Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ṣé Ọgbọ́n Èèyàn Ni Wọ́n Fi Kọ Bíbélì?

Ṣé Ọgbọ́n Èèyàn Ni Wọ́n Fi Kọ Bíbélì?

Ohun tí Bíbélì sọ

Bíbélì, tá a tún máa ń pè ní Ìwé Mímọ́, ní ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n nínú. Àmọ́, gbọ́ ohun tí Bíbélì fúnra rẹ̀ sọ: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí.” (2 Tímótì 3:16) Ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló ti ọ̀rọ̀ yẹn lẹ́yìn. Gbé àwọn kókó yìí yẹ̀ wò:

  • Kò sẹ́nì kankan tó lè fọwọ́ sọ̀yà pé àwọn ìtàn tó wà nínú Bíbélì kì í ṣe òótọ́.

  • Olóòótọ́ èèyàn ni àwọn tó kọ Bíbélì, bọ́rọ̀ sì ṣe rí gẹ́lẹ́ ni wọ́n kọ ọ́. Bí wọ́n ṣe jẹ́ olóòótọ́ mú ká gbà pé òótọ́ ni ohun tí wọ́n kọ.

  • Ohun kan ṣoṣo ni Bíbélì dá lé, ohun náà sì ni: bí Ọlọ́run ṣe máa lo Ìjọba rẹ̀ ọ̀run láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ àti láti dá ara rẹ̀ láre pé òun nìkan ṣoṣo ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso àwọn èèyàn.

  • Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn ni wọ́n kọ Bíbélì, síbẹ̀ ohun tó sọ nípa sáyẹ́ǹsì péye, kò fara mọ́ èrò tí kò tọ̀nà táwọn èèyàn ní nígbà yẹn.

  • Àwọn ohun tí ìtàn tó wà lákọsílẹ̀ sọ fi hàn pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ lóòótọ́.