Ohun tí Bíbélì sọ

Bẹ́ẹ̀ ni. Díẹ̀ lára àwọn ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n láti inú Bíbélì tó ti ran ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin lọ́wọ́ láti ní ìdílé aláyọ̀ nìyí:

  1. Ẹ ṣe ìgbéyàwó lọ́nà tó bá òfin mu. Bí ìdílé bá máa láyọ̀, ó ṣe pàtàkì pé kí ọkùnrin àti obìnrin ṣe ìgbéyàwó lọ́nà tó bá òfin mu.Mátíù 19:4-6.

  2. Ẹ ní ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀. Bí o bá ṣe fẹ́ kí ọkọ tàbí aya rẹ máa ṣe sí ọ ni kí ìwọ náà máa ṣe sí i.Mátíù 7:12; Éfésù 5:25, 33.

  3. Ẹ má ṣe sọ ọ̀rọ̀ tí kò dáa. Ọ̀rọ̀ tó dára ni kí o máa sọ kódà tí ọkọ tàbí aya rẹ bá sọ ohun tó dùn ọ́ tàbí tó ṣe ohun tó dùn ọ́. (Éfésù 4:31, 32) Bíbélì sọ ní Òwe 15:1 pé: “Ìdáhùn kan, nígbà tí ó bá jẹ́ lọ́nà pẹ̀lẹ́, máa ń yí ìhónú padà, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí ń fa ìrora máa ń ru ìbínú sókè.”

  4. Ẹ jẹ́ olóòótọ́ sí ara yín. Ẹni tó jẹ́ ọkọ tàbí aya rẹ nìkan ni kí ìfẹ́ rẹ máa fà sí, òun nìkan sì ni kí ẹ jọ máa ní ìbálòpọ̀. (Mátíù 5:28) Bíbélì sọ pé: “Kí ìgbéyàwó ní ọlá láàárín gbogbo ènìyàn, kí ibùsùn ìgbéyàwó sì wà láìní ẹ̀gbin.”Hébérù 13:4.

  5. Ẹ máa kọ́ àwọn ọmọ yín tìfẹ́tìfẹ́. Ẹ má ṣe gbàgbàkugbà fún ọmọ yín, ẹ má sì ṣe lé koko mọ́ ọn.Òwe 29:15; Kólósè 3:21.