Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Kí Ni Ọ̀run Àpáàdì? Ṣé Ibi Ìdálóró Ayérayé Ni Ọ̀run Àpáàdì?

Kí Ni Ọ̀run Àpáàdì? Ṣé Ibi Ìdálóró Ayérayé Ni Ọ̀run Àpáàdì?

Ohun tí Bíbélì sọ

Àwọn Bíbélì kan tú ọ̀rọ̀ Hébérù náà, “Ṣìọ́ọ̀lù” àti ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó bá a dọ́gba, ìyẹn “Hédíìsì” sí “ọ̀run àpáàdì” nígbà tó sì jẹ́ pé ipò òkú ni ọ̀rọ̀ méjèèjì yìí dúró fún. (Sáàmù 16:10; Ìṣe 2:27) Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà gbọ́ pé iná ọ̀run àpáàdì wà, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú àwòrán àwọn onísìn tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí. Àmọ́, ohun tí Bíbélì fi kọ́ni yàtọ̀ sí ìyẹn.

  1. Àwọn tó wà ní ọ̀run àpáàdì kò mọ nǹkan kan bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò mọ ìrora. “Kò sí iṣẹ́ tàbí ìhùmọ̀ tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n ní Ṣìọ́ọ̀lù.”Oníwàásù 9:10.

  2. Àwọn èèyàn rere máa ń lọ sí ọ̀run àpáàdì. Àwọn ọkùnrin tó jẹ́ olóòótọ́ bíi Jékọ́bù àti Jóòbù fẹ́ láti lọ sí ọ̀run àpáàdì.Jẹ́nẹ́sísì 37:35; Jóòbù 14:13.

  3. Ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀ kì í ṣe ìdálóró nínú iná ọ̀run àpáàdì. “Ẹni tí ó bá ti kú ni a ti dá sílẹ̀ pátápátá kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.”Róòmù 6:7.

  4. Ìdálóró ayérayé máa fi hàn pé Ọlọ́run kì í ṣe onídàájọ́ òdodo. (Diutarónómì 32:4) Nígbà ti Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́ dẹ́ṣẹ̀, Ọlọ́run sọ pé ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ni pé yóò kú, Ọlọ́run ní: ‘erùpẹ̀ ni ìwọ, ìwọ ó sì padà di erùpẹ̀.’ (Jẹ́nẹ́sísì 3:19, Bíbélì Mímọ́) Tó bá jẹ́ pé inú iná ọ̀run àpáàdì ni Ọlọ́run ju Ádámù sí, a jẹ́ pé irọ́ ni Ọlọ́run pa.

  5. Ọlọ́run gan-an kò ronú láti dá ẹnì kankan lóró nínú iná ọ̀run àpáàdì. Èrò pé Ọlọ́run máa fìyà jẹ àwọn èèyàn nínú iná ọ̀run àpáàdì ta ko ohun tí Bíbélì fi kọ́ni pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.”1 Jòhánù 4:8; Jeremáyà7:31.