Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Kí Ni Àwọn Ìtàn Inú Bíbélì Tó Tẹ̀ Léra Fi Hàn Nípa Ọdún 1914?

Kí Ni Àwọn Ìtàn Inú Bíbélì Tó Tẹ̀ Léra Fi Hàn Nípa Ọdún 1914?

Ohun tí Bíbélì sọ

Bí àwọn ìtàn inú Bíbélì ṣe tẹ̀ léra fi hàn pé ọdún 1914 ni Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ní ọ̀run. Àsọtẹ́lẹ̀ kan tó wà nínú ìwé Dáníẹ́lì orí kẹrin ló jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀.

Ohun tí àsọtẹ́lẹ̀ náà dá lé. Ọlọ́run mú kí Nebukadinésárì Ọba Bábílónì lá àlá kan tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀, ó dá lórí igi arabarìbì kan tí wọ́n gé lulẹ̀. Wọ́n kò jẹ́ kí gbòǹgbò rẹ̀ hù títí “ìgbà méje” fi kọjá, lẹ́yìn èyí, igi náà yóò hù pa dà.Dáníẹ́lì 4:1, 10-16.

Bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe kọ́kọ́ nímùúṣẹ. Igi ńlá náà dúró fún Nebukadinésárì ọba fúnra rẹ̀. (Dáníẹ́lì 4:20-22) Ṣe ló dà bíi pé wọ́n gé e lulẹ̀ nígbà tó pàdánù ipò ọba rẹ̀, tí orí rẹ̀ sì dà rú fún ọdún méje. (Dáníẹ́lì 4:25) Àmọ́ nígbà tí Ọlọ́run jẹ́ kí orí rẹ̀ pé pa dà, Nebukadinésárì pa dà sórí ìtẹ́ rẹ̀, ó sì wá gbà pé Jèhófà ni Olùṣàkóso.Dáníẹ́lì 4:34-36.

Ẹ̀rí tó fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ yẹn máa ní ìmúṣẹ tó jùyẹn lọ. Lájorí ohun tí àsọtẹ́lẹ̀ náà wà fún ni pé “kí àwọn ènìyàn tí ó wà láàyè lè mọ̀ pé Ẹni Gíga Jù Lọ ni Olùṣàkóso nínú ìjọba aráyé, ẹni tí ó bá sì fẹ́, ni ó ń fi í fún, ó sì ń gbé àní ẹni rírẹlẹ̀ jù lọ nínú aráyé ka orí rẹ̀.” (Dáníẹ́lì 4:17) Ṣé Nebukadinésárì tó jẹ́ agbéraga ni Ọlọ́run wá fẹ́ gbé irú ìṣàkóso bẹ́ẹ̀ lé lọ́wọ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn? Rárá o, torí pé Ọlọ́run ti mú kí Nebukadinésárì lá àlá míì tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn pé Òun ò ní gbé ìjọba náà fún un, òun ò sì ní gbé e fún alákòóso èyíkéyìí mìíràn. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ “yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé.”Dáníẹ́lì 2:31-44.

Ṣáájú ìgbà yẹn, Ọlọ́run ti ṣètò ìjọba kan tí yóò máa ṣojú fún ìṣàkóso rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, ìyẹn orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́. Ọlọ́run jẹ́ kí wọ́n “run” ìjọba yẹn torí pé àwọn ọba wọn ò pa àṣẹ rẹ̀ mọ́, ó sì ṣèlérí pé òun máa gbé ìjọba fún “ẹni tí ó ní ẹ̀tọ́ lọ́nà òfin.” (Ìsíkíẹ́lì 21:25-27) Bíbélì sọ pé Jésù Kristi lẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ lọ́nà òfin tí Ọlọ́run máa gbé ìjọba tí yóò wà títí láé náà fún. (Lúùkù 1:30-33) Jésù ní tirẹ̀ kò dà bí Nebukadinésárì agbéraga, Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa Jésù pé ó jẹ́ “ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà.”Mátíù 11:29.

Kí ni igi tí Dáníẹ́lì orí kẹrin mẹ́nu bà dúró fún? Nígbà míì, Bíbélì máa ń fi igi ṣàpèjúwe ìṣàkóso. (Ìsíkíẹ́lì 17:22-24; 31:2-5) Nínú ìmúṣẹ tó túbọ̀ gbòòrò tí ìwé Dáníẹ́lì orí kẹrin ní, igi arabarìbì náà dúró fún ìṣàkóso Ọlọ́run.

