Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Fínfín Àmì sí Ara?

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Fínfín Àmì sí Ara?

Ohun tí Bíbélì sọ

Ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni Bíbélì mẹ́nu kan fínfín àmì sí ara ẹni, inú ìwé Léfítíkù  19:28, ló ti sọ ọ́, ó ní: “Ẹ kò . . . gbọ́dọ̀ fín àmì sí ara yín.” Ọlọ́run ló pàṣẹ yìí fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, àṣẹ náà ló mú kí wọ́n yàtọ̀ sí àwọn èèyàn tó wà láyìíká wọn tó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n fín orúkọ àtàwọn àmì àwọn ọlọ́run tí wọ́n ń bọ sí ara wọn. (Diutarónómì 14:2) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Òfin tí Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì yìí kò de àwọn Kristẹni, síbẹ̀ ó yẹ kí wọ́n tẹ̀ lé ìlànà tó wà nínú òfin yìí.

Ǹjẹ́ ó yẹ kí Kristẹni fín àmì tàbí ya àwòrán sára?

Àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí á jẹ́ kó o ronú lórí ọ̀rọ̀ yìí:

  • “Kí àwọn obìnrin máa . . . ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà.” (1 Tímótì 2:9) Bí ìlànà yìí ṣe kan àwọn obìnrin náà ló kan àwọn ọkùnrin. Ó yẹ ká máa ro bí ohun tá a bá ṣe ṣe máa rí lára àwọn ẹlòmíì, kò yẹ ká máa pe àfiyèsí tí kò tọ́ sí ara wa.

  • Àwọn kan máa ń fín ara kí wọ́n lè fi irú ẹni tí wọ́n jẹ́ hàn tàbí torí pé wọ́n lè ṣe ohun tó bá wù wọ́n, nígbà tí àwọn míì ń fín àmì sára nítorí wọ́n gbà pé àwọn làwọn ni ara àwọn. Àmọ́, Bíbélì rọ̀ àwọn Kristẹni pé: “Ẹ fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè, mímọ́, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ pẹ̀lú agbára ìmọnúúrò yín.” (Róòmù 12:1) Lo “agbára ìmọnúúrò” rẹ láti pinnu bóyá ó yẹ kó o fín àmì sí ara. Tó o bá fín àmì sí ara rẹ torí pé àṣà tó wà lòde nìyẹn tàbí torí pé o fẹ́ fi hàn pé ìwọ náà wà nínú ẹgbẹ́ kan, rántí pé ara fínfín lè má wù ọ́ mọ́ tó bá yá, àmọ́ o kò ní lè pa ohun tó o ti fín sára rẹ́ mọ́. Ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu ni wàá ṣe tí o bá ń ronú nípa ìdí tó o fi fẹ́ fín àmì sára rẹ.—Òwe 4:7.

  • “Àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní, ṣùgbọ́n ó dájú pé àìní ni olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń kánjú forí lé.” (Òwe 21:5) Ìkánjú làwọn tó ń fín ara fi máa ń pinnu láti ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì máa ní ipa tí kì í tán bọ̀rọ̀ lórí àjọṣe wọn pẹ̀lú àwọn míì àti lórí iṣẹ́ wọn. Ọ̀pọ̀ ìrora ni àwọn tó bá fẹ́ pa ohun tí wọ́n fín sára rẹ́ máa ń ní, ó sì máa ń ná wọn lówó gan-an. Ìwádìí tí àwọn kan ṣe àti bí owó ṣe túbọ̀ ń wọlé fún àwọn ilé iṣẹ́ tó ń pa ohun tí àwọn èèyàn fín sára rẹ́ fi hàn pé ọ̀pọ̀ àwọn tó fín àmì sára ló kábàámọ̀ pé àwọn ṣe é.