Àwọn Onídàájọ́ 1:1-36
1 Lẹ́yìn ikú+ Jóṣúà, ó ṣẹlẹ̀ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí wádìí+ lọ́dọ̀ Jèhófà pé: “Ta ni nínú wa ni yóò kọ́kọ́ gòkè lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Kénáánì, láti bá wọn jà?”
2 Jèhófà fèsì pé: “Júdà ni yóò gòkè lọ.+ Wò ó! Dájúdájú, èmi yóò fi ilẹ̀ náà lé e lọ́wọ́.”
3 Nígbà náà ni Júdà wí fún Síméónì arákùnrin rẹ̀ pé: “Jẹ́ kí a jọ gòkè lọ sí ìpín mi+ kí a sì bá àwọn ọmọ Kénáánì jà, èmi alára ẹ̀wẹ̀, yóò sì bá ọ lọ sí ìpín tìrẹ.”+ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Síméónì bá a lọ.+
4 Pẹ̀lú ìyẹn, Júdà gòkè lọ, Jèhófà sì fi àwọn ọmọ Kénáánì àti àwọn Pérísì lé wọn lọ́wọ́,+ tí wọ́n fi ṣẹ́gun wọn ní Bésékì, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọkùnrin.
5 Nígbà tí wọ́n rí Adoni-bésékì ní Bésékì, wọ́n wá bá a jà, wọ́n sì ṣẹ́gun àwọn ọmọ Kénáánì+ àti àwọn Pérísì.+
6 Nígbà tí Adoni-bésékì fẹsẹ̀ fẹ, wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí lépa rẹ̀, wọ́n sì gbá a mú, wọ́n sì gé àwọn àtàǹpàkò ọwọ́ rẹ̀ àti àwọn àtàǹpàkò ẹsẹ̀ rẹ̀ kúrò.
7 Látàrí èyí, Adoni-bésékì wí pé: “Àádọ́rin ọba tí a ti gé àwọn àtàǹpàkò ọwọ́ àti àwọn àtàǹpàkò ẹsẹ̀ wọn kúrò ni wọ́n wà, tí wọ́n ń ṣa oúnjẹ jẹ lábẹ́ tábìlì mi. Gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe, bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run san án padà fún mi.”+ Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n mú un wá sí Jerúsálẹ́mù,+ ó sì kú níbẹ̀.
8 Síwájú sí i, àwọn ọmọ Júdà ń bá Jerúsálẹ́mù+ ja ogun nìṣó, wọ́n sì wá gbà á, wọ́n sì wá fi ojú idà kọlù ú, wọ́n sì gbé ìlú ńlá náà lé iná lọ́wọ́.
9 Lẹ́yìn ìgbà náà, àwọn ọmọ Júdà sọ̀ kalẹ̀ lọ bá àwọn ọmọ Kénáánì tí ń gbé ní ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá àti Négébù+ àti Ṣẹ́fẹ́là+ jà.
10 Báyìí ni Júdà lọ gbéjà ko àwọn ọmọ Kénáánì tí ń gbé ní Hébúrónì+ (wàyí o, orúkọ Hébúrónì ṣáájú ìyẹn ni Kiriati-ábà),+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣá Ṣéṣáì àti Áhímánì àti Tálímáì+ balẹ̀.
11 Wọ́n sì ti ibẹ̀ lọ gbéjà ko àwọn olùgbé Débírì.+ (Wàyí o, orúkọ Débírì ṣáájú ìyẹn ni Kiriati-séférì.)+
12 Nígbà náà ni Kálébù+ sọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá kọlu Kiriati-séférì, tí ó sì gbà á, họ́wù, èmi yóò fi Ákúsà+ ọmọbìnrin mi fún un ṣe aya.”+
13 Ótíníẹ́lì+ ọmọkùnrin Kénásì,+ àbúrò+ Kálébù, sì gbà á. Nítorí ìyẹn, ó fi Ákúsà ọmọbìnrin rẹ̀ fún un ṣe aya.+
14 Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí ọmọbìnrin náà ń lọ sí ilé, ó ń ru ú lọ́kàn sókè ṣáá pé kí ó béèrè pápá kan lọ́wọ́ baba òun. Nígbà náà ni ọmọbìnrin náà pàtẹ́wọ́ bí ó ti wà lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.+ Látàrí èyí, Kálébù sọ fún un pé: “Kí ni o ń fẹ́?”
15 Nítorí náà, ó wí fún un pé: “Yọ̀ǹda ìbùkún+ kan fún mi, nítorí ilẹ̀ kan ní ìhà gúúsù ni o fún mi, kí o sì fún mi ní Guloti-máímù.” Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Kálébù fún un ní Gúlótì Òkè àti Gúlótì+ Ìsàlẹ̀.
16 Àwọn ọmọ ẹni tí í ṣe Kénì,+ tí Mósè jẹ́ ọkọ ọmọ rẹ̀,+ sì gòkè pẹ̀lú àwọn ọmọ Júdà láti ìlú ńlá onígi ọ̀pẹ+ wá sí aginjù Júdà, èyí tí ó wà ní gúúsù Árádì.+ Nígbà náà ni wọ́n lọ, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé pẹ̀lú àwọn ènìyàn náà.+
17 Ṣùgbọ́n Júdà ń lọ pẹ̀lú Síméónì arákùnrin rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kọlu àwọn ọmọ Kénáánì tí ń gbé Séfátì, wọ́n sì yà á sọ́tọ̀ fún ìparun.+ Nípa bẹ́ẹ̀, orúkọ ìlú ńlá náà ni a pè ní Hóómà.+
18 Lẹ́yìn ìyẹn, Júdà gba Gásà+ àti ìpínlẹ̀ rẹ̀ àti Áṣíkẹ́lónì+ àti ìpínlẹ̀ rẹ̀ àti Ékírónì+ àti ìpínlẹ̀ rẹ̀.
19 Jèhófà sì ń bá a lọ láti wà pẹ̀lú Júdà, tí wọ́n fi gba ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá náà, ṣùgbọ́n kò lè lé àwọn olùgbé pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ kúrò, nítorí tí wọ́n ní àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun+ onídòjé irin.+
20 Nígbà tí wọ́n fi Hébúrónì fún Kálébù, gan-an gẹ́gẹ́ bí Mósè ti ṣèlérí,+ nígbà náà ni ó lé àwọn ọmọkùnrin Ánákì+ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta jáde níbẹ̀.
