Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Báwo Lo Ṣe Lè Borí Ìbẹ̀rù Ikú?

Báwo Lo Ṣe Lè Borí Ìbẹ̀rù Ikú?

Ohun tí Bíbélì sọ

A máa ń bẹ̀rù ikú lóòótọ́ torí ọ̀tá wa ni, a sì máa n sa gbogbo ipá wa ká lè dáàbò bo ẹ̀mí wa. (1 Kọ́ríńtì 15:26) Àmọ́, ìbẹ̀rù ikú tí kò bọ́gbọ́n mu nítorí ìtàn èké tàbí ìgbàgbọ́ nínú àwọn ohun asán ti fi àwọn èèyàn “sábẹ́ ìsìnrú ní gbogbo ìgbésí ayé wọn.” (Hébérù 2:15) Tó o bá ń bẹ̀rù ikú ju bó ṣe yẹ lọ, o kò ní gbádùn ìgbésí ayé rẹ, àmọ́ tó o bá mọ òtítọ́, wàá bọ́ lọ́wọ́ ìbẹ̀rù ikú.Jòhánù 8:32.

Òtítọ́ nípa ohun tí ikú jẹ́

  • Àwọn òkú kò mọ nǹkan kan. (Sáàmù 146:4) Má ṣe máa bẹ̀rù pé wàá jìyà tàbí joró lẹ́yìn tó o bá kú, torí pé Bíbélì fi ikú wé oorun.Sáàmù 13:3; Jòhánù 11:11-14.

  • Àwọn òkú kò lè pa wá lára. Kódà, àwọn oníjàgídíjàgan tó jẹ́ ọ̀tá wa tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ tí di “aláìlè-ta-pútú nínú ikú.” (Òwe 21:16) Bíbélì sọ pé: “ìkórìíra wọn àti owú wọn ti ṣègbé.”Oníwàásù 9:6.

  • Ikú kì í ṣe òpin ìrìn àjò ẹ̀dá láyé. Ọlọ́run yóò jí àwọn èèyàn tó ti ku dìde nípasẹ̀ àjíǹde.Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 24:15.

  • Ọlọ́run ṣèlérí pé ìgbà kan ń bọ̀ tí ‘ikú kì yóò sí mọ́.’ (Ìṣípayá 21:4) Nígbà yẹn, àwọn èèyàn á ti bọ́ pátápátá lọ́wọ́ ìbẹ̀rù ikú èyíkéyìí. Bíbélì sọ pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”Sáàmù 37:29.