Ohun tí Bíbélì sọ

Orúkọ kan péré ni Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ń jẹ́. Tí wọ́n bá fẹ́ kọ orúkọ náà lédè Hébérù, יהוה ni wọ́n máa ń kọ, “Jèhófà” sì ni wọ́n sábà máa ń kọ lédè Yorùbá. * Ọlọ́run gbẹnu Aísáyà tó jẹ́ wòlíì rẹ̀ sọ̀rọ̀, ó ní: “Èmi ni Jèhófà. Èyí ni orúkọ mi.” (Aísáyà 42:8) Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje [7,000] ìgbà ni orúkọ yìí fara hàn nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ ti Bíbélì, kò sí ọ̀rọ̀ míì tó ń tọ́ka sí Ọlọ́run tàbí orúkọ tí ẹlòmíì ń jẹ́ tó pọ̀ tó báyìí nínú Bíbélì. *

Ṣé Jèhófà ní àwọn orúkọ míì?

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé orúkọ kan ṣoṣo ni Bíbélì fi pe Ọlọ́run, ó pè é ní ọ̀pọ̀ orúkọ oyè. Díẹ̀ lára àwọn orúkọ oyè yẹn ló wà nísàlẹ̀ yìí, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn jẹ́ ká mọ ohun kan nípa Jèhófà àti irú ẹni tó jẹ́.

Orúkọ Oyè

Ẹsẹ Bíbélì

Ìtumọ̀

Allah

(Kò sí)

Èdè Lárúbáwá ni “Allah.” Ìtumọ̀ rẹ̀ ni “Ọlọ́run,” torí náà, kì í ṣe orúkọ ẹnì kan, orúkọ oyè ni. Àwọn Bíbélì tí wọ́n túmọ̀ sí èdè Lárúbáwá àtàwọn èdè míì lo “Allah” níbi tí ọ̀rọ̀ náà, “Ọlọ́run” ti fara hàn.

Olódùmarè

Jẹ́nẹ́sísì 17:1

Agbára rẹ̀ ò láàlà. Ẹ̀ẹ̀méje ni ọ̀rọ̀ Hébérù náà, ʼEl Shad·daiʹ, tó túmọ̀ sí “Ọlọ́run Olódùmarè,” fara hàn nínú Bíbélì.

Ááfà àti Ómégà

Ìṣípayá 1:8; 21:6; 22:13

“Ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìkẹyìn,” tàbí “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ àti òpin,” ó túmọ̀ sí pé kò sí Ọlọ́run Olódùmarè kankan ṣáájú Jèhófà, kò sì ní sí ẹlòmíì lẹ́yìn rẹ̀. (Aísáyà 43:10) Ááfà ni lẹ́tà àkọ́kọ́, Ómégà sì ni lẹ́tà tó gbẹ̀yìn nínú àwọn álífábẹ́ẹ̀tì èdè Gíríìkì.

Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé

Dáníẹ́lì 7:​9, 13, 22

Kò níbẹ̀rẹ̀; láti ayérayé ló ti wà, kí ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun tó wà.​—Sáàmù 90:2.

Ẹlẹ́dàá

Aísáyà 40:28

Òun ló mú kí gbogbo nǹkan wà.

Baba

Mátíù 6:9

Òun ló fún wa ní ìyè.

Ọlọ́run

Jẹ́nẹ́sísì 1:1

Ẹni tá a lè jọ́sìn; Ẹni tó lágbára. Wọ́n máa ń lo ọ̀rọ̀ Hébérù náà, ʼElo·himʹ fún ohun tó ju ẹyọ kan lọ, ìyẹn fi hàn pé Jèhófà ní ọlá, iyì, ó sì tóbi lọ́ba.

Ọlọ́run àwọn ọlọ́run

Diutarónómì 10:17

Òun ni Ọlọ́run gíga jù lọ, ó yàtọ̀ sí “àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí” táwọn kan ń sìn.​—Aísáyà 2:8.

Olùkọ́ni Atóbilọ́lá

Aísáyà 30:20, 21

Ó ń tọ́ wa sọ́nà, ó sì ń kọ́ wa lóhun tó ń ṣe wá láǹfààní.​—Aísáyà 48:17, 18.

Olùṣẹ̀dá Atóbilọ́lá

Sáàmù 149:2

Òun ló mú kí gbogbo nǹkan wà.​—Ìṣípayá 4:​11.

Ọlọ́run aláyọ̀

1 Tímótì 1:​11

Inú rẹ̀ máa ń dùn, ó sì máa ń láyọ̀.​—Sáàmù 104:31.

Olùgbọ́ àdúrà

Sáàmù 65:2

Ó ń tẹ́tí gbọ́ àdúrà tí ẹnikẹ́ni tó nígbàgbọ́ bá gbà sí i.

Èmi Ni Ó Ń Jẹ́ Èmi Ni

Ẹ́kísódù 3:​14, Bíbélì Mímọ́

Ó máa ń di ohunkóhun kó bàa lè ṣe ohun tó ní lọ́kàn. Àwọn Bíbélì kan tún túmọ̀ ọ̀rọ̀ yìí sí “Èmi Yóò Di ohunkóhun tó bá wù mí” tàbí “Èmi Yóò Jẹ́ Ohun tí Èmi Yóò Jẹ́.” (The Emphasised Bible, ti J. B. Rotherham; Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun) Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ká mọ ìtumọ̀ orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́, ìyẹn Jèhófà, bó ṣe wà nínú ẹsẹ tó kàn.​—Ẹ́kísódù 3:​15.

