Ohun tí Bíbélì sọ

Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó sún mọ́ bèbè ikú ló sọ pé ẹ̀mí àwọn jáde lára àwọn tàbí pé àwọn rí ìmọ́lẹ̀ tó mọ́lẹ̀ yòò tàbí ibì kan tó lẹ́wà gan-an. Ìwé Recollections of Death sọ pé: ‘Àwọn èèyàn kan gbà pé ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn yìí fún àwọn ní àǹfààní láti mọ bí nǹkan ṣe rí ní ibòmíì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kò mẹ́nu kan ẹnì kankan tí irú èyí ṣẹlẹ̀ sí, síbẹ̀ àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì fi hàn pé kì í ṣe ìran ayé míì ni àwọn tó sún mọ́ bèbè ikú rí.

Àwọn òkú kò mọ nǹkan kan.

Bíbélì sọ pé àwọn òkú “kò mọ nǹkan kan rárá.” (Oníwàásù 9:5) Téèyàn bá ti kú, ó ti dí aláìsí nìyẹn kì í ṣe pé ẹni náà lọ sí ibì kan tó yàtọ̀ sí ibi tó wà tẹ́lẹ̀. Bíbélì kò kọ́ wa pé ẹ̀mí èèyàn kì í kú. (Ìsíkíẹ́lì 18:4) Torí náà, kì í ṣe bí ọ̀run ṣe rí tàbí bí ọ̀run àpáàdì ṣe rí ni ẹni tó sún mọ́ bèbè ikú rí.

Kí ni Lásárù sọ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i nígbà tó kú?

Ìtàn Lásárù tó wà nínú Bíbélì fi hàn pé Lásárù kù ní ti gidi. Jésù ló jí i dìde lẹ́yìn ọjọ́ kẹrin tó kú. (Jòhánù 11:38-44) Tó bá jẹ́ pé Lásárù wà níbì kan tó ń gbádùn níbẹ̀, a jẹ́ pé ìwà ìkà ni Jésù hù nígbà tó jí i sáyé. Àmọ́, Bíbélì kò sọ pé Lásárù ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i nígbà tó kú. Ó dájú pé Lásárù ò bá ti ṣàlàyé ohun tí ojú rẹ̀ rí nígbà tó kú, tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí i. Ohun pàtàkì kan ni pé, Jésù fi ikú Lásárù wé oorun, tó fi hàn pé Lásárù kò mọ ohunkóhun rárá nígbà tó kú.Jòhánù 11:11-14.