Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Kí Ni Ìdáríjì?

Kí Ni Ìdáríjì?

Ohun tí Bíbélì sọ

Ohun tó túmọ̀ sí láti dárí jini ni pé kéèyàn pa ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹnì kan ṣẹ̀ ẹ́ rẹ́. Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n lò fún “ìdáríjì” túmọ̀ sí kéèyàn “jẹ́ kí nǹkan lọ,” bí ìgbà téèyàn ò béèrè owó tí ẹnì kan jẹ ẹ́. Jésù lo ọ̀rọ̀ tó jọ èyí nígbà tó ń kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà, ó ní: “Dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, nítorí àwa fúnra wa pẹ̀lú a máa dárí ji olúkúlùkù ẹni tí ó jẹ wá ní gbèsè.” (Lúùkù 11:4) Bákan náà, nínú àkàwé ẹrú tí kò láàánú tí Jésù ṣe, ó fi ìdáríjì wé gbèsè tí ẹnì kan fagi lé.Mátíù 18:23-35.

Tí a ò bá di àwọn tó ṣẹ̀ wá sínú, tí a ò sì retí pé kí wọ́n ṣe ohunkóhun fún wa tàbí san ohunkóhun pa dà torí ohun tí wọ́n ṣe sí wa, ó túmọ̀ sí pé a ti dárí jì wọ́n nìyẹn. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìdáríjì tòótọ́ dá lórí ìfẹ́ àtọkànwá, ó ṣe tán, ìfẹ́ kì í “kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe.”1 Kọ́ríńtì 13:4, 5.

Ohun tí ìdáríjì kò túmọ̀ sí

 • Kéèyàn gbà pé ẹ̀ṣẹ̀ náà ò burú. Bíbélì dẹ́bi fún àwọn tó ń sọ pé ìwà búburú ò lè pani lára tàbí tí wọ́n rò pé kò sóhun tó burú níbẹ̀.Aísáyà 5:20.

 • Kéèyàn máa ṣe bíi pé kò sóhun tó ṣẹlẹ̀. Ọlọ́run dárí ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tí Dáfídì ọba ṣẹ̀ jì í, àmọ́ kò dáàbò bo Dáfídì kó má bàa jìyà ohun tó ṣe. Ńṣe ni Ọlọ́run tiẹ̀ jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ Dáfídì wà lákọọ́lẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ká lè máa rántí rẹ̀ lónìí.2 Sámúẹ́lì 2:9-13.

 • Kéèyàn kàn jẹ́ kí àwọn míì yan òun jẹ. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé o yá ẹnì kan lówó, àmọ́ tí ẹni náà ṣe owó tó yá ṣúkaṣùka, tí kò wá lè san owó náà mọ́ bó ṣe sọ. Ohun tó ṣe yìí dùn ún gan-an, ó sì bẹ̀ ọ́ pé kó o máà bínú. O lè dárí jì í, kó o má dì í sínú, kó o má sì fa ọ̀rọ̀ náà mọ́, o tiẹ̀ tún lè fagi lé gbèsè náà pàápàá. Síbẹ̀, o ṣì lè pinnu pé o ò tún ní yá ẹni náà lówó mọ́.— Sáàmù 37:21; Òwe 14:15; 22:3; Gálátíà 6:7.

 • Kéèyàn gbójú fo ẹ̀ṣẹ̀ láìsí ìdí pàtàkì kan. Ọlọ́run kì í dárí ji àwọn tó mọ̀ọ́mọ̀ dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú, tí wọn ò sì gba ẹ̀bi wọn lẹ́bi, tí wọn ò yí ìwà wọn pa dà, tí wọn ò sì tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n ṣẹ̀. (Òwe 28:13; Ìṣe 26:20; Hébérù 10:26) Irú àwọn tí kò ronú pìwà dà bẹ́ẹ̀ máa ń di ọ̀tá Ọlọ́run, kò sì sọ pé ká dárí ji àwọn tí òun fúnra rẹ̀ ò dárí jì.Sáàmù 139:21, 22.

  Ká ní ẹnì kan hùwà àìdáa sí ẹ, tí kò sì tọrọ àforíjì tàbí tí ò tiẹ̀ gbà pé òun jẹ̀bi ńkọ́? Bíbélì sọ pé: “Jáwọ́ nínú ìbínú, kí o sì fi ìhónú sílẹ̀.” (Sáàmù 37:8) O lè pinnu pé o ò ní gbaná jẹ torí ìbínú, bó o bá tiẹ̀ gbà pé ẹni náà ṣẹ̀ ẹ́. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Ọlọ́run máa ṣèdájọ́ ẹni náà. (Hébérù 10:30, 31) Ó lè tù ẹ́ nínú láti mọ̀ pé ìgbà kán ń bọ̀ tí Ọlọ́run máa fòpin sí ìrora tàbí ẹ̀dùn ọkàn tá a máa ń ní báyìí tó lè dà bí ẹrù ìnira.Aísáyà 65:17; Ìṣípayá 21:4.

 • “Máa dárí jini” lórí gbogbo ọ̀rọ̀ tí kò tó nǹkan. Ìgbà míì wà tó jẹ́ pé dípò tá a fi máa dárí ji ẹnì kan tá a rò pé ó ṣẹ̀ wá, a lè gbà pé kò sí ìdí pàtàkì tó fi yẹ ká tiẹ̀ bínú tẹ́lẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Má ṣe kánjú nínú ẹ̀mí rẹ láti fara ya, nítorí pé fífara ya sinmi ní oókan àyà àwọn arìndìn.”Oníwàásù 7:9.

Bó o ṣe lè dárí jini

 1. Rántí ohun tó túmọ̀ sí láti dárí jini. Kì í ṣe pé o gbà pé ohun tẹ́ni náà ṣe kò burú tàbí pé ò ń ṣe bíi pé nǹkan ọ̀hún ò tiẹ̀ wáyé rárá, ńṣe ló kàn fẹ́ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà tán lọ́kàn ẹ.

 2. Mọ àwọn àǹfààní tí wàá rí tó o bá ń dárí jini. Tó ò bá gbé ìbínú sọ́kàn, tó ò sì di ẹni tó ṣẹ̀ ẹ́ sínú, èyí á jẹ́ kí ọkàn ẹ máa balẹ̀, ìlera rẹ á jí pépé, wàá sì máa láyọ̀. (Òwe 14:30; Mátíù 5:9) Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé, tá a bá ń dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá, Ọlọ́run á dárí ẹ̀ṣẹ̀ tiwa náà jì wá.Mátíù 6:14, 15.

 3. Máa fọ̀rọ̀ ro ara rẹ wò. Aláìpé ni gbogbo wa. (Jákọ́bù 3:2) Bó ṣe máa wù wá pé kẹ́ni tá a ṣẹ̀ dárí jì wá náà ló ṣe yẹ ká máa dárí ji àwọn tó bá ṣẹ̀ wá.Mátíù 7:12.

 4. Wò ó bóyá o lè gbójú fo ohun tó ṣẹlẹ̀. Tí nǹkan kan bá ṣẹlẹ̀ tó lè bí wa nínú, a lè tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí, ó ní: “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.”Kólósè 3:13.

 5. Tètè gbé ìgbésẹ̀. Wá bó o ṣe máa dárí ji ẹni tó ṣẹ̀ ọ́ kó tó di pé ó pẹ́ jù, má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà gbòdì lára ẹ débi pé ìbínú á mú kó o gbaná jẹ.Éfésù 4:26, 27.