Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Kí Ní Bíbélì Sọ Nípa Ibi Tí Ọdún Halloween Ti Wá?

Kí Ní Bíbélì Sọ Nípa Ibi Tí Ọdún Halloween Ti Wá?

Ohun tí Bíbélì sọ

Bíbélì kò mẹ́nu kan ọdún Halloween rárá. Àmọ́, àwọn ohun tó pilẹ̀ ọdún Halloween láyé àtijọ́ àti bí wọ́n ṣe ń ṣe ayẹyẹ yìí lónìí fi hàn pé àṣà tó wá látinú ẹ̀kọ́ èké ni, ó sì ní í ṣe pẹ̀lú àwọn òkú àti àwọn ẹ̀mí àìrí tàbí àwọn ẹ̀mí èṣù.—Wo àkọlé náà, “Bí ọdún Halloween ṣe bẹ̀rẹ̀ àti àwọn àṣà rẹ̀.”

Bíbélì sọ pé: “Kí a má ṣe rí láàárín rẹ ẹnikẹ́ni tí ń . . . wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ abẹ́mìílò tàbí olùsàsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí ẹnikẹ́ni tí ń ṣèwádìí lọ́dọ̀ òkú.” (Diutarónómì 18:10-12) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, àwọn kan kò ka ọdún Halloween sí ohun tó burú, síbẹ̀, Bíbélì fi hàn pé àwọn àṣà tí ọdún yìí ń gbé lárugẹ burú gan-an. Ní 1 Kọ́ríńtì 10:20, 21, Bíbélì sọ pé: “Èmi kò sì fẹ́ kí ẹ di alájọpín pẹ̀lú àwọn ẹ̀mí èṣù. Ẹ kò lè máa mu ife Jèhófà àti ife àwọn ẹ̀mí èṣù.”

Bí ọdún Halloween ṣe bẹ̀rẹ̀ àti àwọn àṣà rẹ̀

  1. Àjọ̀dún Samhain: Bí a bá tọpasẹ̀ ibi tí ọdún Halloween ti bẹ̀rẹ̀, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé: “Àjọ̀dún àwọn abọ̀rìṣà ayé àtijọ́ ni, èyí tó wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀yà Celt, ní ohun tó lé ní ẹgbàá [2,000] ọdún sẹ́yìn. Àwọn ẹ̀yà Celt gbà gbọ́ pé àwọn òkú máa rìn kiri láàárín àwọn alààyè nígbà tí wọ́n ń ṣe ọdún yìí. Wọ́n gbà gbọ́ pé àsìkò táwọn bá ń ṣe àjọ̀dún Samhain ni àwọn èèyàn lè ṣè ìbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn òkú.” Àmọ́, ohun tí Bíbélì fi kọ́ni ṣe kedere, ó ní àwọn “òkú kò mọ nǹkan kan rárá.” (Oníwàásù 9:5) Torí náà, àwọn òkú kò lè bẹ àwọn alààyè wò.

  2. Bí wọ́n ṣe ń múra nígbà ọdún Halloween, súìtì àti àṣà fífọgbọ́n tọrọ nǹkan: Ìwé Halloween—An American Holiday, An American History, sọ pé àwọn ẹ̀yà Celt máa ń lo ìbòjú tó lè dẹ́rù bani kí àwọn ẹ̀mí àìrí tó ń rín gbéregbère káàkiri lè rò pé ara àwọn ni wọ́n, tí wọ́n á sì fi wọ́n sílẹ̀. Àwọn míì máa ń fi súìtì rúbọ sí àwọn ẹ̀mí àìrí yìí láti lè tù wọ́n lójú. Ní ilẹ̀ Yúróòpù àtijọ́, àwọn àlùfáà Kátólíìkì mú àwọn àṣà ìbọ̀rìṣà wọ inú ẹ̀sìn wọn, wọ́n á sọ pé kí àwọn ọmọ ìjọ wọn lo ìbòjú, kí wọ́n sì máa tọrọ àwọn ẹ̀bùn kékeré kiri láti ojúlé dé ojúlé. Bíbélì kò fàyè gba àwọn èèyàn láti da àwọn àṣà inú ìsìn èké pọ̀ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run.2 Kọ́ríńtì 6:17.

  3. Àwọn ẹ̀mí àìrí, àǹjọ̀nnú, àwọn èèyàn tó di ìkookò àti àwọn àjẹ́: Àwọn nǹkan yìí ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀mí èṣù. (Ìwé Halloween Trivia) Bíbélì sọ pé ká kọ ojú ìjà si àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú, kì í ṣe pé ká máa bá wọn ṣe àjọ̀dún.Éfésù 6:12.

  4. Èso elégédé tí wọ́n gbẹ́ àti àtùpà tí wọ́n máa ń tàn lásìkò ọdún Halloween: Láye àtijọ́, ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, “àwọn oníbàárà máa ń lọ láti ojúlé kan sí ìkejì, wọ́n á máa béèrè oúnjẹ lọ́wọ́ àwọn èèyàn lẹ́yìn tí wọ́n bá ti ṣàdúrà fún àwọn òkú,” wọ́n á sì gbé irú “èso kan tí wọ́n gbẹ́ ojú àti eyín èèyàn sí lára, tí wọ́n sì tan iná àbẹ́là sínú rẹ̀ dání bí àtùpà. Ẹ̀mí àwọn tó ń joró nínú pọ́gátórì ni àbẹ́là tí wọ́n tàn yìí dúró fún.” (Ìwé Halloween—From Pagan Ritual to Party Night) Àwọn míì sọ pé àwọn àtùpà yìí ni wọ́n fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jìnnà. Nígbà tó fi máa di àárín ọdún 1870 sí ọdún 1899, ní Amẹ́ríkà ti Àríwá, wọ́n fi àtùpà tí wọ́n fi èso elégédé ṣe rọ́pò èyí tí wọ́n ń lò tẹ́lẹ̀ torí pé èso elégédé pọ̀ dáadáa, ó sì rọrùn láti dá ihò sí lára jú èyí tí wọ́n ń lò tẹ́lẹ̀ lọ. Gbogbo àwọn àṣà àti ìgbàgbọ́ inú àjọ̀dún yìí, ìyẹn ìgbàgbọ́ àìleèkú ọkàn, ẹ̀kọ́ pọ́gátórì àti gbígbàdúrà fún àwọn òkú kò bá Bíbélì mu.Ìsíkíẹ́lì 18:4.