Ohun tí Bíbélì sọ

Bẹ́ẹ̀ ni, ìdí ni pé a lè rí ojúlówó ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ “Ọlọ́run, ẹni tí ń tu àwọn tí a rẹ̀ sílẹ̀ nínú.2 Kọ́ríńtì 7:6.

Ohun tí Ọlọ́run máa ń fún àwọn tó ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn

  • Agbára. Ọlọ́run kò ní mú gbogbo ìṣòro tó o ní kúrò torí kó lè tù ẹ́ nínú, àmọ́ ńṣe ni yóò gbọ́ àdúrà rẹ tó o bá béèrè pé kó fún ẹ ní agbára tí wàá fi lè fara dà àwọn ìṣòro náà. (Fílípì 4:13) Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Ọlọ́run máa gbọ́ àdúrà rẹ torí Bíbélì sọ pé: “Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; Ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.” (Sáàmù 34:18) Kódà tí o kò bá lè sọ bí ẹ̀dùn ọkàn tó o ní ṣe rí lára rẹ, Ọlọ́run lè gbọ́ àdúrà tó o bá gbà fún ìrànlọ́wọ́.Róòmù 8:26, 27.

  • Àwọn àpẹẹrẹ rere. Ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Láti inú ibú ni mo ti ké pè ọ́.” Ẹni tó kọ sáàmù yìí lè fara da ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn tó ní nígbà tó rántí pé Ọlọ́run máa ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini. Ó sọ fún Ọlọ́run pé: “Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ìṣìnà ni ìwọ ń ṣọ́, Jáà, Jèhófà, ta ni ì bá dúró? Nítorí ìdáríjì tòótọ́ ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ, Kí a lè máa bẹ̀rù rẹ.Sáàmù 130:1, 3, 4.

  • Ìrètí. Yàtọ̀ sí pé Ọlọ́run ń tù wá nínú nísinsìnyí, ó ti ṣèlérí pé òun máa mú àwọn ìṣòro tó ń fa ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn kúrò. “Àwọn ohun àtijọ́ [tó ní nínú ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn] ni a kì yóò sì mú wá sí ìrántí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wá sí ọkàn-àyà,” nígbà tí Ọlọ́run bá mú ìlérí rẹ̀ ṣẹAísáyà 65:7.

Àkíyèsí: Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà lóòtọ́ pé Ọlọ́run máa ń ràn wá lọ́wọ́, a sì máa ń tọ́jú ara wa ní ilé ìwòsàn tá a bá ń ṣàìsàn, irú bí ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn tó le gan-an. (Máàkù 2:17) Àmọ́ ṣá o, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò ní sọ irú ìtọ́jú kan pàtó tó yẹ kó o gbà lọ́dọ̀ àwọn dókítà fún ẹ; olúkálukú ni yóò pinnu irú ìtọ́jú tó fẹ́ fúnra rẹ̀.