Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ǹjẹ́ Èṣù Wà?

Ǹjẹ́ Èṣù Wà?

Ohun tí Bíbélì sọ

Bẹ́ẹ̀ ni, Èṣù wà. Òun ni “olùṣàkóso ayé,” ẹ̀dá ẹ̀mí tó sọ ara rẹ̀ di ẹni burúkú, tó sì ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run ni. (Jòhánù 14:30; Éfésù 6:11, 12) Bíbélì sọ irú ẹni tí Èṣù jẹ́, díẹ̀ lára àwọn orúkọ tó pè é àti àlàyé tó ṣe nípa rẹ̀ nìyí:

Èrò ibi tó wà nínú èèyàn tàbí ìwà ibi téèyàn hù kọ́ ni Èṣù

Àwọn kan rò pé èrò ibi tó wà nínú èèyàn tàbí ìwà ibi téèyàn hù ni Èṣù. Àmọ́, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan tó wáyé láàárín Ọlọ́run àti Èṣù. Ẹni pípé ni Ọlọ́run, kò lè jẹ́ èrò ibi tí àwọn kan rò pé ó wà nínú rẹ̀ ló ń bá sọ̀rọ̀. (Diutarónómì 32:4; Jóòbù 2:1-6) Bákan náà, Sátánì dán Jésù tí kò ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan wò. (Mátíù 4:8-10; 1 Jòhánù 3:5) Torí náà, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Èṣù wà àti pé Èṣù kì í ṣe ìwà ibi tí ẹnì kan hù.

Ǹjẹ́ ó yẹ kó yà wá lẹ́nu pé àwọn èèyàn kan ò gbà gbọ́ pé Èṣù wà? Rárá o, torí Bíbélì sọ pé Sátánì máa ń lo ẹ̀tàn láti ṣe iṣẹ́ ibi rẹ̀. (2 Tẹsalóníkà 2:9, 10) Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí Sátánì gbà ń tan àwọn èèyàn ni bó ṣe sọ ọ̀pọ̀ èèyàn di afọ́jú nínú ọkàn kí wọ́n má bàa gbà gbọ́ pé ó wà.—2 Kọ́ríńtì 4:4, Bíbélì Mímọ́.

Àwọn nǹkan míì tí kì í ṣe òtítọ́ nípa Èṣù

Irọ́: Lúsíférì ni orúkọ míì tí Èṣù ń jẹ́.

Òtítọ́: Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n tú sí “Lúsíférì” nínú àwọn Bíbélì kan túmọ̀ sí “ẹni tí ń tàn.” (Aísáyà 14:12) Àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣáájú àti èyí tó wà lẹ́yìn ẹsẹ yẹn fi hàn pé àwọn tó ń ṣàkóso tàbí ìlà ìdílé tó ń jọba ní ilẹ̀ Bábílónì ni ọ̀rọ̀ náà ń tọ́ka sí, Ọlọ́run sì máa rẹ àwọn ọba agbéraga yìí nípò wálẹ̀. (Aísáyà 14:4, 13-20) Ńṣe ni wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ náà, “ẹni tí ń tàn” pẹ̀gàn àwọn ìdílé tó ń jọba ní ilẹ̀ Bábílónì lẹ́yìn tí wọ́n gbàjọba lọ́wọ́ wọn.

Irọ́: Sátánì ni Ọlọ́run ń lò láti máa dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́.

Òtítọ́: Ọ̀tá Ọlọ́run ni Èṣù, kì í ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀. Sátánì Èṣù máa ń ta ko àwọn tó ń sin Ọlọ́run, ó sì máa ń fi ẹ̀sùn èké kàn wọ́n.1 Pétérù 5:8; Ìṣípayá 12:10.