Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Àwòrán Oníhòòhò? Ǹjẹ́ Ó Burú Láti Fi Ohun Tó Ń Mú Ọkàn Fà Sí Ìṣekúṣe Ránṣẹ́ Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì?

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Àwòrán Oníhòòhò? Ǹjẹ́ Ó Burú Láti Fi Ohun Tó Ń Mú Ọkàn Fà Sí Ìṣekúṣe Ránṣẹ́ Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì?

Ohun tí Bíbélì sọ

Kò síbì tí Bíbélì ti dìídì sọ̀rọ̀ nípa àwòrán oníhòòhò, fífi ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe ránṣẹ́ lórí íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí àwọn àṣà míì tó jọ ọ́. Síbẹ̀, ohun tí Bíbélì sọ ṣe kedere nípa ojú tí Ọlọ́run fi ń wo bí àwọn èèyàn ṣe ń gbé ìbálòpọ̀ láàárín àwọn tí kì í ṣe tọkọtaya lárugẹ àti èrò tí kò tọ́ tí wọ́n ní nípa ìbálòpọ̀. Gbé àwọn ẹsẹ Bíbélì wọ̀nyí yẹ̀wò:

  • “Ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé di òkú ní ti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo.” (Kólósè 3:5) Wíwo àwòrán oníhòòhò ń mú kí ìfẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ túbọ̀ lágbára lọ́kàn èèyàn, dípò kó sọ àwọn èrò tí kò tọ́ di òkú. Ó sì máa ń sọ èèyàn di aláìmọ́ tàbí ẹlẹ́gbin lójú Ọlọ́run.

  • “Olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i, ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀.” (Mátíù 5:28) Wíwo àwọn àwòrán ìṣekúṣe lè mú kéèyàn máa ro èròkerò tó lè sún un ṣe àwọn ohun tí kò tọ́.

  • “Kí a má tilẹ̀ mẹ́nu kan àgbèrè àti ìwà àìmọ́ onírúurú gbogbo tàbí ìwà ìwọra láàárín yín.” (Éfésù 5:3) Kò tiẹ̀ yẹ ká máa fi ọ̀rọ̀ ìṣekúṣe ṣàwàdà, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti pé ká wò ó tàbí kà nípa rẹ̀.

  • “Àwọn iṣẹ́ ti ara fara hàn kedere, àwọn sì ni àgbèrè, ìwà àìmọ́, . . . àti nǹkan báwọ̀nyí. Ní ti nǹkan wọ̀nyí ni èmi ń kìlọ̀ ṣáájú fún yín, lọ́nà kan náà gẹ́gẹ́ bí mo ti kìlọ̀ ṣáájú fún yín, pé àwọn tí ń fi irúfẹ́ nǹkan báwọ̀nyí ṣe ìwà hù kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.” (Gálátíà 5:19-21) Lójú Ọlọ́run, ìwà àìmọ́ ni àwọn tó bá ń wo àwòrán oníhòòhò, tó ń sọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ lórí fóònù tàbí tó ń fi ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe ránṣẹ́ lórí fóònù tàbí íńtánẹ́ẹ̀tì ń hù. Tí a bá sọ àwọn ìwà yìí dàṣà, a kò ní rí ojúure Ọlọ́run mọ́.