Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

FÍDÍÒ ÀWỌN Ẹ̀KỌ́

Fídíò Tó Nasẹ̀ Ìwé Bíbélì

Àwọn fídíò kéékèèké yìí máa jẹ́ kó o rí àwọn ìsọfúnni pàtàkì nípa kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó wà nínú àwọn ìwé Bíbélì. Lo àwọn ẹ̀kọ́ yìí kó o lè túbọ̀ gbádùn Bíbélì tó o bá ń kà á, tó o sì ń kẹ́kọ̀ọ́.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ẹ́sírà

Jèhófà mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé òun máa dá àwọn èèyàn òun sílẹ̀ kúrò nígbèkùn ní Bábílónì àti pé òun á mú kí ìjọsìn tòótọ́ pa dà fìdí múlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Nehemáyà

Ìwé Nehemáyà kọ́ gbogbo àwọn tó ń ṣe ìjọsìn tòótọ́ láwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì lóde òní.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ẹ́sítérì

Àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Ẹ́sítérì máa mú kó o túbọ̀ nígbàgbọ́ pé Jèhófà Ọlọ́run lágbára láti gbà àwa èèyàn rẹ̀ sílẹ̀ nígbà ìṣòrò.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jóòbù

Gbogbo àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ni Èṣù máa dán wò. Ìtàn Jóòbù jẹ́ kó dá wa lójú pé a lè pa ìwà títọ́ wa mọ́ ká sì gbé ipò ọba aláṣẹ Jèhófà lárugẹ.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Sáàmù

Ìwé Sáàmù ti ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run lẹ́yìn, ó ń ran àwọn tó nífẹ̀ẹ́ tó Jèhófà lọ́wọ́, ó sì ń tù wọ́n nínú, ó tú sọ bí ìjọba Ọlọ́run ṣe máa tún ayé ṣe.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Òwe

Wà á rí ọ̀nà ọgbọ́n tó o lè gbà ṣe nǹkan ní ìgbésí ayé rẹ látori iṣẹ́ oúnjẹ ọ̀jọ́ títí kan ọ̀rọ̀ ìdílé.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Oníwàásù

Ọba Sólómọ́nì sọ àwọn ohun tó ṣe pàtàkì nígbèésí ayé ẹ̀dá, ó sì fi wọ́n wéra pẹ̀lú àwọn ohun tó lòdì sí ọgbọ́n Ọlọ́run.

Ohun Tó Wà Nínú Orin Sólómọ́nì

Bíbélì pe ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí ọ̀dọ́bìnrin Ṣúlámáítì ní sí ọ̀dọ́kùnrin olùṣọ́ àgùntàn kan ní “ọwọ́ iná Jáà.” Kí nìdí?

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Aísáyà

Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó jóòótọ́ délẹ̀délẹ̀ ló wà nínú ìwé Aísáyà, ó sì mú ká túbọ̀ fọkàn balẹ̀ pé gbogbo ohun tí Jèhófà sọ ló máa ṣẹ, ó sì máa gbà wá là.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jeremáyà

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jeremáyà kojú ìṣòro tó lágbára gan-an, kò kúrò nídìí iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún un. Ronú nípa bí àwa Kristẹni ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ lóde òní.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìdárò

Wòlíì Jeremáyà ló kọ ìwé Ìdárò, ó kédàárò nítorí ìparun Jerúsálẹ́mù, ó sì tún jẹ́ ká rí i pé Ọlọ́run máa ń ṣàánú àwọn ẹlẹ́sẹ̀ tó bá ronú pìwà dà.

Ohun Tó wà Nínú Ìwé Ìsíkíẹ́lì

Ìsíkíẹ́lì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó sì máa ń fi ìgboyà ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tí Jèhófà bá gbé fún un, láìka bí iṣẹ́ náà ṣe nira tó. Àpẹẹrẹ àtàtà ló jẹ́ fún wa lónìí.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Dáníẹ́lì

Dáníẹ́lì àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà ní gbogbo ọ̀nà. Àpẹẹrẹ wọn àti bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà ṣe ní ìmúṣẹ lè ṣe àwa tá a wà láyé ní àkókò òpin yìí láǹfààní.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Hóséà

A lè rí ẹ̀kọ́ pàtàkì kọ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ Hóséà lóde òní. Ó sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe máa ń ṣàánú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà àti irú ìjọsìn tó tẹ́wọ́ gbà.

