Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

FÍDÍÒ ÀWỌN Ẹ̀KỌ́

Fídíò Tó Dá Lórí Bíbélì—Ẹ̀kọ́ Pàtàkì

Àwọn fídíò kéékèèké yìí dáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì látinú Bíbélì, ó sì tan mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ inú ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!

Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!

Kí ni ìròyìn àyọ̀ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run? Kí nìdí tó fi yẹ ká gbà á gbọ́? Ìwé yìí dáhùn àwọn ìbéèrè tí ọ̀pọ̀ èèyàn sábà máa ń béèrè nípa Bíbélì.

Ṣé Ọlọ́run ní Orúkọ?

Ọlọ́run ní ọ̀pọ̀ orúkọ oyè, lára rẹ̀ ni Olódùmarè, Ẹlẹ́dàá, àti Olúwa. Fídíò yìí sọ orúkọ Ọlọ́run gangan èyí tó fara hàn ní ibi tó lé ni ẹgbẹ̀rún méje [7,000] nínú Bíbélì.

Ta Ni Òǹṣèwé Bíbélì?

Tó bá jẹ́ pé èèyàn ló kọ ọ́, ṣé a wá lè pè é ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Èrò ta ló wà nínú Bíbélì?

Ṣe Òótọ́ Ni Ọ̀rọ̀ Inú Bíbélì?

Tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run ló ni Bíbélì, á jẹ́ pé kò sí ìwé míì tá a lè fi í wé.

Kí Nìdí Tí Jésù Fi Kú?

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ikú Jésù ṣe pàtàkì gan-an. Ṣé àǹfààní kankan wà nínú ikú Jésù?

Kí Ni Ìdí Tí Ọlọ́run Fi Dá Ayé?

Ayé yìí rẹwà gan-an ni. Kò sún mọ́ oòrùn jù, kò sì jìnnà sí i jù, ibi tó yẹ gẹ́lẹ́ ló rọra dagun sí, ńṣe ló sì ń yípo ní ìwọ̀n tó yẹ gẹ́lẹ́. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá ayé lọ́nà tó dára tó bẹ́ẹ̀ tó sì tún ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan ribiribi sínú rẹ̀?

Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ sí Àwọn Tó Ti Kú?

Bíbélì sọ pé ìgbà kan ń bọ̀ tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa jí dìde, gẹ́gẹ́ bí Lásárù ṣe jí dìde.

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

Nígbà tí Jésù wà láyé, ẹ̀kọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run ló kọ́ àwọn èèyàn jù lọ. Ọjọ́ pẹ́ táwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ti ń gbàdúrà pé kí Ìjọba yẹn dé.