Rárá o. Tá a bá fi àwọn ìwé àfọwọ́kọ àtijọ́ wéra, ó jẹ́ ká rí i pé àwọn ohun tó wà nínú Bíbélì ò yí pa dà bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn ni wọ́n ti ń ṣe àdàkọ rẹ̀ sórí àwọn nǹkan ìkọ̀wé tó lè bà jẹ́.

Ṣó túmọ̀ sí pé àwọn tó da Bíbélì kọ ò ṣàṣìṣe rárá ni?

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé àfọwọ́kọ Bíbélì làwọn èèyàn ti wá rí. Ìyàtọ̀ díẹ̀díẹ̀ wà nínú àwọn kan, tó fi hàn pé àwọn tó dà á kọ ṣàṣìṣe nígbà tí wọ́n ń kọ ọ́. Ìyàtọ̀ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ ló pọ̀ jù, àwọn ìyàtọ̀ yìí ò sì yí ìtumọ̀ ohun tí Bíbélì sọ pa dà. Àmọ́, a ti rí àwọn ibi mélòó kan tó yàtọ̀ gan-an, ó sì jọ pé ṣe làwọn tó dà á kọ lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn yẹn fẹ́ mọ̀ọ́mọ̀ yí ohun tí Bíbélì sọ pa dà láwọn ibì kan. Wo àpẹẹrẹ méjì yìí:

  1. 1 Jòhánù 5:7, ohun tó wà nínú àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì kan tó ti pẹ́ ni pé: “ní ọ̀run, Baba, Ọ̀rọ̀ náà àti Ẹ̀mí Mímọ́: àwọn mẹ́ta yìí sì jẹ́ ọ̀kan.” Àmọ́ àwọn ìwé àfọwọ́kọ tó ṣeé fọkàn tán jẹ́ kó dá wa lójú pé àwọn ọ̀rọ̀ yìí ò sí nínú Bíbélì tí wọ́n kọ níbẹ̀rẹ̀. Àwọn èèyàn ló fìyẹn kún un. * Torí ẹ̀ ló ṣe jẹ́ pé a ò lè rí àwọn ọ̀rọ̀ yẹn nínú àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì òde òní tó ṣeé fọkàn tán.

  2. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìgbà ni orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́ gangan fara hàn nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ Bíbélì àtijọ́. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ìtúmọ̀ Bíbélì ló ti fi àwọn orúkọ oyè bí “Olúwa” tàbí “Ọlọ́run” rọ́pò orúkọ Ọlọ́run.

Ṣe kì í ṣe pé ọ̀pọ̀ àṣìṣe míì ló ṣì wà táwọn èèyàn ò tíì rí?

Lásìkò wa yìí, ìwé àfọwọ́kọ táwọn èèyàn ti wá rí ti pọ̀ gan-an, ìyẹn sì ti mú kó rọrùn ju tàtẹ̀yìnwá lọ láti rí àṣìṣe tó bá wà. * Nígbà tá a fi àwọn ìwé yìí wéra, kí ló jẹ́ ká mọ̀ nípa bí ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ṣe péye tó lónìí?

  • Ọ̀mọ̀wé William H. Green sọ̀rọ̀ lórí ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù (táwọn èèyàn ń pè ní “Májẹ̀mú Láéláé”), ó ní: “A lè fi gbogbo ẹnu sọ ọ́ pé kò sí iṣẹ́ kankan tí wọ́n ṣe láyé àtijọ́ tó ṣì péye títí dòní bí èyí.”

  • Ọ̀mọ̀wé F. F. Bruce kọ̀wé nípa Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, tí wọ́n tún ń pè ní “Májẹ̀mú Tuntun,” ó ní: “Ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló wà tó fi hàn pé àwọn ìwé inú Májẹ̀mú Tuntun lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ dáadáa ju ìwé tí ọ̀pọ̀ àwọn òǹkọ̀wé pàtàkì-pàtàkì kọ, bẹ́ẹ̀ sì rèé, kò sẹ́ni tó jẹ́ yẹ àwọn òǹkọ̀wé yìí lọ́wọ́ wò láti mọ̀ bóyá òótọ́ ni wọ́n kọ àbí bẹ́ẹ̀ kọ́.”

