DI Ọ̀RẸ́ JÈHÓFÀ
Ìwọ Náà Lè Di Aṣáájú-Ọ̀nà!
Eré yìí lè jẹ́ kó wu àwọn ọmọ rẹ láti di aṣáájú-ọ̀nà.
Ẹ̀yin òbí, ẹ ka Mátíù 28:19, 20 kẹ́ ẹ sì jíròrò ẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ yín.
Wa eré yìí jáde, kó o sì tẹ̀ ẹ́ sórí ìwé.
Ìwọ àtàwọn ọmọ rẹ lè jọ sọ̀rọ̀ nípa ohun táwọn aṣáájú-ọ̀nà máa ń ṣe, kó o wá ní kí wọ́n ya àwòrán ara wọn tí wọ́n bá ti di aṣáájú-ọ̀nà lọ́jọ́ iwájú. Lẹ́yìn náà, sọ fún wọn pé kí wọ́n bi aṣáájú-ọ̀nà kan ní ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí.

