ̀ náà àti láti yẹ̀ ẹ́ wò. Nítorí náà, wọ́n sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ yẹ ilẹ̀ náà wò.” Nígbà tí ó ṣe, wọ́n dé ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Éfúráímù+ títí dé ilé Míkà,+ wọ́n sì sun ibẹ̀ mọ́jú.
3 Nígbà tí wọ́n sún mọ́ tòsí ilé Míkà, wọ́n dá ohùn ọ̀dọ́kùnrin náà, ọmọ Léfì mọ̀, wọ́n sì yà síbẹ̀. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún un pé: “Ta ní mú ọ wá síhìn-ín, kí sì ni ohun tí o ń ṣe níbí, kí sì ni o lọ́kàn-ìfẹ́ sí níhìn-ín?”
4 Ẹ̀wẹ̀, ó wí fún wọn pé: “Báyìí báyìí ni Míkà ṣe fún mi kí ó lè háyà mi,+ àti pé kí n lè ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà+ fún un.”
5 Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé: “Jọ̀wọ́, wádìí+ lọ́dọ̀ Ọlọ́run+ kí a lè mọ̀ bóyá ọ̀nà wa tí àwa ń lọ yóò yọrí sí rere.”
6 Nítorí náà, àlùfáà náà wí fún wọn pé: “Ẹ máa lọ ní àlàáfíà. Iwájú Jèhófà ni ọ̀nà yín tí ẹ̀yin ń lọ wà.”
7 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn ọkùnrin márùn-ún náà tẹ̀ síwájú, wọ́n sì dé Láíṣì,+ wọ́n sì rí bí àwọn ènìyàn tí wọ́n wà nínú rẹ̀ ti ń gbé lọ́nà ìgbẹ́kẹ̀lé ara-ẹni gẹ́gẹ́ bí àṣà àwọn ọmọ Sídónì, ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ àti láìfura,+ kò sì sí aṣẹ́gun tí ń nini lára tí ń fìtínà ohunkóhun ní ilẹ̀ náà, bí wọ́n ti wà ní ibi jíjì nnàréré sí àwọn ọmọ Sídónì,+ wọn kò sì ní nǹkan kan láti ṣe pẹ̀lú aráyé.
8 Níkẹyìn wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin wọn ní Sórà+ àti Éṣítáólì,+ àwọn arákùnrin wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún wọn pé: “Báwo ni ẹ ti rí i sí?”
9 Látàrí èyí, wọ́n wí pé: “Ẹ dìde, ẹ sì jẹ́ kí a gòkè lọ gbéjà kò wọ́n; nítorí tí a ti rí ilẹ̀ náà, wò ó! ó dára gidigidi.+ Ẹ sì ń lọ́ tìkọ̀. Ẹ má ṣe lọ́ra nípa rírìn wọlé wá láti gba ilẹ̀ náà.+
10 Nígbà tí ẹ bá wọlé wá, ẹ̀yin yóò wá bá àwọn ènìyàn tí ó wà láìfura,+ ilẹ̀ náà sì gbòòrò díẹ̀; nítorí tí Ọlọ́run ti fi í lé yín lọ́wọ́,+ ibì kan tí kò ṣe aláìní ohunkóhun tí ó wà ní ilẹ̀ ayé.”+
11 Nígbà náà ni ẹgbẹ̀ta ọkùnrin tí a fi àwọn ohun ìjà ogun dì lámùrè, láti inú ìdílé àwọn ọmọ Dánì,+ gbéra lọ láti ibẹ̀, èyíinì ni, láti Sórà àti Éṣítáólì.+
12 Wọ́n sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n gòkè lọ, wọ́n sì lọ dó sí Kiriati-jéárímù+ ní Júdà. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi pe ibẹ̀ ní Mahane-dánì+ títí di òní yìí. Wò ó! Ó wà ní ìwọ̀-oòrùn Kiriati-jéárímù.
13 Lẹ́yìn náà, wọ́n kọjá lọ láti ibẹ̀ sí ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Éfúráímù, wọ́n sì lọ títí dé ilé Míkà.+
14 Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin márùn-ún náà tí ó lọ ṣe amí+ ilẹ̀ Láíṣì+ dáhùn, wọ́n sì wí fún àwọn arákùnrin wọn pé: “Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé éfódì àti ère tẹ́ráfímù+ àti ère gbígbẹ́+ àti ère dídà+ wà nínú ilé wọ̀nyí? Wàyí o, ẹ ní ohun tí ó yẹ kí ẹ ṣe lọ́kàn.”+
15 Nítorí náà, wọ́n yà síbẹ̀, wọ́n sì wá sí ilé ọ̀dọ́kùnrin náà, ọmọ Léfì,+ ní ilé Míkà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí béèrè nípa bí ó ti ń ṣe sí.+
16 Ní gbogbo àkókò náà, ẹgbẹ̀ta ọkùnrin tí a fi àwọn ohun ìjà ogun+ wọn dì lámùrè, tí wọ́n jẹ́ ara àwọn ọmọ Dánì,+ dúró sí ibi àbáwọ ẹnubodè.
