Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ṣé Ibi Gbogbo Ni Ọlọ́run Wà?

Ṣé Ibi Gbogbo Ni Ọlọ́run Wà?

Ohun tí Bíbélì sọ

Ọlọ́run lè rí gbogbo nǹkan, ó sì lè ṣe ohun tó fẹ́ níbikíbi tó bá wù ú. (Òwe 15:3; Hébérù 4:13) Àmọ́, Bíbélì ò fi kọ́ni pé gbogbo ibi ni Ọlọ́run wà tàbí pé Ọlọ́run wà nínú ohun gbogbo. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ká mọ̀ pé ẹni gidi kan ni Ọlọ́run, ó sì níbi tó ń gbé.

  • Bí Ọlọ́run ṣe rí: Ẹni ẹ̀mí ni Ọlọ́run. (Jòhánù 4:​24) Àwa èèyàn ò lè rí i. (Jòhánù 1:​18) Àwọn ìran tí Bíbélì sọ pé àwọn kan rí nípa Ọlọ́run máa ń jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ní ibì kan pàtó tó wà. Wọn ò mẹ́nu bà á rí pé ibi gbogbo ló wà.​—Aísáyà 6:​1, 2; Ìṣípayá 4:​2, 3, 8.

  • Ibi tí Ọlọ́run ń gbé: Ọ̀run ni Ọlọ́run ń gbé, níbi táwọn ẹ̀dá ẹ̀mí wà, ibẹ̀ sì yàtọ̀ sí ayé tàbí ojú ọ̀run tá à ń rí. Níbi táwọn ẹ̀dá ẹ̀mí yẹn wà, Ọlọ́run ní “ibi tí [ó] ń gbé, ní ọ̀run.” (1 Àwọn Ọba 8:​30) Bíbélì sọ̀rọ̀ ìgbà kan táwọn ẹ̀dá ẹ̀mí “wọlé láti mú ìdúró wọn níwájú Jèhófà,” * ìyẹn jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ní ibì kan pàtó tó ń gbé.​—Jóòbù 1:6.

Tí Ọlọ́run ò bá sí níbi gbogbo, ṣé ó wá lè rí tèmi rò?

Bẹ́ẹ̀ ni. Ọlọ́run mọ gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, ọ̀rọ̀ wa sì jẹ ẹ́ lógún gan-an. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀run ló ń gbé, Ọlọ́run máa ń rí àwọn tó fẹ́ ṣe ìfẹ́ rẹ̀ láyé, ó sì máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́. (1 Àwọn Ọba 8:​39; 2 Kíróníkà 16:9) Wo bí Jèhófà ṣe ń ran àwọn tó ń fi òótọ́ inú sìn ín lọ́wọ́:

  • Tó o bá gbàdúrà: Gbàrà tó o bá gbàdúrà sí Jèhófà ló lè gbọ́ ẹ.​—2 Kíróníkà 18:31.

  • Tó o bá sorí kọ́: “Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.”​—Sáàmù 34:18.

  • Tó o bá ń wá ìtọ́sọ́nà: Jèhófà máa lo Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti ‘mú kí o ní ìjìnlẹ̀ òye, á sì fún ọ ní ìtọ́ni.’​—Sáàmù 32:8.

Èrò tí kò tọ́ táwọn èèyàn ní pé ibi gbogbo ni Ọlọ́run wà

Èrò tí kò tọ́: Ọlọ́run wà nínú gbogbo ohun tó dá.

Òótọ́: Kì í ṣe ayé ni Ọlọ́run ń gbé, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe inú àwọn ohun tó wà lójú ọ̀run. (1 Àwọn Ọba 8:​27) Òótọ́ ni pé àwọn ìràwọ̀ àtàwọn ohun míì tí Ọlọ́run dá “ń polongo ògo Ọlọ́run.” (Sáàmù 19:1) Àmọ́ Ọlọ́run kì í gbé inú àwọn ohun tó dá. Bí àpẹẹrẹ, ayàwòrán kan ò lè máa gbé nínú àwòrán tó yà. Síbẹ̀, àwòrán náà lè jẹ́ ká mọ irú èèyàn tí ẹni tó yà á jẹ́. Lọ́nà kan náà, àwọn ohun tá à ń rí láyé jẹ́ ká mọ “àwọn ànímọ́ [Ẹlẹ́dàá] tí a kò lè rí,” bí agbára, ọgbọ́n àti ìfẹ́.​—Róòmù 1:​20.

Èrò tí kò tọ́: Tí Ọlọ́run ò bá sí níbi gbogbo, kò ní lè mọ gbogbo nǹkan, kó sì lè lágbára lórí ohun gbogbo.

Òótọ́: Ẹ̀mí mímọ́ ni agbára tí Ọlọ́run fi ń ṣiṣẹ́. Ọlọ́run lè fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ mọ ohunkóhun, ó sì lè fi ṣe ohunkóhun, níbikíbi, nígbàkigbà láìjẹ́ pé òun fúnra rẹ̀ wà níbẹ̀.​—Sáàmù 139:7.

Èrò tí kò tọ́: Sáàmù 139:8 kọ́ wa pé ibi gbogbo ni Ọlọ́run wà, torí ó sọ pé: “Bí mo bá gòkè re ọ̀run, ibẹ̀ ni ìwọ yóò wà; bí mo bá sì ga àga ìrọ̀gbọ̀kú mi ní Ṣìọ́ọ̀lù, wò ó! ìwọ yóò wà níbẹ̀.”

Òótọ́: Kì í ṣe ibi tí Ọlọ́run wà ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ń sọ. Ṣe ló ń sọ̀rọ̀ lówelówe pé kò síbi tó jìnnà jù fún Ọlọ́run láti dé kó lè ràn wá lọ́wọ́.

^ ìpínrọ̀ 5 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.

Mọ Púpọ̀ Sí I

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Kí Ni Ọlọ́run Fẹ́ Kí N Fi Ayé Mi Ṣe?

Ǹjẹ́ o nílò kí Ọlọ́run fi àmì àrà ọ̀tọ̀ kan hàn ọ́ tàbí kí Ọlọ́run bá ọ sọ̀rọ̀ kó o tó mọ bí wàá ṣe máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀? Ka ohun tí Bíbélì sọ.