Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Kí Ni Ìrìbọmi?

Kí Ni Ìrìbọmi?

Ohun tí Bíbélì sọ

Tí wọ́n bá ri ẹnì kan bọnú omi, tí wọ́n sì gbé e jáde látinú rẹ̀, ẹni náà ti ṣe ìrìbọmi. * Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé inú odò ńlá ni Jésù ti ṣe ìrìbọmi. (Mátíù 3:13, 16) Bákan náà, ọkùnrin ará Etiópíà kan sọ pé òun fẹ́ ṣe ìrìbọmi nígbà tí wọ́n dé ibi “ìwọ́jọpọ̀ omi.”Ìṣe 8:36-40.

Ohun tí ìrìbọmi túmọ̀ sí

Bíbélì fi ẹni tó ṣe ìrìbọmi wé ẹni tí wọ́n sin. (Róòmù 6:4; Kólósè 2:12) Téèyàn bá ṣèrìbọmi, ohun tó ṣàpẹẹrẹ ni pé ẹni náà ti di òkú nínú ìgbésí ayé tó ń gbé tẹ́lẹ̀, ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbésí ayé tuntun torí ó ti di Kristẹni tó ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run. Ìrìbọmi àtàwọn ohun téèyàn máa ṣe ṣáájú ìrìbọmi ni ètò tí Ọlọ́run ṣe kí ẹnì kan lè ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ torí pé ó nígbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi. (1 Pétérù 3:21) Ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun gbọ́dọ̀ ṣèrìbọmi.Mátíù 28:19, 20.

Ṣé ìrìbọmi máa ń wẹ ẹ̀ṣẹ̀ kúrò?

Rárá. Ohun tí Bíbélì fi kọ́ni ni pé ẹ̀jẹ̀ Jésù tó fi rúbọ nìkan ló lè wẹ̀ wá mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀. (Róòmù 5:8, 9; 1 Jòhánù 1:7) Àmọ́ kí ẹbọ ìràpadà Jésù tó lè ṣe ẹnì kan láǹfààní, ó gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ nígbàgbọ́ nínú Jésù, kó yí ìwà rẹ̀ pa dà kó lè máa ṣe àwọn ohun tó bá ohun tí Jésù fi kọ́ni mu, kó sì ṣe ìrìbọmi.Ìṣe 2:38; 3:19.

Kí ni ìsàmì fún ọmọdé?

Kò sí “ìsàmì fún ọmọdé” nínú Bíbélì. Àwọn ṣọ́ọ̀ṣì kan ló máa ń ṣe ayẹyẹ náà. Wọ́n á wọ́n omi sí ọmọdé kan lórí tàbí kí wọ́n da omi sí i lórí, wọ́n á sì sọ pé ó ti “ṣèrìbọmi,” wọ́n á wá sọ ọmọ náà lórúkọ.

Ṣé Bíbélì fi kọ́ni pé àwọn ọmọdé lè ṣèrìbọmi?

Rárá o. Àwọn tó ti dàgbà tó láti lóye “ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run” kí wọ́n sì gbà á gbọ́ ló lè ṣèrìbọmi, kí wọ́n sì di Kristẹni. (Ìṣe 8:12) Ìrìbọmi ní ín ṣe pẹ̀lú kéèyàn gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kó gbà á gbọ́, kó sì ronú pìwà dà. Ọmọdé ò lè ṣe àwọn nǹkan yìí.Ìṣe 2:22, 38, 41.

Bákan náà, Bíbélì fi hàn pé Ọlọ́run máa ń fojú ẹni tó mọ́ wo àwọn ọmọdé tí òbí wọn jẹ́ Kristẹni, torí pé olóòótọ́ ni àwọn òbí wọn. (1 Kọ́ríńtì 7:14) Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ló yẹ káwọn ọmọdé ṣèrìbọmi, Ọlọ́run ò ní máa wo tàwọn òbí wọn mọ́ wọn lára. *

Èrò tí kò tọ́ táwọn èèyàn ní nípa ìrìbọmi àwọn Kristẹni

Èrò tí kò tọ́: Kò sóhun tó burú nínú kí wọ́n wọ́n omi sí ẹnì kan lára tàbí kí wọ́n dà á síni lára dípò kí wọ́n rì í bọnú omi.