Kí ni gígé tí wọ́n gé igi náà lulẹ̀ túmọ̀ sí? Bí gígé tí wọ́n gé igi náà lulẹ̀ ṣe dúró fún bí wọ́n ṣe fòpin sí ìṣàkóso Nebukadinésárì fúngbà díẹ̀, ó tún dúró fún bí wọ́n ṣe fòpin sí ìṣàkóso Ọlọ́run fúngbà díẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Èyí ṣẹlẹ̀ nígbà tí Nebukadinésárì pa Jerúsálẹ́mù run, ìyẹn ìlú tí àwọn ọba Ísírẹ́lì ti jókòó lórí “ìtẹ́ Jèhófà” láti ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba tó ń ṣojú fún Ọlọ́run.1 Kíróníkà 29:23.

Kí ni “ìgbà méje” náà dúró fún? “Ìgbà méje” náà dúró fún àkókò tí Ọlọ́run gba àwọn orílẹ̀-èdè láyè láti ṣàkóso lórí ayé, tí ìjọba èyíkéyìí tó gbé kalẹ̀ ò sì dí wọn lọ́wọ́. “Ìgbà méje” náà bẹ̀rẹ̀ ní oṣù October, ọdún 607 Ṣ.S.K táwọn ará Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù run bí ìtàn Bíbélì ṣe sọ. *2 Àwọn Ọba 25:1, 8-10.

Báwo ni “ìgbà méje” náà ṣe gùn tó? Kò lè jẹ́ ọdún méje péré bó ṣe rí ní ti ọ̀rọ̀ Nebukadinésárì. Jésù jẹ́ ká mọ bó ṣe gùn tó nígbà tó sọ pé “àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì tẹ Jerúsálẹ́mù [tó ṣàpẹẹrẹ ìṣàkóso Ọlọ́run] mọ́lẹ̀, títí àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè yóò fi pé.” (Lúùkù 21:24) “Àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè,” ìyẹn àkókò tí Ọlọ́run fi fàyè gba kí ‘àwọn orílẹ̀-èdè tẹ’ ìṣàkóso rẹ̀ mọ́lẹ̀, jẹ́ ọ̀kan náà pẹ̀lú “ìgbà méje” tí ìwé Dáníẹ́lì orí 4 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Èyí wá jẹ́ ká mọ̀ pé “ìgbà méje” náà kò tíì dópin ní gbogbo ìgbà tí Jésù fi wà lórí ilẹ̀ ayé pàápàá.

Bíbélì sọ bá a ṣe lè mọ bí “ìgbà méje” náà á ṣe gùn tó. Ó sọ pé “àkókò” mẹ́ta àti ààbọ̀ jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀fà [1,260] ọjọ́, nípa bẹ́ẹ̀, “ìgbà méje” tó jẹ́ ìlọ́po méjì rẹ̀ yóò jẹ́, ẹgbẹ̀rún méjì, ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé ogún [2,520] ọjọ́. (Ìṣípayá 12:6, 14) Tá a bá wá fi ìlànà àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó sọ pé “ọjọ́ kan fún ọdún kan” díwọ̀n rẹ̀, a jẹ́ pé 2,520 ọjọ́ dúró fún 2,520 ọdún. Torí náà, “ìgbà méje” yìí, tàbí ẹgbẹ̀rún méjì, ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé ogún [2,520] ọdún náà, ti dópin ní October 1914.Númérì 14:34; Ìsíkíẹ́lì 4:6.

^ ìpínrọ̀ 10 Tó o bá ń fẹ́ kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa ìdí tá a ṣe lo ọdún 607 Ṣ.S.K, wo àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Ìgbà Wo Ni Wọ́n Pa Jerúsálẹ́mù Àtijọ́ Run?—Apá Kìíní,” lójú ìwé 26 sí 31 nínú Ilé Ìṣọ́ October 1, 2011 àti Apá Kejì àpilẹ̀kọ náà tó wà lójú ìwé 22 sí 28 nínú Ilé Ìṣọ́ November 1, 2011.