Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Atọ́nà Ìkẹ́kọ̀ọ́

Wa àwọn atọ́nà ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí jáde, kó o wá fi òun àti ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? kẹ́kọ̀ọ́. Ṣàyẹ̀wò ohun tó o gbà gbọ́, wo ohun tí Bíbélì fi kọ́ni, kó o sì kọ́ bó o ṣe lè ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́.

 

Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?

A ṣe ìwé tá a fi ń kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ Bíbélì yìí kí o lè mọ onírúurú ẹ̀kọ́ Bíbélì, bí ìdí tí a fi ń jìyà, ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ téèyàn bá kú, bí ìdílé wa ṣe lè jẹ́ aláyọ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Kí Ni Òtítọ́ Nípa Irú Ẹni Tí Ọlọ́run Jẹ́? (Apá 1)

Kí lo máa sọ tí ẹnì kan bá sọ pé “Ọlọ́run ló máa ń mú kí ìyà jẹ àwọn èèyàn burúkú”?

Kí Ni Òtítọ́ Nípa Irú Ẹni Tí Ọlọ́run Jẹ́? (Apá 2)

Ṣé ó ṣeé ṣe kéèyàn di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run lóòótọ́?

Bíbélì—Ìwé Kan Tó Wá Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run (Apá 1)

Àwọn èèyàn ló kọ Bíbélì, báwo ló ṣe wá jẹ́ ‘ìwé tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run’?

Bíbélì—Ìwé Kan Tó Wá Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run (Apá 2)

Wo ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ẹ̀rí tó jẹ́ kó dà àwọn èèyàn lójú pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì ti wá.

Kí Ni Ọlọ́run Ní Lọ́kàn Tó Fi Dá Ilẹ̀ Ayé? (Apá 1)

Ṣé bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kí ayé rí ló rí yìí?

Kí Ni Ọlọ́run Ní Lọ́kàn Tó Fi Dá Ilẹ̀ Ayé? (Apá 2)

Tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run fẹ́ kí ayé di párádísè, kí ló dé tí ayé yìí ṣì rí bó ṣe rí yìí?

Kí Ni Ọlọ́run Ní Lọ́kàn Tó Fi Dá Ilẹ̀ Ayé? (Apá 3)

Ṣé Ọlọ́run ní in lọ́kàn láti yanjú ìṣòro aráyé?

Ta Ni Jésù Kristi? (Apá 1)

Kí lo máa sọ tí ẹni kan bá sọ pé ẹni rere ni Jésù wulẹ̀ jẹ́?

Ta Ni Jésù Kristi? (Apá 2)

Kí lo máa sọ tí ẹnì kan bá sọ pé Jésù bá Ọlọ́run dọ́gba?

ORÍ 4

Ta Ni Jésù Kristi? (Apá 3)

Báwo ni ó ṣe fi hàn lọ́nà tó ṣe rẹ́gí pé òun jẹ́ alágbára àti oníwà pẹ̀lẹ́?

Ìràpadà—Ẹ̀bùn Tó Ṣeyebíye Jù Lọ Tí Ọlọ́run Fúnni (Apá 1)

Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí èèyàn ìgbàlà nípa ṣíṣe iṣẹ́ ìgbàgbọ́?

Ìràpadà—Ẹ̀bùn Tó Ṣeyebíye Jù Lọ Tí Ọlọ́run Fúnni (Apá 2)

Báwo ni ikú ẹnì kan láìmọye ọdún sẹ́yìn ṣe lè ṣe ọ́ láǹfààní lónìí?

Ibo Làwọn Òkú Wà? (Apá 1)

Ṣé ibì kan ni wọ́n ń gbé ni? Sé wọ́n ń joró ní ọ̀run àpáàdì ni?

Ibo Làwọn Òkú Wà? (Apá 2)

Ṣé Ọlọ́run ti kádàrá ikú mọ́ àwa èèyàn?

Ojúlówó Ìrètí Fáwọn Èèyàn Rẹ Tó Ti Kú (Apá 1)

Tí èèyàn rẹ bá kú, tó o wá ń banú jẹ́, ṣé ó túmọ̀ sí pé o ò nígbàgbọ́ nínú àjíǹde ni?

