Ohun tí Bíbélì sọ

Gbogbo èèyàn ló ní orúkọ. Ǹjẹ́ kò bọ́gbọ́n pé kí Ọlọ́run ní orúkọ tiẹ̀? Bí a ṣe ń fi orúkọ àwọn èèyàn pè wọ́n máa ń jẹ́ kí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wa pẹ̀lú wọn dán mọ́rán. Ṣé kì í ṣe bó ṣe yẹ kó rí náà nìyẹn nínú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wa pẹ̀lú Ọlọ́run?

Ọlọ́run sọ nínú Bíbélì pé: “Èmi ni Jèhófà. Èyí ni orúkọ mi.” (Aísáyà 42:8) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ní ọ̀pọ̀ orúkọ oyè, bí “Ọlọ́run Olódùmarè,” “Olúwa Ọba Aláṣẹ,” àti “Ẹlẹ́dàá,” ó dá àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ lọ́lá pé kí wọ́n máa fi orúkọ òun pe òun.—Jẹ́nẹ́sísì 17:1; Ìṣe 4:24; 1 Pétérù 4:19.

Nínú ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì, a rí orúkọ Ọlọ́run ní Ẹ́kísódù 6:3. Ẹsẹ yẹn sọ pé: “Èmi sì ti máa ń fara han Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù ní Ọlọ́run Olódùmarè, ṣùgbọ́n ní ti orúkọ mi Jèhófà èmi kò sọ ara mi di mímọ̀ fún wọn.

Láti ọ̀pọ̀ ọdún wá ni a ti ń pé orúkọ Ọlọ́run ní Jèhófà lédè Yorùbá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé “Yáwè” ni ọ̀pọ̀ ọ̀mọ̀wé máa ń kọ sílẹ̀, àmọ́ Jèhófà ni orúkọ táwọn èèyàn mọ̀ jù lọ. Kì í ṣe èdè Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n fi kọ apá àkọ́kọ́ nínú Bíbélì, èdè Hébérù ni wọ́n fi kọ ọ́, wọ́n máa ń ka èdè yìí láti apá ọ̀tún sí apá òsì. Ní èdè Hébérù, wọ́n máa ń fi kọ́ńsónáǹtì mẹ́rin yìí, יהוה kọ orúkọ Ọlọ́run. Àwọn lẹ́tà tí wọ́n máa fi ń dípò àwọn kọ́ńsónáǹtì Hébérù mẹ́rin náà ni YHWH, tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run.