Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ǹjẹ́ Àwọn Ẹ̀mí Èṣù Wà?

Ǹjẹ́ Àwọn Ẹ̀mí Èṣù Wà?

Ohun tí Bíbélì sọ

Bẹ́ẹ̀ ni. “Àwọn áńgẹ́lì tí ó ṣẹ̀” ni àwọn ẹ̀mí èṣù, ẹ̀dá ẹ̀mí tó ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run sì ni wọ́n. (2 Pétérù 2:4) Sátánì Èṣù ni áńgẹ́lì tó kọ́kọ́ sọ ara rẹ̀ di ẹ̀mí èṣù, òun sì ni Bíbélì pè ní “olùṣàkóso àwọn ẹ̀mí èṣù.”—Mátíù 12:24, 26.

Ìwà ọ̀tẹ̀ tó wáyé nígbà ayé Nóà

Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn áńgẹ́lì kan ṣe hùwà ọ̀tẹ̀ ṣáájú Ìkún-omi ọjọ́ Nóà, ó ní: “Àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́ bẹ̀rẹ̀ sí kíyè sí àwọn ọmọbìnrin ènìyàn, pé wọ́n dára ní ìrísí; wọ́n sì ń mú aya fún ara wọn, èyíinì ni, gbogbo ẹni tí wọ́n bá yàn.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:2) Àwọn áńgẹ́lì burúkú tàbí àwọn áńgẹ́lì tó ṣubú yìí fi “ibi gbígbé tiwọn tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu” ní ọ̀run sílẹ̀, wọ́n sì gbé àwọ̀ èèyàn wọ̀ torí kí wọ́n lè ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn obìnrin.—Júúdà 6.

Nígbà tí Ìkún-omi dé, ńṣe ni àwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ yìí bọ́ ara èèyàn tí wọ́n gbé wọ̀ sílẹ̀ tí wọ́n sì padà sí ọ̀run. Àmọ́, Ọlọ́run lé wọn dànù, torí wọn kì í ṣe ara ìdílé rẹ̀ mọ́. Bí Ọlọ́run kò ṣe jẹ́ kí àwọn ẹ̀mí èṣù gbé àwọ̀ èèyàn wọ̀ mọ́ jẹ́ ara ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.—Éfésù 6:11, 12.

 

Mọ Púpọ̀ Sí I

Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?

Àwọn Ẹ̀dá Ẹ̀mí—Ohun Tí Wọ́n Ń Ṣe fún Wa

Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn áńgẹ́lì àti àwọn ẹ̀mí èṣù. Ṣé lóòótọ́ ni wọ́n wà? Ṣé wọ́n lè ràn ọ́ lọ́wọ́ tàbí kí wọ́n pa ọ́ lára?