Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Kí Nìdí Tá A Fi Pe Jésù Ní Ọmọ Ọlọ́run?

Kí Nìdí Tá A Fi Pe Jésù Ní Ọmọ Ọlọ́run?

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ọlọ́rùn kò ní aya, kò sì bímọ. Òun ló dá ohun gbogbo. (Ìṣípayá 4:11) Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pe Ádámù, èèyàn tí Ọlọ́run kọ́kọ́ dá, ní “ọmọ Ọlọ́run.” (Lúùkù 3:38, Bíbélì Mímọ́) Bákan náà, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ló dá Jésù. Nítorí náà, ó pe Jésù pẹ̀lú ní “Ọmọ Ọlọ́run.”—Jòhánù 1:49.

Ọlọ́run dá Jésù kó tó dá Ádámù. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa Jésù pé: “Òun ni àwòrán Ọlọ́run tí a kò lè rí, àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá.” (Kólósè 1:15) Jésù ti wà tipẹ́ kó tó di pé Màríà bí i sí ibùjẹ ẹran ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Kódà Bíbélì sọ pé “orírun rẹ̀ jẹ́ láti àwọn àkókò ìjímìjí, láti àwọn ọjọ́ tí ó jẹ́ àkókò tí ó lọ kánrin.” (Míkà 5:2) Jésù ni àkọ́bí Ọmọ Ọlọ́run, ó jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí ní ọ̀run kó tó wá sáyé. Jésù sọ pé: “Èmi sọ kalẹ̀ wá láti ọ̀run.”—Jòhánù 6:38; 8:23.