Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ìgbà Wo Ni Òpin Ayé Máa Dé?

Ìgbà Wo Ni Òpin Ayé Máa Dé?

Ohun tí Bíbélì sọ

Láti mọ ìgbà tí òpin ayé máa dé, ó yẹ ká mọ ohun tí ọ̀rọ̀ náà “ayé” tó wà nínú Bíbélì máa ń túmọ̀ sí. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, koʹsmos, tó túmọ̀ sí “ayé,” sábà máa ń tọ́ka sí aráyé, pàápàá àwọn tó kẹ̀yìn sí Ọlọ́run, tí wọn ò sì ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (Jòhánù 15:18, 19; 2 Pétérù 2:5) Nígbà míì, koʹsmos máa ń tọ́ka sí ètò ìgbésí ayé ẹ̀dá èèyàn.1 Kọ́ríńtì 7:31; 1 Jòhánù 2:15, 16. *

Kí ni “òpin ayé”?

Ọ̀pọ̀ ìtúmọ̀ Bíbélì lo ọ̀rọ̀ náà, “òpin ayé,” a sì tún lè pè é ní “ìparí ètò àwọn nǹkan” tàbí “ìparí igbeaye yìí.” (Mátíù 24:3; Bibeli Yoruba Atọ́ka) Kì í ṣe ìparun ayé tàbí gbogbo aráyé ló ń tọ́ka sí, òpin ètò ìgbésí ayé ẹ̀dá èèyàn ló ń tọ́ka sí.1 Jòhánù 2:17.

Bíbélì fi kọ́ni pé “àwọn aṣebi ni a óò ké kúrò” kí àwọn èèyàn rere lè máa gbádùn lórí ilẹ̀ ayé. (Sáàmù 37:9-11) Ìparun yìí máa wáyé nígbà “ìpọ́njú ńlá,” èyí tó máa yọrí sí ogun Amágẹ́dọ́nì.Mátíù 24:21, 22; Ìṣípayá 16:14, 16.

Ìgbà wo ni òpin ayé máa dé?

Jésù sọ pé: “Ní ti ọjọ́ àti wákàtí yẹn, kò sí ẹnì kankan tí ó mọ̀ ọ́n, àwọn áńgẹ́lì ọ̀run tàbí Ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe Baba nìkan.” (Mátíù 24:36, 42) Ó tún sọ pé òjijì ni òpin máa dé, “ní wákàtí tí ẹ kò ronú pé yóò jẹ́.”Mátíù 24:44.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò lè mọ ọjọ́ àti wákàtí náà gan-an, Jésù jẹ́ ká mọ “àmì” tàbí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀, tó máa jẹ́ ká mọ àwọn ohun tó máa wáyé kí òpin ayé tó dé. (Mátíù 24:3, 7-14) Bíbélì pé àkókò tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà máa wáyé ní “àkókò òpin,” “ìgbà ìkẹyìn,” àti “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.”Dáníẹ́lì 12:4; Bíbélì Mímọ́; 2 Tímótì 3:1-5.

Ṣé ohunkóhun máa ṣẹ́ kù lẹ́yìn tí òpin ayé bá dé?

Bẹ́ẹ̀ ni. Ayé tá à ń gbé yìí ò ní pa run, torí Bíbélì sọ pé “kò lè ṣípò padà láéláé.” (Sáàmù 104:5, Bíbélì Mímọ́) Àwọn èèyàn á sì kún ayé, bí ìlérí tó wà nínú Bíbélì, tó ní: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” (Sáàmù 37:29) Ọlọ́run máa wá ṣe àwọn ohun tó ti ní lọ́kàn láti ṣe:

^ ìpínrọ̀ 3 Àwọn Bíbélì kan tún túmọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, ai·onʹ sí “ayé”. Tí wọ́n bá túmọ̀ rẹ̀ lọ́nà yìí, ìtumọ̀ ai·onʹ àti koʹsmos máa ń jọra, òun náà máa ń tọ́ka sí ètò ìgbésí ayé ẹ̀dá èèyàn.