Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ṣé Orí Àgbélébùú Ni Jésù Kú Sí?

Ṣé Orí Àgbélébùú Ni Jésù Kú Sí?

Ohun tí Bíbélì sọ

Àmì tí àwọn èèyàn fi ń dá àwọn Kristẹni mọ̀ ni ọ̀pọ̀ èèyàn ka àgbélébùú sí. Àmọ́, Bíbélì kò ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa bí ohun tí wọ́n fi pa Jésù ṣe rí gan-an, torí náà kò sẹ́ni tó lè sọ bó ṣe rí ní pàtó. Síbẹ̀, Bíbélì fún wa ní àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé orí òpó igi tó dúró ṣánṣán ni Jésù kú sí, kì í ṣe orí àgbélébùú.

Lọ́pọ̀ ìgbà, ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, stau·ros′ ni Bíbélì máa ń lò tó bá ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tí wọ́n kan Jésù mọ́. (Mátíù 27:40; Jòhánù 19:17) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn atúmọ̀ èdè kan túmọ̀ ọ̀rọ̀ náà sí “àgbélébùú,” síbẹ̀, àwọn ọ̀mọ̀wé kan gbà pé ohun tó túmọ̀ sí gan-an ni “òpó igi tó dúró ṣánṣán.” * Ìwé atúmọ̀ èdè náà, A Critical Lexicon and Concordance to the English and Greek New Testament, sọ pé stau·ros′ “kì í ṣe ẹ̀là igi méjì tí wọ́n gbé dábùú ara wọn.”

Ọ̀rọ̀ míì tí Bíbélì máa ń lò fún ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà stau·ros′ ni xy′lon. (Ìṣe 5:30; 1 Pétérù 2:24) Ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí “igi,” “igi gẹdú,” “òpó igi,” tàbí “igi.” * Ibi tí Bíbélì The Companion Bible parí ọ̀rọ̀ sí ni pé: “Kò tiẹ̀ sí ohun kankan nínú èdè Gíríìkì tí wọ́n fi kọ [Májẹ̀mú Tuntun] tó túmọ̀ sí igi méjì.”

Ṣé Ọlọ́run fọwọ́ sí lílo àgbélébùú nínú ìjọsìn?

Ọ̀rọ̀ náà, crux simplex tó wá láti inú èdè Látìn, túmọ̀ sí òpó igi kan ṣoṣo tó dúró ṣánṣán tí wọ́n máa ń kan àwọn ọ̀daràn mọ́

Láìka ibi yòówù tí wọ́n kan Jésù mọ́ tó fi kú, àwọn kókó pàtàkì àtàwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà nísàlẹ̀ yìí fi hàn pé a kò gbọ́dọ̀ lo àgbélébùú nínú ìjọsìn.

  1. Ọlọ́run kò fọwọ́ sí lílo àwọn ère tàbí àmì nínú ìjọsìn, títí kan àgbélébùú. Ọlọ́run pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, wọn kò gbọ́dọ̀ lo “ìrísí àpẹẹrẹ èyíkéyìí” nínú ìjọsìn wọn. Bíbélì sọ pé kí àwọn Kristẹni náà “sá fún ìbọ̀rìṣà.”Diutarónómì 4:15-19; 1 Kọ́ríńtì 10:14.

  2. Àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní kò lo àgbélébùú nínú ìjọsìn wọn. * Ohun tí àwọn àpọ́sítélì fi kọ́ àwọn èèyàn àti àpẹẹrẹ wọn ló yẹ kí gbogbo Kristẹni máa tẹ̀ lé.2 Tẹsalóníkà 2:15.

  3. Ọ̀dọ̀ àwọn abọ̀rìṣà ni àṣà lílo àgbélébùú nínú ìjọsìn ti wá. * Ọgọ́rùn-ún ọdún mélòó kan lẹ́yìn ikú Jésù, nígbà tí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti yapa kúrò nínú àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀, wọ́n sì fàyè gbà àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọmọ ìjọ wọn “láti máa lo àwọn àmì ìbọ̀rìṣà wọn nìṣó,” títí kan àgbélébùú. (The Expanded Vine’s Expository Dictionary of New Testament Words) Àmọ́, Bíbélì kò fàyè gba lílo àmì ìbọ̀rìṣà nítorí kí àwọn èèyàn lè di onígbàgbọ́.2 Kọ́ríńtì 6:17.

^ ìpínrọ̀ 4 Wo ìwé atúmọ̀ ọ̀rọ̀ inú Bíbélì náà, New Bible Dictionary, Ìtẹ̀jáde Kẹta, látọwọ́ D. R. W. Wood, ojú ìwé 245; ìwé atúmọ̀ èdè kan tó dá lórí ẹ̀kọ́ ìsìn, ìyẹn Theological Dictionary of the New Testament, Volume VII, ojú ìwé 572; ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The International Standard Bible Encyclopedia, Revised Edition, Volume 1, ojú ìwé 825; àti ìwé The Imperial Bible-Dictionary, Volume II, ojú ìwé 84.

^ ìpínrọ̀ 5 Wo ìwé atúmọ̀ èdè náà, The Expanded Vine’s Expository Dictionary of New Testament Words, ojú ìwé 1165; ìwé atúmọ̀ èdè kan tí Liddell àti Scott ṣe, tí wọ́n pè ní A Greek-English Lexicon, Ninth Edition, ojú ìwé 1191 sí 1192; àti ìwé Theological Dictionary of the New Testament, Volume V, ojú ìwé 37.

^ ìpínrọ̀ 9 Wo ìwé Gbédègbẹ́yọ̀ náà, Encyclopædia Britannica, 2003, wo abẹ́ àgbélébùú, ìyẹn “Cross”; ìwé The Cross—Its History and Symbolism, ojú ìwé 40; àti ìwé The Companion Bible, tí Oxford University Press tẹ̀ jáde, Àfikún àlàyé (appendix) 162, ojú ìwé 186.

^ ìpínrọ̀ 10 Wo ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia of Religion, Volume 4, ojú ìwé 165; ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia Americana, Volume 8, ojú ìwé 246; àti ìwé Symbols Around Us, ojú ìwé 205-207.

 

Mọ Púpọ̀ Sí I

ÌRÒYÌN AYỌ̀ LÁTỌ̀DỌ̀ ỌLỌ́RUN!

Ta Ni Jésù Kristi?

Kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìdí tí Jésù fi kú, ohun tí ìràpadà jẹ́ àti ohun tí Jésù ń ṣe nísinsìnyí.