Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Báwo Ni Àlàáfíà Ṣe Máa Wà ní Ayé?

Báwo Ni Àlàáfíà Ṣe Máa Wà ní Ayé?

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Kì í ṣe ìsapá àwọn èèyàn ló máa mú kí àlàáfíà wà ní ayé, Ìjọba Ọlọ́run ni. Èyí jẹ́ ìjọba ọ̀run tí Jésù Kristi máa jẹ́ olórí rẹ̀. Wo bí Bíbélì ṣe kọ́ wa nípa ìrétí àgbàyanu yìí.

  1. Ọlọ́run máa mú “kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé,” á sì tipa báyìí mú ìlérí tó ṣe ṣẹ pé òun máa mú kí àlàáfíà ní ayé láàárín “àwọn ẹni tí inú Ọlọ́run dùn sí.”—Sáàmù 46:9; Lúùkù 2:14, Ìròyìn Ayọ̀.

  2. Ìjọba Ọlọ́run máa ṣàkóso láti ọ̀run lórí gbogbo ayé. (Dáníẹ́lì 7:14) Ìjọba kan ṣoṣo tó kárí ayé yìí máa mú kí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni dópin, ìfẹ́ yìí ló sábà máa ń dá ìjà sílẹ̀.

  3. Bíbélì pe Jésù, tó jẹ́ Alákòóso Ìjọba Ọlọ́run, ní “Ọmọ Aládé Àlàáfíà” tó máa rí sí i pé “àlàáfíà kì yóò lópin.”—Isaiah 9:6, 7.

  4. Ọlọ́run kò ní jẹ́ kí àwọn tó fẹ́ máa jà gbé lábẹ́ Ìjọba náà, torí pé “ọkàn [Ọlọ́run] kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.”—Sáàmù 11:5; Òwe 2:22.

  5. Ọlọ́run ń kọ́ àwọn ọmọ abẹ́ ìjọba rẹ̀ ní béèyàn ṣe ń gbé ìgbé ayé àlàáfíà. Nígbà tí Bíbélì ń ṣàpèjúwé ohun tí ẹ̀kọ́ yìí máa yọrí sí, ó sọ pé: “Wọn yóò ní láti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn. Orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.”—Aísáyà 2:3, 4.

Ní báyìí, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ló ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípa bí wọ́n ṣe lè jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà. (Mátíù 5:9) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a wá láti inú onírúurú ẹ̀yà, tá a sì ń gbé ní àwọn ilẹ̀ tí iye wọn lé ní igba àti ọgbọ̀n [230], a ti pinnu pé a ò ní gbé ohun ìjà sókè sí èèyàn bí i tiwa.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ọ̀nà àlàáfíà lónìí

 

Mọ Púpọ̀ Sí I

ÌRÒYÌN AYỌ̀ LÁTỌ̀DỌ̀ ỌLỌ́RUN!

Kí Ni Ìròyìn Ayọ̀ Náà?

Kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìròyìn tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ìdí tó fi jẹ́ kánjúkánjú àti ohun tó yẹ kó o ṣe.

ÀWỌN WO LÓ Ń ṢE ÌFẸ́ JÈHÓFÀ LÓDE ÒNÍ?

Irú Èèyàn Wo Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Ẹlẹ́rìí Jèhófà mélòó lo mọ̀? Kí lo mọ̀ gan-an nípa wa?