Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Mọ Ìsìn Tòótọ́?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Mọ Ìsìn Tòótọ́?

Ohun tí Bíbélì sọ

Nígbà tí Bíbélì ń ṣe àpèjúwe kan nípa bá a ṣe lè dá àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ mọ̀, ó sọ pé: “Nípa àwọn èso wọn ni ẹ ó fi dá wọn mọ̀. Àwọn ènìyàn kì í kó èso àjàrà jọ láti ara ẹ̀gún tàbí ọ̀pọ̀tọ́ láti ara òṣùṣú, wọ́n ha ń ṣe bẹ́ẹ̀ bí?” (Mátíù 7:16) Bí o ṣe lè fi ìyàtọ̀ sáàárín èso àjàrà àti igi ẹ̀gún, bẹ́ẹ̀ náà lo ṣe lè fi ìyàtọ̀ sáàárín ìsìn tòótọ́ àti ìsìn èké tó o bá wo ìwà àti ìṣe àwọn tó ń ṣe ìsìn náà. Díẹ̀ lára àwọn ohun tí a lè fi mọ ìsìn tòótọ́ nìyí.

  1. Ìsìn tòótọ́ máa ń fi òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ni, kì í kọ́ni ní ọgbọ́n orí èèyàn. (Jòhánù 4:24; 17:17) Lára àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ yìí ni òtítọ́ nípa ọkàn àti ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. (Sáàmù 37:29; Aísáyà 35:5, 6; Ìsíkíẹ́lì 18:4) Ìsìn tòótọ́ máa ń tú àṣírí àwọn ẹ̀kọ́ èké tí àwọn onísìn fi ń kọ́ àwọn èèyàn.—Mátíù 15:9; 23:27, 28.

  2. Ìsìn tòótọ́ máa ń kọ́ àwọn èèyàn nípa Ọlọ́run, tó fi mọ́ orúkọ rẹ̀, ìyẹn Jèhófà. (Sáàmù 83:18; Aísáyà 42:8; Jòhánù 17:3, 6) Ìsìn tòótọ́ kì í kọ́ àwọn èèyàn pé Ọlọrun kò ṣeé sún mọ́ tàbí pé ó rorò. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa ń kọni pé Ọlọ́run fẹ́ ká sún mọ́ òun.—Jákọ́bù 4:8.

  3. Ìsìn tòótọ́ máa ń kọ́ni pé nípasẹ̀ Jésù Kristi ni a fi lè rí ìgbàlà. (Ìṣe 4:10, 12) Àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ máa ń pa àṣẹ Jésù mọ́, wọ́n sì máa ń sapá láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀.—Jòhánù 13:15; 15:14.

  4. Ìsìn tòótọ́ gbà pé Ìjọba Ọlọ́run ló máa yanjú àwọn ìṣòro wa. Àwọn tó sì ń ṣe ìsìn tòótọ́ máa ń fìtara wàásù nípa Ìjọba yìí fún àwọn èèyàn.—Mátíù 10:7; 24:14.

  5. Ìfẹ́ tòótọ́ máa ń wà láàárín àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́. (Jòhánù 13:35) Ìsìn tòótọ́ kọ́ni pé ká máa bọ̀wọ̀ fún àwọn èèyàn tó wá láti onírúurú ẹ̀yà, àṣà ìbílẹ̀ àti èdè. (Ìṣe 10:34, 35) Nítorí ìfẹ́ tí wọ́n ní síra wọn, wọn kì í lọ́wọ́ sí ogun jíjà.—Míkà 4:3; 1 Jòhánù 3:11, 12.

  6. Ìsìn tòótọ́ kò ní àwọn olórí ìsìn tí wọ́n ń sanwó fún, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kì í fún ẹnikẹ́ni nínú ìjọ wọn ní àwọn oyè ńlá-ńlá.—Mátíù 23:8-12; 1 Pétérù 5:2, 3.

  7. Ìsìn tòótọ́ kì í lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ òṣèlú rárá. (Jòhánù 17:16; 18:36) Àmọ́, àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ máa ń bọ̀wọ̀ fún ìjọba wọ́n sì máa ń pa òfin ìjọba mọ́ ní ibikíbi tí wọ́n bá wà, ìyẹn sì bá ohun tí Bíbélì sọ mu pé: “Ẹ san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì, [ìyẹn àwọn aláṣẹ] ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”—Máàkù 12:17; Róòmù 13:1, 2.

  8. Àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ máa ń fi ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣèwà hù. Àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ máa ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì ní gbogbo apá ìgbésí ayé wọn. (Éfésù 5:3-5; 1 Jòhánù 3:18) Àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ máa ń fayọ̀ sin “Ọlọ́run aláyọ̀” láìka bí nǹkan ṣe lè le tó fún wọn.—1 Tímótì 1:11.

  9. Àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ kì í pọ̀. (Mátíù 7:13, 14) Ìfẹ́ Ọlọ́run ni àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ máa ń ṣe, torí náà àwọn èèyàn kì í kà wọ́n sí, wọ́n máa ń fi wọ́n ṣẹ̀sín, wọ́n sì máa ń ṣe inúnibíni sí wọn.—Mátíù 5:10-12.

Ìsìn tòótọ́ kì í ṣe ‘ìsìn tó o bá ṣáà ti nífẹ̀ẹ́ sí’

Ó léwu téèyàn bá ń ṣe ìsìn kan torí pé ó kàn nífẹ̀ẹ́ sí i. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn “yóo kó àwọn olùkọ́ [ìsìn] tira, tí wọn yóo máa sọ ohun tí wọ́n fẹ́ gbọ́ fún wọn.” (2 Tímótì 4:3, Ìròhìn Ayọ̀) Àmọ́, Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká ṣe “ìjọsìn tí ó mọ́, tí ó sì jẹ́ aláìlẹ́gbin ní ojú Ọlọ́run àti Baba,” kódà tí ìsìn náà kò bá tiẹ̀ gbajúmọ̀.—Jákọ́bù 1:27; Jòhánù 15:18, 19.