Ohun Tó wà Nínú Ìwé Jóẹ́lì

Jóẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ nípa “ọjọ́ Jèhófà” tó máa tó dé àti àwọn ohun tá a lè ṣe láti là á já. Ó túbọ̀ ṣe pàtàkì gan-an lóde òní pé ká fi àsọtẹ́lẹ̀ yìí sọ́kàn.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ámósì

Jèhófà gbé iṣẹ́ pàtàkì kan fún ọkùnrin onírẹ̀lẹ̀ yìí. Ohun pàtàkì wo la lè rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Ámósì?

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ọbadáyà

Ìwé yìí ló kéré jù nínú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù tàbí Májẹ̀mú Láéláé. Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń fúnni nírètí, ó sì ń fini lọ́kàn balẹ̀ pé ìṣàkóso Jèhófà ló máa lékè

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jónà

Wolíì náà gba ìbáwí, ó ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún un ní àṣeyanjú, ó sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti àánú Ọlọ́run. Ìtàn Jónà máa wọ̀ ẹ́ lọ́kàn gan-an.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Míkà

Àsọtélẹ̀ tí Ọlọ́run mí sí yìí á jẹ́ kí ọkàn rẹ túbọ̀ balẹ̀ pé àwọn nǹkan tí Jèhófà sọ pé ká máa ṣe kì í ṣe ohun tó pọ̀ ju agbára wa lọ, àǹfààní wa ni wọ́n sì wà fún.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Náhúmù

Àsọtẹ́lẹ̀ yìí fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé ọ̀rọ̀ Jèhófà ò ní lọ láìṣẹ àti pé ó máa ń tu àwọn tó ń wá àláàfíà àti ìgbàlà lábẹ́ Ìjọba rẹ̀ nínú.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Hábákúkù

Ọkàn wa balẹ̀ pé ìgbà gbogbo ni Jèhófà mọ àkókò tó dáa jù àti ọ̀nà tó dáa jù láti gba àwọn èèyàn rẹ̀ là.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Sefanáyà

Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣọ́ra, ká má ṣe máa ronú pé ọjọ́ Jèhófà ò ní dé?

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Hágáì

Àsọtẹ́lẹ̀ yìí sọ sọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká fi ìjọsìn Jèhófà ṣáájú àwọn nǹkan ti ara wa.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Sekaráyà

Ọ̀pọ̀ ìran àtàwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run mí sí fún àwọn èèyàn Ọlọ́run lókun nígbà àtijọ́. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣì ń fi àwa èèyàn Jèhófà lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà wà lẹ́yìn wà lóde òní.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Málákì

Ó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ tó dá lórí ìlànà, àánú, àti ìfẹ́ Jèhófà. Àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tó wúlò gan-an fún wa lóde òní tún wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ náà.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Mátíù

Wàá gbádùn àwọn nǹkan pàtàkì tó wà nínú ìwé Mátíù tó jẹ́ àkọ́kọ́ nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Máàkù

Ìwé Máàkù ló kéré jù lára àwọn ìwé Ìhìn Rere, ó sì jẹ́ ká mọ àwọn ohun tí Jésù máa gbé ṣe tó bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Lúùkù

Àwọn ìsọfúnni wo ló wà nínú ìhìn rere Lúùkù to mú kó ṣàrà ọ̀tọ̀?

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jòhánù

Àkọsílẹ̀ Jòhánù jẹ́ ká rí i pé Jésù nífẹ̀ẹ́ gbogbo aráyé, ó tún sọ̀rọ̀ nípa ìwà ìrẹ̀lẹ̀ Jésù àtàwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé òun ni Mèsáyà, Ọba Ìjọba Ọlọ́run.

Mọ Púpọ̀ Sí I

ÀWỌN ÌWÉ ŃLÁ ÀTÀWỌN ÌWÉ PẸLẸBẸ

Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?

Kí ni lájorí ẹ̀kọ́ tá a lè kọ́ nínú Bíbélì?