Ojúlówó Ìrètí Fáwọn Èèyàn Rẹ Tó Ti Kú (Apá 2)

Báwo ni wà á ṣe fèsì fún ẹni tó sọ pé irọ́ tó jìnnà sí òótọ́ ni ọ̀rọ̀ àjíǹde?

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run? (Apá 1)

Kí nìdí tí Ọlọ́run fi máa yan àwọn èèyàn láti ṣàkóso bí ọba lọ́run nígbà tó ní àìmọye àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ tó lè yàn?

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run? (Apá 2)

Kí ni àwọn nǹkan tí Ìjọba Ọlọ́run ti gbé ṣe? Kí làwọn nǹkan tó máa ṣe lọ́jọ́ iwájú?

Ṣé “Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn” La Wà Yìí? (Apá 1)

Ó ṣòro fáwọn kan láti gbà pé a ti ń gbé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Kí làwọn ohun tó o rí tó o fi gbà pé ètò nǹkan yìí kò ní pẹ́ dópin?

Ṣé “Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn” La Wà Yìí? (Apá 2)

Bíbélì sọ nípa àwọn nǹkan rere tó máa ṣẹlẹ̀ ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.

Àwọn Ẹ̀dá Ẹ̀mí—Ohun Tí Wọ́n Ń Ṣe fún Wa (Apá 1)

Ṣé àwọn áńgẹ́lì wà lóòótọ́? Ṣé àwọn áńgẹ́lì búburú wà? Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí á jẹ́ kó o mọ ìdáhùn.

Àwọn Ẹ̀dá Ẹ̀mí​—Ohun Tí Wọ́n Ń Ṣe fún Wa (Apá 2)

Kí ló burú nínú kéèyàn fẹ́ máa bá àwọn ẹ̀mí àìrí sọ̀rọ̀?

Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ìyà Tó Ń Jẹ Aráyé? (Apá 1)

Tó bá jẹ́ pé kò sẹ́ni tó lágbára bí Ọlọ́run, ta ló tún wá lè máa fa gbogbo ohun búburú tó ń ṣẹlẹ̀ tí kì í bá ṣe òun?

Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ìyà Tó Ń Jẹ Aráyé? (Apá 2)

Ìwé Mímọ́ fún wa ní ìdáhùn tó ṣe kedere, tó sì ń tẹ́ni lọ́rùn sí ìbéèrè tó ta kókó yìí.

Gbé Ìgbé Ayé Tó Múnú Ọlọ́run Dùn (Apá 1)

Ṣé o lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run? Ṣàyẹ̀wò ohun tó o gbà gbọ́ àti ìdí tó o fi gbà á gbọ́, kó o sì wo ohun tí Bíbélì fi kọ́ni.

Gbé Ìgbé Ayé Tó Múnú Ọlọ́run Dùn (Apá 2)

Ṣé a lè múnú Ọlọ́run dùn bí Sátánì tiẹ̀ ń da ìṣòro sí wa lágbada?

Gbé Ìgbé Ayé Tó Múnú Ọlọ́run Dùn (Apá 3)

Ó gba ìsapá kéèyàn tó lè máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà inú Bíbélì. Àmọ́ ṣé àǹfààní wà níbẹ̀?

Ojú Tí Ọlọ́run Fi Ń Wo Ẹ̀mí Ni Kí Ìwọ Náà Máa Fi Wò Ó (Apá 1)

Ẹ̀mí jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Báwo la ṣe lè fi hàn pé ẹ̀mí ara wa àti ti àwọn ẹlòmíì jọ wá lójú?

Ojú Tí Ọlọ́run Fi Ń Wo Ẹ̀mí Ni Kí Ìwọ Náà Máa Fi Wò Ó (Apá 2)

Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí máa jẹ́ kó o ṣàyẹ̀wò ohun tó o gbà gbọ́ lórí ọ̀rọ̀ fífa ẹ̀jẹ̀ síni lára àti bó ṣe yẹ ká máa lo ẹ̀jẹ̀ àti ọ̀rọ̀ fífa ẹ̀jẹ̀ síni lára, á sì tún jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn míì.

ORÍ 14

Ohun Tó O Lè Ṣe Kí Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀ (Apá 1)

Kí ló lè mú kí ìgbéyàwó láyọ̀? Ṣàyẹ̀wò ohun tó o gbà gbọ́, wo ohun tí Bíbélì fi kọ́ni, kó o sì mọ bí wàá ṣe fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn míì.

