Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ǹjẹ́ Èṣù Lè Darí Àwọn Èèyàn?

Ǹjẹ́ Èṣù Lè Darí Àwọn Èèyàn?

Ohun tí Bíbélì sọ

Ipa tí Èṣù àti àwọn ẹ̀mí èṣù ń ní lórí aráyé pọ̀ gan-an débi pé Bíbélì sọ pé: “Gbogbo ayé patapata wà lábẹ́ Èṣù.” (1 Jòhánù 5:19, Bíbélì Ìròhìn Ayọ̀) Bíbélì jẹ́ ká mọ àwọn ọ̀nà tí Èṣù gbà ń nípa lórí àwọn èèyàn.

  • Ẹ̀tàn. Bíbélì rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n “kọ ojú ìjà sí àrékérekè Èṣù.” (Éfésù 6:11, Bíbélì Mímọ́ ) Ọ̀kan lára àwọn àrékérekè Èṣù ni bó ṣe ń lo ẹ̀tàn láti mú kí àwọn èèyàn gbà pé ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀.2 Kọ́ríńtì 11:13-15.

  • Ìbẹ́mìílò. Èṣù máa ń lo àwọn abókùúsọ̀rọ̀, àwọn tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ oríire, àwọn woṣẹ́woṣẹ́ àti àwọn awòràwọ̀ láti ṣi àwọn èèyàn lọ́nà. (Diutarónómì 18:10-12) Lílo oògùn tó ní agbára òkùnkùn nínú, ìmúnimúyè àti ṣíṣe àṣàrò tí kò ní láárí wà lára àwọn nǹkan tó ń jẹ́ kí àwọn ẹ̀mí èṣù máa darí àwọn èèyàn.Lúùkù 11:24-26.

  • Ìsìn èké. Ìsìn tó bá ń fi ẹ̀kọ́ èké kọ́ àwọn èèyàn ń ṣì wọ́n lọ́nà, ó sì ń mú kí wọ́n ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. (1 Kọ́ríńtì 10:20) Bíbélì pe irú àwọn ẹ̀kọ́ èké bẹ́ẹ̀ ní “àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀mí èṣù.”1 Tímótì 4:1.

  • Ẹ̀mí èṣù. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn èèyàn kan tí ẹ̀mí èṣù ń darí. Lọ́pọ̀ ìgbà, ẹ̀mí yìí máa ń fọ́ àwọn tó ní i lójú, ó máa ń sọ wọ́n di odi tàbí kó jẹ́ kí wọ́n máa ṣe ara wọn léṣe.Mátíù 12:22; Máàkù 5:2-5.

Bí a kò ṣe ní jẹ́ kí Èṣù darí wa

Kò yẹ kó o máa bẹ̀rù pé àwọn ẹ̀mí èṣù á máa darí rẹ torí Bíbélì sọ àwọn nǹkan tí o lè ṣe láti kọjú ìjà sí Èṣù, tí wàá sì ṣẹ́gun rẹ̀:

  • Kọ́ bí wàá ṣe mọ àwọn ọ̀nà tí Èṣù ń lò, kí o lè mọ “àwọn ète-ọkàn rẹ̀.”2 Kọ́ríńtì 2:11.

  • Kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì kí o sì máa fi àwọn ohun tí ò ń kọ́ ṣèwà hù. Tí o bá ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, wàá lè dáàbò bò ara rẹ lọ́wọ́ ìdarí Èṣù.Éfésù 6:11-18.

  • Kó gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ìbẹ́mìílò dà nù. (Ìṣe 19:19) Tó fi mọ́ orin, ìwé, àwòrán ara ògiri tàbí fídíò tó ń gbé ìbẹ́mìílò lárugẹ.