17 Àwọn ọkùnrin márùn-ún náà tí ó lọ ṣe amí ilẹ̀ náà+ gòkè lọ wàyí, kí wọ́n lè wọ ibẹ̀ láti kó ère gbígbẹ́+ àti éfódì+ àti ère tẹ́ráfímù+ àti ère dídà náà.+ (Àlùfáà náà+ sì dúró sí ibi àbáwọ ẹnubodè pẹ̀lú ẹgbẹ̀ta ọkùnrin náà tí a fi àwọn ohun ìjà ogun dì lámùrè.)
18 Àwọn wọ̀nyí sì wọnú ilé Míkà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kó ère gbígbẹ́ náà, éfódì àti ère tẹ́ráfímù àti ère dídà náà.+ Látàrí ìyẹn, àlùfáà náà+ wí fún wọn pé: “Kí ni ẹ ń ṣe yìí?”
19 Ṣùgbọ́n wọ́n wí fún un pé: “Dákẹ́. Fi ọwọ́ rẹ bo ẹnu rẹ, kí o sì bá wa lọ, kí o sì di baba+ àti àlùfáà+ fún wa. Èwo ni ó sàn jù, pé kí o máa bá a lọ bí àlùfáà fún ilé ọkùnrin kan+ tàbí kí o di àlùfáà fún ẹ̀yà àti ìdílé kan ní Ísírẹ́lì?”+
20 Látàrí èyí, ó dùn mọ́ ọkàn-àyà àlùfáà náà,+ ó sì kó éfódì àti ère tẹ́ráfímù àti ère gbígbẹ́+ náà wàyí, ó sì wá sí àárín àwọn ènìyàn náà.
21 Nígbà náà ni wọ́n yí padà, wọ́n sì bá ọ̀nà wọn lọ, wọ́n sì fi àwọn ọmọ kéékèèké àti ohun ọ̀sìn àti àwọn ohun tí ó níye lórí ṣáájú wọn.+
22 Àwọn fúnra wọn ti rìn jì nnà díẹ̀ sí ilé Míkà nígbà tí àwọn ọkùnrin tí wọ́n wà ní àwọn ilé tí ó wà nítòsí ilé Míkà+ péjọ, tí wọ́n sì gbìyànjú láti lé àwọn ọmọ Dánì bá.
23 Nígbà tí wọ́n ń ké jáde sí àwọn ọmọ Dánì ṣáá, nígbà náà ni wọ́n yíjú padà, wọ́n sì wí fún Míkà pé: “Kí ní ṣe yín+ tí ẹ fi péjọ?”
24 Nítorí náà, ó wí pé: “Àwọn ọlọ́run mi+ tí mo ṣe+ ni ẹ ti kó, àlùfáà+ náà pẹ̀lú, ẹ sì bá ọ̀nà yín lọ, kí sì ni mo tún ní?+ Báwo wá ni ẹ ṣe lè sọ fún mi pé, ‘Kí ní ṣe ọ́?’”
25 Látàrí èyí, àwọn ọmọ Dánì wí fún un pé: “Má ṣe jẹ́ kí a gbọ́ ohùn rẹ ní etí ọ̀dọ̀ wa, kí àwọn ọkùnrin tí ó ní ìkorò+ ọkàn má bàa fipá kọlù yín, tí ẹ ó sì pàdánù ọkàn tiyín àti ọkàn agbo ilé yín dájúdájú.”
26 Àwọn ọmọ Dánì sì ń bá ọ̀nà wọn lọ; Míkà sì wá rí i pé wọ́n lágbára ju òun lọ,+ nípa báyìí, ó yí padà, ó sì padà lọ sí ilé rẹ̀.
27 Ní tiwọn, wọ́n kó ohun tí Míkà ṣe àti àlùfáà+ tí ó di tirẹ̀, wọ́n sì ń lọ síhà Láíṣì,+ láti gbéjà ko àwọn ènìyàn tí wọ́n wà ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ tí wọ́n sì wà láìfura.+ Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ojú idà kọlù wọ́n,+ ìlú ńlá náà ni wọ́n sì fi iná sun.+
28 Kò sì sí olùdáǹdè, nítorí tí ó jì nnàréré sí Sídónì,+ wọn kò sì ní nǹkan kan láti ṣe rárá pẹ̀lú aráyé; ó sì wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ tí ó jẹ́ ti Bẹti-réhóbù.+ Nígbà náà ni wọ́n kọ́ ìlú ńlá náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé inú rẹ̀.+
29 Pẹ̀lúpẹ̀lù, wọ́n pe orúkọ ìlú ńlá náà ní Dánì nípa orúkọ baba wọn, Dánì,+ tí a bí fún Ísírẹ́lì.+ Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Láíṣì ni orúkọ ìlú ńlá náà ní ìbẹ̀rẹ̀ pàá.+
30 Lẹ́yìn èyíinì, àwọn ọmọ Dánì gbé ère gbígbẹ́+ náà nà ró fún ara wọn; Jònátánì+ ọmọkùnrin Gẹ́ṣómù,+ ọmọkùnrin Mósè, òun àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, sì di àlùfáà fún ẹ̀yà àwọn ọmọ Dánì títí di ọjọ́ tí a kó ilẹ̀ náà lọ sí ìgbèkùn.+
31 Wọ́n sì gbé ère gbígbẹ́ Míkà, èyí tí ó ṣe, kalẹ̀ fún ara wọn ní gbogbo ọjọ́ tí ilé+ Ọlọ́run tòótọ́ fi ń bá a lọ ní wíwà ní Ṣílò.+