Ohun Tó O Lè Ṣe Kí Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀ (Apá 2)

Àǹfààní wo ni àpẹẹrẹ Jésù lè ṣe àwọn òbí àtàwọn ọmọ? Ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tó o gbà gbọ́ àti ohun tí Bíbélì sọ.

Ìjọsìn Tó Ní Ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run (Apá 1)

Ṣé gbogbo ìsìn ni Ọlọ́run fọwọ́ sí? Tí kì í bá ṣe gbogbo wọn, báwo lo ṣe lè dá ìsìn tòótọ́ mọ̀? Wo ohun tí Bíbélì fi kọ́ni, kó o sì ṣàyẹ̀wò ohun tó o gbà gbọ́.

Ìjọsìn Tó Ní Ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run (Apá 2)

Téèyàn bá fẹ́ rí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run, ṣé kéèyàn kàn gbà á gbọ́ nìkan tó? Àbí ohun tí Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ àwọn tó ń sìn ín jù bẹ́ẹ̀ lọ?

Fi Hàn Pé Ìsìn Tòótọ́ Lo Fẹ́ Ṣe (Apá 1)

Ṣé Ọlọ́run fọwọ́ sí i ká máa ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí, àwọn ayẹyẹ ìsìn, ká sì máa lo ère tá a bá ń jọ́sìn? Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló máa jẹ́ ká mọ ìdáhùn?

Fi Hàn Pé Ìsìn Tòótọ́ Lo Fẹ́ Ṣe (Apá 2)

Báwo lo ṣe lè fọgbọ́n ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn míì, kó o sì fọ̀wọ̀ àwọn míì wọ̀ wọ́n lórí ohun tí wọ́n gbà gbọ́?

Sún Mọ́ Ọlọ́run Nípasẹ̀ Àdúrà (Apá 1)

Báwo lo ṣe lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run? Báwo lo ṣe lè mọ̀ bóyá lóòótọ́ ló ń gbọ́ àdúrà ẹ?

Sún Mọ́ Ọlọ́run Nípasẹ̀ Àdúrà (Apá 2)

Wo ohun tí Bíbélì sọ nípa bó ṣe yẹ ká máa gbàdúrà àti ìgbà tó yẹ ká gbàdúrà.

Sún Mọ́ Ọlọ́run Nípasẹ̀ Àdúrà (Apá 3)

Bíbélì fi kọ́ wa pé oríṣiríṣi ọ̀nà ni Ọlọ́run máa ń gbà dáhùn àdúrà. Ọ̀nà wo ló lè gbà dáhùn àdúrà ẹ, ìgbà wo ló sì lè dáhùn ẹ̀?

Ìrìbọmi Ló Máa Fìdí Àjọṣe Rẹ Pẹ̀lú Ọlọ́run Múlẹ̀ (Apá 1)

Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì káwọn Kristẹni ṣèrìbọmi? Kí ló yẹ kó sún àwọn Kristẹni ṣèrìbọmi?

Ìrìbọmi Ló Máa Fìdí Àjọṣe Rẹ Pẹ̀lú Ọlọ́run Múlẹ̀ (Apá 2)

Kí làwọn ohun tí Kristẹni kan gbọ́dọ̀ ṣe kó tó ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà? Lẹ́yìn tó bá ya ara rẹ̀ sí mímọ́, ipa wo nìyẹn máa ní lórí gbogbo ìpinnu tó bá fẹ́ máa ṣe?

Ìrìbọmi Ló Máa Fìdí Àjọṣe Rẹ Pẹ̀lú Ọlọ́run Múlẹ̀ (Apá 3)

Kí ni Ọlọ́run fẹ́ kí ẹni tó ti ṣe ìyàsímímọ́ máa ṣe? Kí nìdí tó fi yẹ kó dá àwọn Kristẹni tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tọkàntọkàn lójú pé àwọn á lè máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run?

Má Ṣe Kúrò Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run (Apá 1)

Báwo lo ṣe lè máa ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà? Atọ́nà ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣàyẹ̀wò ohun tó o gbà gbọ́, kó o sì lè ṣàlàyé rẹ̀ fún àwọn ẹlòmíì.