Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Se Olorun Ti Kadara Igba Ti A Maa Ku??

Se Olorun Ti Kadara Igba Ti A Maa Ku??

Ohun tí Bíbélì sọ

Rárá, Ọlọ́run kò kádàrá ìgbà tí a máa kú. Dípò tí a ó fi gbà pé kádàrá wà, Bíbélì sọ pé “ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” ló sábà máa ń fa ikú.—Oníwàásù 9:11.

Ṣé Bíbélì náà kọ́ ló sọ pé “ìgbà kíkú” wà ni?

Bẹ́ẹ̀ ni, Oníwàásù 3:2 sọ pé “ìgbà bíbí, àti ìgbà kíkú, ìgbà gbíngbìn àti ìgbà kíká ohun tí a gbìn” wà. (Bíbélì Mímọ́) Àmọ́, ohun tí Bíbélì sọ ṣáájú àti lẹ́yìn ẹsẹ yìí fi hàn pé àwọn àyípoyípo ohun tó máa ń wáyé nígbèésí ayé ni Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. (Oníwàásù 3:1-8) Bí Ọlọ́run kò ṣe fi tipátipá mú àgbẹ̀ kan pé kó gbin irúgbìn kan lásìkò kan pàtó, bẹ́ẹ̀ náà ni kò ṣe kádàrá ìgbà tí a máa kú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀kọ́ pàtàkì tá a kọ́ ni pé kò yẹ ká jẹ́ kí àwọn nǹkan tí kò pọndandan gbà wá lọ́kàn débi pé a ó wá gbàgbé Ẹlẹ́dàá wa.—Oníwàásù 3:11; 12:1, 13.

Ẹ̀mí wa ṣì lè gùn

Láìka bí ìgbésí ayé ṣe kún fún ìdààmú tó, ẹ̀mí wa ṣì lè gùn tá a bá ń ṣe àwọn ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu. Bíbélì sọ pé: “Òfin ọlọ́gbọ́n jẹ́ orísun ìyè, láti yí ènìyàn padà kúrò nínú àwọn ìdẹkùn ikú.” (Òwe 13:14) Bákan náà, Mósè sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé ‘ọjọ́ wọn lè di gígùn’ tí wọ́n bá ṣègbọràn sí àwọn àṣẹ Ọlọ́run. (Diutarónómì 6:2) Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, tí a kò bá ṣọ́ra, a lè fúnra wa dá ẹ̀mí ara wa légbodò tá a bá lọ ń ṣe àwọn nǹkan tí kò dáa tàbí tí a ń hùwà òmùgọ̀.—Oníwàásù 7:17.

Láìka bí a ṣe ń hùwà ọgbọ́n tàbí ṣọ́ra tó, a ò lè bọ́ lọ́wọ́ ikú. (Róòmù 5:12) Síbẹ̀, nǹkan ṣì máa yí pa dà torí Bíbélì ṣèlérí pé ìgbà kan ń bọ̀ tí ‘ikú kì yóò sí mọ́.’—Ìṣípayá 21:4.