  • Sir Frederic Kenyon, tó jẹ́ aláṣẹ pàtàkì lórí ọ̀rọ̀ àwọn ìwé àfọwọ́kọ Bíbélì sọ pé èèyàn “lè mú Bíbélì lódindi dání, kó sì sọ láìbẹ̀rù, láìkọ́ ọ lẹ́nu, pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó jóòótọ́ lòun mú dání, ìwé tí ohun tó wa nínú ẹ̀ ò yí pa dà ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún tó ti wà láti ìrandíran.”

Àwọn ohun míì wo ló jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ pé ohun tó wà nínú Bíbélì ò yí pa dà?

  • Àwọn Júù àtàwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ adàwékọ ò ṣe àyípadà sí ìtàn àwọn àṣìṣe ńlá táwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe nínú Bíbélì. * (Númérì 20:12; 2 Sámúẹ́lì 11:​2-4; Gálátíà 2:​11-​14) Ohun kan náà ni wọ́n ṣe sí àwọn ìtàn tó dá lórí bí Ọlọ́run ṣe dá àwọn Júù lẹ́bi torí wọ́n jẹ́ aláìgbọràn àti bí a ṣe túdìí àṣírí àwọn ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́. (Hóséà 4:2; Málákì 2:​8, 9; Mátíù 23:​8, 9; 1 Jòhánù 5:​21) Bí àwọn adàwékọ yìí ò ṣe yí àwọn àkọsílẹ̀ yìí pa dà fi hàn pé wọ́n ṣeé fọkàn tán, wọ́n sì ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó jẹ́ mímọ́ sí pàtàkì gan-an.

  • Ṣé kò bọ́gbọ́n mu lóòótọ́ pé, Ọlọ́run tó mí sí Bíbélì náà tún máa rí sí i pé ohun tó wà nínú ẹ̀ ò yí pa dà? * (Aísáyà 40:8; 1 Pétérù 1:​24, 25) Ó ṣe tán, kì í ṣe àwọn èèyàn ìgbà àtijọ́ nìkan ni Ọlọ́run fẹ́ kí ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ ṣe láǹfààní, ó tún fẹ́ kí àwa èèyàn lóde òní náà jàǹfààní látinú ẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 10:11) Kódà, “gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa, pé nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí.”​—Róòmù 15:4.

  • Jésù àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù táwọn èèyàn fọwọ́ dà kọ láì máa rò ó bóyá àwọn ọ̀rọ̀ àtijọ́ yẹn jóòótọ́ àbí kò jóòótọ́.​—Lúùkù 4:​16-​21; Ìṣe 17:​1-3.

^ ìpínrọ̀ 5 A ò lè rí àwọn ọ̀rọ̀ yìí nínú ìwé Codex Sinaiticus, Codex Alexandrinus, Vatican Manuscript 1209, Bíbélì Vulgate tí wọ́n kọ ní èdè Latin ìbẹ̀rẹ̀, Bíbélì Philoxenian-Harclean Syriac Version, àbí nínú Bíbélì Syriac Peshitta.

^ ìpínrọ̀ 8 Bí àpẹẹrẹ, ó lé ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún [5,000] ìwé àfọwọ́kọ lédè Gíríìkì, tí wọ́n ń pè ní Májẹ̀mú Tuntun tàbí Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, táwọn èèyàn ti wá rí.

^ ìpínrọ̀ 13 Bíbélì ò sọ pé àwọn èèyàn tó ń ṣojú fún Ọlọ́run ò lè ṣàṣìṣe. Bó ṣe rí gẹ́lẹ́ ló sọ ọ́, ó ní: “Kò sí ènìyàn tí kì í dẹ́ṣẹ̀.”​—1 Àwọn Ọba 8:​46.

^ ìpínrọ̀ 14 Bíbélì sọ pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ò pe gbogbo ohun tó fẹ́ kí wọ́n kọ sínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan, ó darí èrò àwọn èèyàn tó kọ ọ́.​—2 Tímótì 3:​16, 17; 2 Pétérù 1:​21.