Ohun Tí Bíbélì Sọ

Kò tí i sí ènìyàn tó rí Ọlọ́run rí. (Ẹ́kísódù 33:20; Jòhánù 1:18; 1 Jòhánù 4:12) Bíbélì sọ pé “Ọlọ́run jẹ́ Ẹ̀mí,” ìyẹn ẹ̀dá téèyàn kò lè fojú rí.Jòhánù 4:24; 1 Tímótì 1:17.

Àwọn Áńgẹ́lì lè rí Ọlọ́run, torí pé àwọn náà jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí bíi tirẹ̀. (Mátíù 18:10) Bákan náà, lẹ́yìn táwọn ẹ̀dá èèyàn kan bá kú wọ́n máa jí dìde sí ọ̀run gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí, wọ́n á sì lè rí Ọlọ́run sójú.Fílípì 3:20, 21; 1 Jòhánù 3:2.

Bá a ṣe lè “rí” Ọlọ́run

Bíbélì máa ń lo ojú lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ohun tó sì máa ń ṣàpẹẹrẹ ni ìlàlóye. (Aísáyà 6:10; Jeremáyà 5:21; Jòhánù 9:39-41) Nítorí náà, ẹnìkan lè fi “ojú ọkàn-àyà” rí Ọlọ́run nípa níní ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀ kó lè mọ̀ ọ́n kó sì mọ rírì àwọn ànímọ́ Rẹ̀. (Éfésù 1:18) Bíbélì sọ àwọn ìgbésẹ̀ tá a lè gbé ká lè ní irú ìgbàgbọ́ yìí.

  • Kọ́ nípa àwọn ànímọ́ Ọlọ́run lára bíi ìfẹ́, ọ̀làwọ́, ọgbọ́n àti agbára lára àwọn ohun tó dá. (Róòmù 1:20) Lẹ́yìn tí ọkùnrin olóòótọ́ náà Jóòbù kíyè sí àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá, ohun tó sọ ni pé òun ti rí Ọlọ́run.Jóòbù 42:5.

  • Mọ Ọlọrun nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bíbélì gbà wá níyànjú pé: “Bí ìwọ bá wá a [Ọlọ́run], yóò jẹ́ kí o rí òun.”1 Kíróníkà 28:9; Sáàmù 119:2; Jòhánù 17:3.

  • Kọ́ nípa Ọlọ́run lára Jésù. Nígbà tó jẹ́ pé Jésù fìwà jọ Bàbá rẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run lọ́nà tó ṣe rẹ́gí, ẹnu gbà á láti sọ pé: “Ẹni tí ó ti rí mi ti rí Baba pẹ̀lú.”Jòhánù 14:9.

  • Gbé ìgbé ayé rẹ lọ́nà tó máa múnú Ọlọ́run dùn, kó o sì rí bí yóò ṣe ràn ẹ́ lọ́wọ́. Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn ẹni mímọ́ gaara ní ọkàn-àyà, níwọ̀n bí wọn yóò ti rí Ọlọ́run.” Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ níṣàájú, àwọn tí wọ́n múnú Ọlọ́run dùn máa jí dìde sí ọ̀run wọ́n á “rí Ọlọ́run” níbẹ̀.Mátíù 5:8; Sáàmù 11:7.

Ṣé Mósè, Ábúráhámù, àtàwọn míì kò rí Ọlọ́run ni?

Nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tó sọ pé àwọn èèyàn rí Ọlọ́run, àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ ṣáájú tàbí lẹ́yìn àwọn ẹsẹ Bíbélì náà fi hàn pé áńgẹ́lì ni wọ́n rí tàbí kó jẹ́ pé wọ́n rí Ọlọ́run nípasẹ̀ ìran.

Áńgẹ́lì

. Láyé àtijọ́, Ọlọ́run máa ń rán àwọn áńgẹ́lì láti lọ ṣojú òun lọ́dọ̀ àwọn èèyàn kí wọ́n sì dárúkọ òun níbẹ̀. (Sáàmù 103:20) Bí àpẹẹrẹ, nígbà kan tí Ọlọ́run ń bá Mósè sọ̀rọ̀ níbi igi kan tó ń jó, Bíbélì sọ pé “Mósè fi ojú rẹ̀ pa mọ́, nítorí pé àyà fò ó láti wo Ọlọ́run tòótọ́.” (Ẹ́kísódù 3:4, 6) Kì í ṣe pé Mósè rí Ọlọ́run sójú, torí àwọn ọ̀rọ̀ tí ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ ṣáájú fi hàn pé “áńgẹ́lì Jèhófà” ló rí.Ẹ́kísódù 3:2.

Bákan náà, nígbà tí Bíbélì sọ pé Ọlọ́run “bá Mósè sọ̀rọ̀ ní ojúkojú,” ohun tó túmọ̀ sí ni pé Ọlọ́run bá Mósè sọ̀rọ̀ ní tààràtà. (Ẹ́kísódù 4:10, 11; 33:11) Mósè kò rí Ọlọrun sójú, ‘ipasẹ̀ àwọn áńgẹ́lì’ ló fi gba àwọn ìsọfúnni tó rí gbà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. (Gálátíà 3:19; Ìṣe 7:53) Síbẹ̀, ìgbàgbọ́ tí Mósè ní nínú lágbára débi pé Bíbélì sọ pé ó ń “rí Ẹni tí a kò lè rí.”Hébérù 11:27.

Bí Ọlọ́run ṣe lo àwọn áńgẹ́lì láti bá Mósè sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe lò ó láti bá Ábúráhámù sọ̀rọ̀. Ó sì lè jẹ́ pé torí bí Ábúráhámù ṣe ń ka Ìwé Mímọ́ ló ṣe dà bí i pé ó rí Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 18:1, 33) Àmọ́, àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣáájú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn fi hàn áńgẹ́lì tí Jèhófà rán ni “àwọn ọkùnrin mẹ́ta” tí wọ́n wá sọ́dọ̀ Ábúráhámù. Aṣojú Ọlọ́run ni Ábúráhámù ka àwọn áńgẹ́lì yẹn sí ó sì ń bá wọn sọ̀rọ̀ bí pé Jèhófà ló ń bá sọ̀rọ̀ ní tààràtà.Jẹ́nẹ́sísì 18:2, 3, 22, 32; 19:1.

Ìran.

Ọlọ́run tún máa ń fara han àwọn èèyàn nínú ìran tàbí nígbà tí wọ́n bá ń fọkàn yàwòrán. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Bíbélì sọ pé Mósè àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì “rí Ọlọ́run Ísírẹ́lì,” ohun tí wọ́n rí ni “ìran Ọlọ́run tòótọ́.” (Ẹ́kísódù 24:9-11) Bákan náà, láwọn ìgbà míì Bíbélì máa ń sọ pé àwọn wòlíì “rí Jèhófà.” (Aísáyà 6:1; Dáníẹ́lì 7:9; Ámósì 9:1) Láwọn ibi tí Bíbélì ti sọ bẹ́ẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ ṣáájú fi hàn pé ìran ni wọ́n rí kì í ṣe pé wọ́n rí Ọlọ́run lójúkojú.Aísáyà 1:1; Dáníẹ́lì 7:2; Ámósì 1:1.