Òótọ́: Gbogbo àwọn tí Bíbélì mẹ́nu kàn pé wọ́n ṣèrìbọmi ni wọ́n rì bọnú omi. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ọmọlẹ́yìn náà Fílípì fẹ́ ṣèrìbọmi fún ọkùnrin ará Etiópíà náà, wọ́n “sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú omi náà” kó lè rì í bọmi. Lẹ́yìn náà, “wọ́n jáde kúrò nínú omi.”Ìṣe 8:36-39. *

Èrò tí kò tọ́: Tí Bíbélì bá ń sọ pé gbogbo àwọn tó wà nínú agboolé kan ṣèrìbọmi, ohun tó túmọ̀ sí ni pé àwọn ọmọdé ibẹ̀ náà ṣèrìbọmi. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ nípa olùṣọ́ ẹ̀wọ̀n kan ní Fílípì pé: ‘Gbogbo wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, òun àti àwọn tirẹ̀ ni a batisí láìjáfara.’Ìṣe 16:31-34.

Òótọ́: Ìtàn olùṣọ́ ẹ̀wọ̀n tó di Kristẹni yẹn fi hàn pé “ọ̀rọ̀ Jèhófà” yé àwọn tó ṣèrìbọmi, wọ́n sì “yọ̀ gidigidi.” (Ìṣe 16:32, 34) Ohun tí ìyẹn jẹ́ ká parí èrò sí ni pé ìkankan nínú àwọn ọmọdé tó wà nínú agboolé ọkùnrin náà kò ṣèrìbọmi, torí ọ̀rọ̀ Jèhófà ò lè yé wọn.

Èrò tí kò tọ́: Jésù fi kọ́ni pé ó yẹ káwọn ọmọdé máa ṣèrìbọmi torí ó sọ pé ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ti àwọn ọmọ kékeré.Mátíù 19:13-15; Máàkù 10:13-16.

Òótọ́: Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ yẹn, ọ̀rọ̀ ìrìbọmi kọ́ ló ń sọ. Ohun tó ń sọ ni pé àwọn tó bá máa wọ Ìjọba Ọlọ́run gbọ́dọ̀ dà bí ọmọdé, ìyẹn ni pé kí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, kí wọ́n sì jẹ́ ẹni tó máa ń gba ẹ̀kọ́.Mátíù 18:4; Lúùkù 18:16, 17.

^ ìpínrọ̀ 3 Ọ̀rọ̀ tó túmọ̀ sí “rì bọ̀” ni wọ́n ti mú ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n túmọ̀ sí “ìrìbọmi.” Wo ìwé Theological Dictionary of the New Testament, Ìdìpọ̀ I, ojú ìwé 529.

^ ìpínrọ̀ 12 Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The International Standard Bible Encyclopedia sọ pé “kò sí ọ̀rọ̀ nípa ìrìbọmi ọmọ kékeré nínú Májẹ̀mú Tuntun.” Ó tún sọ pé ohun tó bí àṣà yẹn ni pé “àwọn èèyàn ṣi ọ̀rọ̀ ìrìbọmi lóye, wọ́n sì bù mọ́ ọn,” ní ti pé wọ́n ní ìrìbọmi gangan ló máa ń wẹ ẹ̀ṣẹ̀ kúrò.—Ìdìpọ̀ 1, ojú ìwé 416-417.

^ ìpínrọ̀ 15 Ìsọ̀rí náà, “Ìrìbọmi (nínú Bíbélì)” nínú ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia sọ pé: “Ó ṣe kedere pé nínú Ìjọ láyé àtijọ́, ṣe ni wọ́n máa ń ri àwọn tó bá fẹ́ ṣe ìbatisí bọmi.”—Ìdìpọ̀ 2, ojú ìwé 59.