Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ṣé Ó Burú Kí Kristẹni Lo Oògùn Tí Kì Í Jẹ́ Kéèyàn Lóyún?

Ṣé Ó Burú Kí Kristẹni Lo Oògùn Tí Kì Í Jẹ́ Kéèyàn Lóyún?

Ohun tí Bíbélì sọ

Jésù kò pàṣẹ pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun bímọ tàbí kí wọ́n má ṣe bímọ. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ náà kò sì sọ ohun tó jọ bẹ́ẹ̀. Kò sí ibì kankan tí Bíbélì ti sọ pé èèyàn kò gbọ́dọ̀ fètò sọ́mọ bíbí. Ìlànà tó wà nínú Róòmù 14:12 ló yẹ ká tẹ̀ lé lórí ọ̀rọ̀ yìí, ó sọ pé: “Olúkúlùkù wa ni yóò ṣe ìjíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.

Nítorí náà, tọkọtaya ló máa pinnu bóyá àwọn fẹ́ bímọ tàbí wọn kò fẹ́. Wọ́n tún lè pinnu iye ọmọ tí wọ́n fẹ́ bí àti ìgbà tí wọ́n fẹ́ bí wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé tọkọtaya kan kò gbọ́dọ̀ lo oògùn tó ń ṣẹ́yún, síbẹ̀ wọ́n lè yàn bí wọ́n bá fẹ́ láti lo oògùn tí kì í jẹ́ kéèyàn lóyún. Ẹnì kankan kò gbọ́dọ̀ dá wọn lẹ́bi lórí èyí.—Róòmù 14:4, 10-13.