21 Àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì kò sì lé àwọn ará Jébúsì tí ń gbé Jerúsálẹ́mù+ jáde; ṣùgbọ́n àwọn ará Jébúsì ń bá a nìṣó ní gbígbé pẹ̀lú àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì ní Jerúsálẹ́mù títí di òní yìí.+
22 Láàárín àkókò yìí, ilé Jósẹ́fù+ pẹ̀lú gòkè lọ lòdì sí Bẹ́tẹ́lì,+ Jèhófà sì wà pẹ̀lú wọn.+
23 Ilé Jósẹ́fù sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe amí+ Bẹ́tẹ́lì (ó ṣẹlẹ̀ pé, orúkọ ìlú ńlá náà ṣáájú ìyẹn ni Lúsì),+
24 àwọn olùṣọ́ sì wá rí ọkùnrin kan tí ń jáde lọ láti ìlú ńlá náà. Nítorí náà, wọ́n wí fún un pé: “Jọ̀wọ́, fi ọ̀nà láti gbà wọnú ìlú ńlá yìí hàn wá, àwa yóò sì ṣe inú rere sí ọ dájúdájú.”+
25 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ọkùnrin náà fi ọ̀nà láti gbà wọnú ìlú ńlá náà hàn wọ́n; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ojú idà+ kọlu ìlú ńlá náà, ṣùgbọ́n ọkùnrin náà àti gbogbo ìdílé rẹ̀ ni wọ́n jẹ́ kí ó lọ.+
26 Látàrí ìyẹn, ọkùnrin náà lọ sí ilẹ̀ àwọn ọmọ Hétì,+ ó sì tẹ ìlú ńlá kan dó, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Lúsì. Orúkọ rẹ̀ níyẹn títí di òní yìí.
27 Mánásè+ kò sì gba Bẹti-ṣéánì+ àti àwọn àrọko rẹ̀ àti Táánákì+ àti àwọn àrọko rẹ̀ àti àwọn olùgbé Dórì+ àti àwọn àrọko rẹ̀ àti àwọn olùgbé Íbíléámù+ àti àwọn àrọko rẹ̀ àti àwọn olùgbé Mẹ́gídò+ àti àwọn àrọko rẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Kénáánì ń bá a lọ ní gbígbé ilẹ̀ yìí.+
28 Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, Ísírẹ́lì di alágbára,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn ọmọ Kénáánì ṣe òpò àfipámúniṣe,+ wọn kò sì lé wọn jáde pátápátá.+
29 Bẹ́ẹ̀ ni Éfúráímù kò lé àwọn ọmọ Kénáánì tí ń gbé ní Gésérì jáde, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Kénáánì ń bá a lọ ní gbígbé láàárín wọn ní Gésérì.+
30 Sébúlúnì+ kò lé àwọn olùgbé Kítírónì àti àwọn olùgbé Náhálólì+ jáde, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Kénáánì ń bá a lọ ní gbígbé láàárín wọn,+ wọ́n sì wá fi wọ́n ṣe òpò àfipámúniṣe.+
31 Áṣérì+ kò lé àwọn olùgbé Ákò àti àwọn olùgbé Sídónì+ àti Álábù àti Ákísíbù+ àti Hélíbà àti Áfíkì+ àti Réhóbù+ jáde.
32 Àwọn ọmọ Áṣérì sì ń bá a lọ ní gbígbé láàárín àwọn ọmọ Kénáánì tí ń gbé ilẹ̀ náà, nítorí tí wọn kò lé wọn jáde.+
33 Náfútálì+ kò lé àwọn olùgbé Bẹti-ṣémẹ́ṣì àti àwọn olùgbé Bẹti-ánátì+ jáde, ṣùgbọ́n wọ́n ń bá a lọ ní gbígbé láàárín àwọn ọmọ Kénáánì tí ń gbé ilẹ̀ náà;+ àwọn olùgbé Bẹti-ṣémẹ́ṣì àti ti Bẹti-ánátì sì di tiwọn fún òpò àfipámúniṣe.+
34 Àwọn Ámórì sì ń bá a lọ láti ti àwọn ọmọ Dánì+ sí ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá, nítorí wọn kò jẹ́ kí wọ́n sọ̀ kalẹ̀ wá sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀.+
35 Nítorí náà, àwọn Ámórì ń bá a lọ ní gbígbé ní Òkè Ńlá Hérésì àti Áíjálónì+ àti Ṣáálíbímù.+ Ṣùgbọ́n ọwọ́ ilé Jósẹ́fù rinlẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí a fi fi ipá mú wọ́n wọnú iṣẹ́ ìmúnisìn.+
36 Ìpínlẹ̀ àwọn Ámórì sì jẹ́ láti ìgòkè Ákírábímù,+ láti Sẹ́ẹ́là sókè.

