Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ọdún Àjíǹde?

Ohun tí Bíbélì sọ

Ayẹyẹ Ọdún àjíǹde kò bá Bíbélì mu. Tó o bá ka ìtàn bí ọdún àjíǹde ṣe bẹ̀rẹ̀, wàá mọ ohun tí ọdún àjíǹde túmọ̀ sí gan-an. Ó dá lórí àṣà ìbímọlémọ ìgbà àtijọ́. Gbé àwọn kókó yìí yẹ̀wò.

  1. Orúkọ: Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica sọ pé: “Ibi tí orúkọ náà Easter, lédè Gẹ̀ẹ́sì ti wá kò dá wa lójú; àlùfáà ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan tó ń jẹ́ Bede tó gbáyé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹjọ ló mú orúkọ náà jáde látinú Eostre tó jẹ́ orúkọ abo ọlọ́run àwọn ará ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.” Àwọn ìwé ìwádìí míì pe abo ọlọ́run yìí ní Astarte, ìyẹn abo ọlọ́run ìbímọlémọ àwọn ará Fòníṣíà tó ṣe déédéé pẹ̀lú abo ọlọ́run àwọn ará Bábílónì tí wọ́n ń pè ní Ishtar.

  2. Ehoro: Ehoro ni wọ́n fi ṣe àmì ìbímọlémọ “èyí tí wọ́n ti ń lò láti ìgbà àtijọ́ tí wọ́n bá ńṣe ayẹyẹ, ó sì jẹ́ àmì tí àwọn kèfèrí Ilẹ̀ Yúróòpù àti ti Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé máa ń lò tí wọ́n bá ń ṣe àjọ̀dún nígbà ìrúwé.”Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica.

  3. Ẹyin: Gẹ́gẹ́ bí ìwé Funk & Wagnalls Standard Dictionary of Folklore, Mythology and Legend ṣe sọ, bí àwọn èèyàn ṣe máa ń wá ẹyin Ọdún Àjíǹde tí wọ́n lérò pé ara ehoro Ọdún Àjíǹde ló ti wá kiri “kì í ṣe nǹkan ṣeréṣeré rárá, torí ó jẹ́ apá kékeré lara àmì ìbímọlémọ tí wọ́n kà sí pàtàkì.” Nínú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn kan, wọ́n gbà gbọ́ pé ẹyin Ọdún Àjíǹde tí wọ́n ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ “lè jẹ́ kéèyàn ní ayọ̀, aásìkí, ìlera àti ààbò lọ́nà àrà.”—Ìwé Traditional Festivals.

  4. Aṣọ tuntun lọ́jọ́ Ọdún Àjíǹde: “Nǹkan tí kò bójú mu rárá ni wọ́n kà á sí àti pé àmì orí burúkú ni fún ẹni tí kò bá wọ aṣọ tuntun lọ́jọ́ ọdún tó bá ń lọ júbà abo ọlọ́run ìgbà ìrúwé ti àwọn ará Scandinavia tí wọ́n ń pè ní Eastre.”—Ìwé The Giant Book of Superstitions.

  5. Ìjọsìn àárọ̀ ọjọ́ Ọdún Àjíǹde: Inú àṣà ẹ̀sìn àwọn tó ń bọ oòrùn nígbà àtijọ́ ni àṣà yìí ti wá, èyí “tó máa ń wáyé níbẹ̀rẹ̀ ìgbà ìrúwé, lásìkò tí oòrùn dé agbede méjì ayé, tí ọ̀sán àti òru sì gùn bákan náà, ìgbà yẹn ni wọ́n máa ń kí oòrùn àti agbára ńlá rẹ̀ káàbọ̀ láti ìrìn-àjò kó lè mú kí gbogbo nǹkan ọ̀gbìn tuntun hù.”—Ìwé Celebrations—The Complete Book of American Holidays.

Ìwé The American Book of Days ṣàlàyé ibi tí Ọdún Àjíǹde ti wá, ó ní: “Kò sí àníàní pé ńṣe ni Ṣọ́ọ̀ṣì nígbà náà lọ́hùn-ún tẹ́wọ́ gba àwọn àṣà kèfèrí, tí wọ́n sì mú un wọnú ìsìn Kristẹni.”

Bíbélì kìlọ̀ pé ká má sọ pé à ń sin Ọlọ́run ká wá máa tẹ̀ lé àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ tí inú Ọlọ́run kò dùn sí. (Máàkù 7:6-8) Ìwé 2 Kọ́ríńtì 6:17 sọ pé: Ẹ “‘ya ara yín sọ́tọ̀,’ ni Jèhófà wí, ‘kí ẹ sì jáwọ́ nínú fífọwọ́kan ohun àìmọ́.’” Ọdún àwọn kèfèrí ni Ọdún Àjíǹde, kò sì yẹ kí àwọn tó bá fẹ́ múnú Ọlọ́run dùn máa ṣe ọdún yìí.