Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Kí Ni Àsọtẹ́lẹ̀?

Kí Ni Àsọtẹ́lẹ̀?

Ohun tí Bíbélì sọ

Ọ̀rọ̀ tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run tàbí ohun tí Ọlọ́run fi han ẹnì kan pé ó máa ṣẹlẹ̀ là ń pè ní àsọtẹ́lẹ̀. Bíbélì sọ pé àwọn wòlíì “sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ti ń darí wọn.” (2 Pétérù 1:20, 21) Torí náà, wòlíì ni ẹni tí Ọlọ́run fi iṣẹ́ rán sáwọn ẹlòmíì, tó sì ń jíṣẹ́ ọ̀hún.Ìṣe 3:18.

Báwo ni Ọlọ́run ṣe bá àwọn wòlíì sọ̀rọ̀?

Oríṣiríṣi ọ̀nà ni Ọlọ́rùn gbà bá àwọn wòlíì rẹ̀ sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀:

  • Ó kọ̀wé. Ó kéré tán, Ọlọ́run lo ọ̀nà yìí lẹ́ẹ̀kan. Ọlọ́run kọ Òfin Mẹ́wàá, ó sì fún Mósè ní tààràtà.Ẹ́kísódù 31:18.

  • Ó tipasẹ̀ àwọn áńgẹ́lì bá wọn sọ̀rọ̀. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run lo áńgẹ́lì kan láti sọ fún Mósè nípa iṣẹ́ tó máa lọ jẹ́ fún Fáráò nílẹ̀ Íjíbítì. (Ẹ́kísódù 3:2-4, 10) Tí Ọlọ́run bá fẹ́ kí wọ́n sọ ọ́ bí òun ṣe fẹ́ ẹ gan-an, ó máa ń pàṣẹ pé kí àwọn áńgẹ́lì pe àwọn ọ̀rọ̀ náà fún wọn. Ohun tó ṣe nígbà tó bá Mósè sọ̀rọ̀ nìyẹn, ó ní: “Kọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sílẹ̀, . . . nítorí ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni mo bá ìwọ àti Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú.”Ẹ́kísódù 34:27. *

  • Ìran. Ọlọ́run lè mú kí wòlíì kan rí ìran láìsùn. (Aísáyà 1:1; Hábákúkù 1:1) Nígbà míì, ẹni tó ń rí ìran náà á tún wà nínú ìran ọ̀hún, á sì máa ṣe nǹkan kan. (Lúùkù 9:28-36; Ìṣípayá 1:10-17) Ọlọ́rùn tún máa ń mú kó dà bíi pé ẹnì kan ti sùn, kó wá fi ìran hàn án. (Ìṣe 10:10, 11; 22:17-21) Bákan náà, Ọlọ́run máa ń fi ìran han wòlíì lójú àlá.Dáníẹ́lì 7:1; Ìṣe 16:9, 10.

  • Ó máa ń darí èrò wọn. Ọlọ́run máa ń fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí àwọn wòlíì rẹ̀ lọ́kàn. Ohun tí Bíbélì ní lọ́kàn nìyẹn nígbà tó sọ pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí.” Tá a bá fẹ́ sọ pé “Ọlọ́run mí sí” lọ́nà míì, a lè sọ pé “ní ìmísí Ọlọ́run.” (2 Tímótì 3:16; Bíbélì Mímọ́) Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ tàbí ipá ìṣiṣẹ́ rẹ̀ “mí” èrò ọkàn rẹ̀ sínú ọkàn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Ọlọ́run máa jẹ́ kó mọ ohun tí òun ní lọ́kàn, wòlíì yẹn á wá kọ ọ́ sílẹ̀ lọ́rọ̀ ara ẹ̀.2 Sámúẹ́lì 23:1, 2.

Ṣe gbogbo ìgbà ni àsọtẹ́lẹ̀ máa ń dá lórí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú?

Rárá, kì í ṣe ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú nìkan ni àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì máa ń dá lé. Síbẹ̀, àwọn tí Ọlọ́run sọ sábà máa ń tan mọ́ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú lọ́nà kan ṣá. Bí àpẹẹrẹ, lemọ́lemọ́ ni àwọn wòlíì Ọlọ́run ń kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì pé kí wọ́n yíwà burúkú wọn pa dà. Wọ́n kìlọ̀ fún wọn pé tí wọ́n bá yíwà pa dà, Ọlọ́run máa bù kún wọn, tí wọ́n bá sì kọ̀, ó máa fìyà jẹ wọ́n. (Jeremáyà 25:4-6) Ohun tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ṣe ló máa pinnu ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn.Diutarónómì 30:19, 20.

Àpẹẹrẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì ti kò dá lórí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú

  • Nígbà kan táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ Ọlọ́run pé kó ran àwọn lọ́wọ́, ó rán wòlíì kan sí wọn kó lè ṣàlàyé fún wọn pé torí pé wọn ò ṣègbọràn sí àṣẹ tí Ọlọ́run pa fún wọn ni Òun ò ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́.Onídàájọ́ 6:6-10.

  • Nígbà tí Jésù ń bá obìnrin ará Samáríà sọ̀rọ̀, ó sọ àwọn ohun kan tí obìnrin náà ti ṣe sẹ́yìn fún un, ó sì dájú pé Ọlọ́run ló fi hàn án. Bí Jésù ò tiẹ̀ bá obìnrin náà sọ ohunkóhun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, obìnrin náà gbà pé wòlíì ni.Jòhánù 4:17-19.

  • Nígbà tí àwọn ọ̀tá Jésù ń dán an wò, wọ́n bò ó lójú, wọ́n lù ú, wọ́n wá sọ pé: “Sọ tẹ́lẹ̀. Ta ni ó gbá ọ?” Wọn ò ní kí Jésù sọ ohunkóhun tó máa ṣẹlẹ̀, ohun tí wọ́n ní kó ṣe ni pé kó fi agbára tí Ọlọ́run fún un dárúkọ ẹni tó lù ú.Lúùkù 22:63, 64.

^ ìpínrọ̀ 7 Nínú àpẹẹrẹ yìí, ó lè kọ́kọ́ fẹ́ dà bíi pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló ń bá Mósè sọ̀rọ̀, àmọ́ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn áńgẹ́lì ni Ọlọ́run lò láti fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní májẹ̀mú Òfin Mósè.Ìṣe 7:53; Gálátíà 3:19.