Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Orúkọ Àwọn Wo Ni Wọ́n Kọ Sínú “Ìwé Ìyè”?

Orúkọ Àwọn Wo Ni Wọ́n Kọ Sínú “Ìwé Ìyè”?

Ohun tí Bíbélì sọ

Orúkọ àwọn èèyàn tó ń retí ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun ló wà nínú “ìwé ìyè” tí Bíbélì tún pè ní “àkájọ ìwé ìyè” tàbí “ìwé ìrántí.” (Ìṣípayá 3:5; 20:12; Málákì 3:16) Ọlọ́run ló ń pinnu àwọn tí orúkọ wọn á wọ inú ìwé ìyè, ìyẹn àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ àti onígbọràn sí i.Jòhánù 3:16; 1 Jòhánù 5:3.

Ọlọ́run kò gbàgbé ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́, àfi bí ẹni pé ńṣe ló ti ń kọ orúkọ wọn sínú ìwé láti “ìgbà pípilẹ̀ ayé” wá. (Ìṣípayá 17:8) Ó jọ pé orúkọ ọkùnrin olóòótọ́ náà, Ébẹ́lì ló kọ́kọ́ wọ inú ìwé ìyè. (Hébérù 11:4) Kì í ṣe pé Ọlọ́run kàn ṣáà ń kọ orúkọ àwọn èèyàn bó ṣe wù ú, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni bó ṣe ń kọ orúkọ àwọn èèyàn sínú ìwé ìyè náà jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ tó “mọ àwọn tí í ṣe tirẹ̀” ni Jèhófà.2 Tímótì 2:19; 1 Jòhánù 4:8.

Ǹjẹ́ Ọlọ́run lè pa àwọn orúkọ kan rẹ́ nínú “ìwé ìyè”?

Bẹ́ẹ̀ ni. Ọlọ́run sọ nípa àwọn èèyàn aláìgbọràn tó wà ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì pé: “Ẹnì yòówù tí ó ti ṣẹ̀ mí, ni èmi yóò pa rẹ́ kúrò nínú ìwé mi.” (Ẹ́kísódù 32:33) Àmọ́, tí a bá jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run, orúkọ wa á ṣì máa wà nínú “àkájọ ìwé ìyè.”Ìṣípayá 20:12.