Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe?

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe?

Ohun tí Bíbélì sọ

Ìjọba Ọlọ́run máa rọ́pò gbogbo àwọn ìjọba èèyàn, yóò sì ṣàkóso gbogbo ayé. (Dáníẹ́lì 2:44; Ìṣípayá 16:14) Gbàrà tí èyí bá bẹ̀rẹ̀, Ìjọba Ọlọ́run máa . . .

  • Mú àwọn ẹni ibi kúrò, torí ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan wọn ń pa gbogbo wa lára. “Ní ti àwọn ẹni burúkú, a óò ké wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé gan-an.”—Òwe 2:22.

  • Fi òpin sí gbogbo ogun. “[Ọlọ́run] mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.”—Sáàmù 46:9.

  • Mú kí àwọn èèyàn máà gbé ìgbé ayé ìrọ̀rùn, kí wọ́n sì wà ní ààbò. “Wọn yóò sì jókòó ní ti tòótọ́, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì.”—Míkà 4:4.

  • Sọ ayé di párádísè. “Aginjù àti ẹkùn ilẹ̀ aláìlómi yóò yọ ayọ̀ ńláǹlà, pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ yóò sì kún fún ìdùnnú, yóò sì yọ ìtànná gẹ́gẹ́ bí sáfúrónì.”—Aísáyà 35:1.

  • Pèsè iṣẹ́ tó dára tó sì gbádùn mọ́ni fún gbogbo èèyàn. “Àwọn àyànfẹ́ [Ọlọ́run] yóò sì jìfà iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Wọn kì yóò ṣiṣẹ́ lásán.”—Aísáyà 65:21-23, Bíbélì Mímọ.

  • Mú àìsàn kúrò. “Kò sì sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: “Àìsàn ń ṣe mí.’”—Aísáyà 33:24.

  • Mú ọjọ́ ogbó kúrò. “Kí ara rẹ̀ jà yọ̀yọ̀ ju ti ìgbà èwe; Kí ó padà sí àwọn ọjọ́ okun inú ti ìgbà èwe rẹ̀.”—Jóòbù 33:25.

  • Jí àwọn òkú dìde. “Gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn [Jésù], wọn yóò sì jáde wá.”—Jòhánù 5:28, 29.

 

Mọ Púpọ̀ Sí I

ÌRÒYÌN AYỌ̀ LÁTỌ̀DỌ̀ ỌLỌ́RUN!

Kí Ni Ìròyìn Ayọ̀ Náà?

Kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìròyìn tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ìdí tó fi jẹ́ kánjúkánjú àti ohun tó yẹ kó o ṣe.

Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?

Kí Ni Ọlọ́run Ní Lọ́kàn Tó Fi Dá Ilẹ̀ Ayé?

Ṣé ayé yìí ṣì máa di Párádísè bí Ọlọ́run ṣe sọ? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ìgbà wo?