Ohun tí Bíbélì sọ

Ìrékọjá làwọn Júù fi máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún bó ṣe gbà wọ́n sílẹ̀ lóko ẹrú àwọn ará Íjíbítì ní 1513  ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ọlọ́run pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n máa rántí ọjọ́ pàtàkì yìí lọ́dọọdún ní ọjọ́ kẹrìnlá [14] oṣù Ábíbù tàwọn Júù, tí wọ́n ń pè ní Nísàn nígbà tó yá.​—Ẹ́kísódù 12:42; Léfítíkù 23:5.

Kí nìdí tí wọ́n fi ń pè é ní Ìrékọjá?

Ọ̀rọ̀ náà “Ìrékọjá” tọ́ka sí bí Ọlọ́run ṣe ré àjálù kọjá lórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí gbogbo àkọ́bí wọn ní Íjíbítì kú. (Ẹ́kísódù 12:27; 13:15) Kí Ọlọ́run tó mú àjálù burúkú yìí wá, ó sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n fọ́n ẹ̀jẹ̀ àgùntàn tàbí ewúrẹ́ sára òpó ilẹ̀kùn ilé wọn. (Ẹ́kísódù 12:21, 22) Tí Ọlọ́run bá ti rí àmí yìí, ńṣe láá ré ilé wọn kọjá, tí kò sì ní ṣe ìpalára kankan fún àwọn àkọ́bí wọn.​—Ẹ́kísódù 12:​7, 13.

Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣe Ìrékọjá nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì?

Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ìtọ́ni nípa bí wọ́n ṣe máa ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá àkọ́kọ́. * Díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí wọ́n máa ń ṣe nígbà àjọyọ̀ Ìrékọjá ni.

  • Ìrúbọ: Ìdílé kọ̀ọ̀kan máa mú ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan (tàbí ewúrẹ́) jáde ní ọjọ́ kẹwàá ti oṣù Ábíbù (Nísàn), tó bá sì di ọjọ́ kẹrìnlá, wọ́n máa pa á. Nígbà àkọ́kọ́ tí wọ́n máa ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá, àwọn Júù wọ́n ẹ̀jẹ̀ ẹran náà sí òpó ilẹ̀kùn ilé wọn àti apá òkè ẹnu ilẹ̀kùn wọn, wọ́n yan odindi ẹran náà, wọ́n sì jẹ ẹ́.​—Ẹ́kísódù 12:​3-9.

  • Oúnjẹ: Yàtọ̀ sí àgùntàn (tàbí ewúrẹ́) táwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń jẹ nígbà àjọyọ̀ Ìrékọjá, wọ́n tún máa ń jẹ àkàrà aláìwú àti ewébẹ̀ kíkorò lásìkò yẹn.​—Ẹ́kísódù 12:8.

  • Àjọyọ̀: Lẹ́yìn àjọyọ̀ Ìrékọjá, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ṣe àjọyọ̀ àkàrà aláìwú fún ọjọ́ méje, ní gbogbo àsìkò yìí, wọn kò ní jẹ ohunkóhun tó ní ìwúkàrà.​—Ẹ́kísódù 12:17-​20; 2 Kíróníkà 30:21.

  • Ẹ̀kọ́: Àwọn òbí máa ń fi àjọyọ̀ Ìrékọjá kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run.​—Ẹ́kísódù 12:25-27.

  • Ìrìn àjò: Nígbà tó yá, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í rìrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù láti ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá.​—Diutarónómì 16:​5-7; Lúùkù 2:​41.

  • Àwọn àṣà míì: Nígbà ayé Jésù, wọ́n máa ń mu wáìnì, wọ́n sì máa ń kọrin tí wọ́n bá ń ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá.​—Mátíù 26:19, 30; Lúùkù 22:15-​18.

Àwọn àṣìlóye nípa Ìrékọjá

Àṣìlóye: Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ oúnjẹ àjọyọ̀ Ìrékọjá ní Nísàn 15.

Òótọ́: Ọlọ́run pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n pa ewúré kan nígbà tí oòrùn bá wọ̀ ní Nísàn 14, kí wọ́n sì jẹ ẹ́ ní alẹ́ ọjọ́ yẹn gan-an. (Ẹ́kísódù 12:​6, 8) Ìrọ̀lẹ́ sí ìrọ̀lẹ́ làwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi máa ń ka ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. (Léfítíkù 23:32) Torí náà, wọ́n pa ewúré wọ́n sì jẹ oúnjẹ Ìrẹ́kọjá ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ Nísàn 14.

Àṣìlóye: Ó yẹ kí gbogbo Kristẹni máa ṣe àyọjọ̀ Ìrékojá.

Òótọ́: Lẹ́yìn tí Jésù ṣe àyọjọ̀ Ìrékojá ní Nísàn 14, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, ó ní ká máa ṣe nǹkan míì, ìyẹn Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa. (Lúùkù 22:19, 20; 1 Kọ́ríńtì 11:20) Òun ló rọ́pò àjọyọ̀ Ìrékọjá, torí ńṣe la fi ń rántí bí a ṣe fi “Kristi ìrékọjá [náà] rúbọ.” (1 Kọ́ríńtì 5:7) Ẹbọ ìràpadà Jésù tóbi ju àjọyọ̀ Ìrékọjá lọ ní ti pé òun ló gba gbogbo aráyé lóko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.​—Mátíù 20:28; Hébérù 9:​15.

^ ìpínrọ̀ 7 Àmọ́ nígbà tó yá, ó gba pé kí wọ́n yí àwọn nǹkan kan pa dà. Bí àpẹẹrẹ, ìkánjú làwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá nígbà àkọ́kọ́ torí wọ́n ní láti kúrò ní Íjíbítì. (Ẹ́kísódù 12:11) Àmọ́ látìgbà tí wọ́n ti dé Ìlẹ̀ Ìlérí, kò sídìí fún wọn láti fi ìkánjú ṣe é mọ́.