Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ṣé Ọ̀kan Náà Ni Gbogbo Ìsìn? Ǹjẹ́ Gbogbo Rẹ̀ Ni Ọlọrun Tẹ́wọ́ Gbà?

Ṣé Ọ̀kan Náà Ni Gbogbo Ìsìn? Ǹjẹ́ Gbogbo Rẹ̀ Ni Ọlọrun Tẹ́wọ́ Gbà?

Ohun tí Bíbélì sọ

Rárá, gbogbo ìsìn kì í ṣe ọ̀kan náà. Nínú Bíbélì, a rí àpẹẹrẹ àwọn ìsìn tí inú Ọlọ́run kò dùn sí. Apá méjì sì ni àwọn ìsìn yìí pín sí.

Apá kìíní: Àwọn tó ń jọ́sìn ọlọ́run èké

Bíbélì lo àwọn ọ̀rọ̀ bí “èémí àmíjáde lásán,” “asán,” àti “àwọn nǹkan tí kò ní àǹfààní” láti fi ṣàpèjúwe ìjọsìn ọlọ́run èké. (Jeremáyà 10:3-5; 16:19, 20) Jèhófà * Ọlọ́run pàṣẹ fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ní àwọn ọlọ́run èyíkéyìí mìíràn níṣojú mi.” (Ẹ́kísódù 20:3, 23; 23:24) ‘Ìbínú Jèhófà ru’ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn àwọn ọlọ́run mìíràn.Númérì 25:3; Léfítíkù 20:2; Àwọn Onídàájọ́ 2:13, 14.

Ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìjọsìn ‘àwọn tí wọ́n ń pè ní ọlọ́run’ kò tíì yí pa dà. (1 Kọ́ríńtì 8:5, 6; Gálátíà 4:8) Ó pàṣẹ fún àwọn tó fẹ́ jọ́sìn rẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú àwọn tó ń ṣe ìsìn èké, ó ní: “Ẹ jáde kúrò láàárín wọn, kí ẹ sì ya ara yín sọ́tọ̀.” (2 Kọ́ríńtì 6:14-17) Tó bá jẹ́ pé ọ̀kan náà ni gbogbo ìsìn, tí Ọlọ́run sì tẹ́wọ́ gbà gbogbo wọn, kí wá nìdí tí Ọlọ́run fi pa irú àṣẹ yìí?

Apá kejì: Àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ lọ́nà tí kò tẹ́wọ́ gbà

Nígbà míì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń tẹ̀ lé àṣà àwọn tó ń ṣe ìsìn èké tí wọ́n bá ń jọ́sìn Ọlọ́run, ṣùgbọ́n Jèhófà kò nífẹ̀ẹ́ sí bí wọ́n ṣe fẹ́ máa da ìsìn tòótọ́ pọ̀ mọ́ ìsìn èké. (Ẹ́kísódù 32:8; Diutarónómì 12:2-4) Jésù bẹnu àtẹ́ lu àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ìgbà ayé rẹ̀ torí ọ̀nà tí wọ́n gbà jọ́sìn Ọlọ́run; wọ́n máa ń ṣe bí ẹni pé ọ̀nà tó tọ́ ni wọ́n ń gbà jọ́sìn Ọlọ́run, síbẹ̀ “wọ́n ṣàìka àwọn ọ̀ràn wíwúwo jù lọ nínú Òfin sí, èyíinì ni, ìdájọ́ òdodo àti àánú àti ìṣòtítọ́.”Mátíù 23:23.

Bákan náà lóde òní, ìsìn tó ń fi òtítọ́ kọ́ni nìkan ló máa jẹ́ káwọn èèyàn mọ Ọlọ́run. Inú Bíbélì sì ni òtítọ́ yìí wà. (Jòhánù 4:24; 17:17; 2 Tímótì 3:16, 17) Ẹ̀sìn tó ń kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ tó ta ko Bíbélì kì í jẹ́ káwọn èèyàn fẹ́ mọ Ọlọ́run. Àwọn ẹ̀kọ́ bíi Mẹ́talọ́kan, àìleèkú ọkàn àti ìdálóró ayérayé táwọn èèyàn rò pé ó wà nínú Bíbélì jẹ́ ara àwọn ẹ̀kọ́ èké tó wà látọ̀dọ̀ àwọn tó ń jọ́sìn ọlọ́run èké. Ẹ̀sìn tí kò wúlò tàbí tó jẹ́ ‘asán’ ni ìsìn tó ń fi irú àwọn ẹ̀kọ́ yìí kọ́ni jẹ́ torí pé ó ń fi àwọn àṣà ìsìn kọni dípò àṣẹ Ọlọ́run.Máàkù 7:7, 8.

Ọlọ́run kórìíra àgàbàgebè inú ẹ̀sìn. (Títù 1:16) Kí àwọn èèyàn tó lè sún mọ́ Ọlọ́run, ó yẹ kí ìsìn tí wọ́n ń ṣe yí ìgbésí ayé wọn pa dà sí rere. Kì í kàn ṣe kí wọ́n máa ṣe ààtò ẹ̀sìn tàbí kí wọ́n máa fi ẹnu lásán jọ́sìn Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé: “Bí ọkùnrin èyíkéyìí lójú ara rẹ̀ bá dà bí olùjọsìn ní irú ọ̀nà kan, síbẹ̀ tí kò kó ahọ́n rẹ̀ níjàánu, ṣùgbọ́n tí ó ń bá a lọ ní títan ọkàn-àyà ara rẹ̀ jẹ, ọ̀nà ìjọsìn ọkùnrin yìí jẹ́ ìmúlẹ̀mófo. Ọ̀nà ìjọsìn tí ó mọ́, tí ó sì jẹ́ aláìlẹ́gbin ní ojú ìwòye Ọlọ́run àti Baba wa ni èyí: láti máa bójú tó àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn opó nínú ìpọ́njú wọn, àti láti pa ara ẹni mọ́ láìní èérí kúrò nínú ayé.” (Jákọ́bù 1:26, 27) “Ìsìn mímọ́” ni Bíbélì Mímọ́ pe irú ìjọsìn tó mọ́ yìí, tí kò sì ní àgàbàgebè nínú.

^ ìpínrọ̀ 5 Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run tòótọ́ ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Bíbélì sọ.