Owú

Ẹ́kísódù 34:14, Bibeli Ìròyìn Ayọ̀

Kì í gbà kí ẹlòmíì gba ìjọsìn tó tọ́ sí i. Àwọn Bíbélì míì tún túmọ̀ ọ̀rọ̀ yìí sí “kì í gbà kí a bá òun díje” àti pé òun nìkan ló fẹ́ kí a máa jọ́sìn.​—God’s Word Bible; Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì.

Ọba ayérayé

Ìṣípayá 15:3

Àkóso rẹ̀ ò ní ìbẹ̀rẹ̀, kò sì lópin.

Olúwa

Sáàmù 135:5

Olówó ẹni tàbí ọ̀gá; lédè Hébérù, ʼA·dhohnʹ àti ʼAdho·nimʹ.

Olúwa àwọn ọmọ ogun, Olúwa Sábáótì

Aísáyà 1:9, Bíbélì Mímọ́; Róòmù 9:​29, Bíbélì King James Version

Olórí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọmọ ogun tí wọ́n jẹ́ áńgẹ́lì. A tún lè pe “Olúwa Sábáótì” ní “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun” àti “Olúwa àwọn ọmọ ogun [ọ̀run].”​—Róòmù 9:​29, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun; Bibeli Yoruba Atọ́ka.

Ẹni Gíga Jù Lọ

Sáàmù 47:2

Òun ni ẹni tó ga jù láyé àtọ̀run.

Ẹni Mímọ́ Jù Lọ

Òwe 9:​10

Ó mọ́ ju ẹnikẹ́ni lọ (oníwà mímọ́ ni).

Amọ̀kòkò

Aísáyà 64:8

Ó láṣẹ lórí ẹnì kọ̀ọ̀kan àtàwọn orílẹ̀-èdè, bí amọ̀kòkò ṣe lè fi amọ̀ ṣe ohun tó bá wù ú.​—Róòmù 9:​20, 21.

Olùràpadà, Olùtúnnirà

Aísáyà 41:14; Bíbélì Mímọ́

Ó fi ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi ra aráyé pa dà kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.​—Jòhánù 3:​16.

Àpáta

Sáàmù 18:​2, 46

Ibi ààbò àti orísun ìgbàlà.

Olùgbàlà

Aísáyà 45:21

Ó ń gbani lọ́wọ́ ewu tàbí ìparun.

Olùṣọ́ Àgùntàn

Sáàmù 23:1

Ó ń bójú tó àwọn tó ń sìn ín.

Olúwa Ọba Aláṣẹ

Jẹ́nẹ́sísì 15:2

Òun ni àṣẹ rẹ̀ ga jù lọ; Lédè Hébérù, ʼAdho·naiʹ.

Onípò Àjùlọ

Dáníẹ́lì 7:​18, 27

Òun ni ipò rẹ̀ ga jù lọ.

Orúkọ àwọn ibì kan nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù

Orúkọ Ọlọ́run wà nínú orúkọ àwọn ibì kan tó wà nínú Bíbélì, àmọ́ orúkọ àwọn ibí yìí kì í ṣe orúkọ Ọlọ́run.

Orúkọ ibẹ̀

Ẹsẹ Bíbélì

Ìtumọ̀

Jèhófá-jirè

Jẹ́nẹ́sísì 22:13, 14

“Jèhófà Máa Pèsè.”

Jèhófá-nisì

Ẹ́kísódù 17:15

“Jèhófà Ni Òpó Àmì Mi,” tàbí “Àsíá mi.” (Bíbélì Today’s New International Version) Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run tí àwọn tó ń sìn ín lè wá bá pé kó ran àwọn lọ́wọ́, kó sì dáàbò bò wọ́n.​—Ẹ́kísódù 17:13-​16.

Jehofa-ṣálómù

Onídàájọ́ 6:​23, 24

“Jèhófà Jẹ́ Àlàáfíà.”

Jèhófá-ṣamà

Ìsíkíẹ́lì 48:35, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, Bíbélì American Standard Version

‘Jèhófà Wà Níbẹ̀.’

Ìdí tó fi yẹ ká mọ orúkọ Ọlọ́run, ká sì máa lò ó

  • Ó ní láti jẹ́ pé Ọlọ́run rí i pé orúkọ òun, tó ń jẹ́ Jèhófà, ṣe pàtàkì torí pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìgbà ló jẹ́ kí orúkọ náà wà nínú Bíbélì.​—Málákì 1:​11.

  • Léraléra ni Jésù, ọmọ Ọlọ́run, tẹnu mọ́ bí orúkọ Ọlọ́run ṣe ṣe pàtàkì tó. Bí àpẹẹrẹ, ó gbàdúrà sí Jèhófà pé: “Kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.”​—Mátíù 6:9; Jòhánù 17:6.

  • Àwọn tó wá mọ orúkọ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń lò ó ń fi hàn pé àwọn fẹ́ di ọ̀rẹ́ Jèhófà. (Sáàmù 9:​10; Málákì 3:​16) Tí wọ́n bá ti di ọ̀rẹ́ rẹ̀, ìlérí tí Ọlọ́run ṣe máa ṣẹ sí wọn lára, pé: “Nítorí pé òun darí ìfẹ́ni rẹ̀ sí mi, èmi pẹ̀lú yóò pèsè àsálà fún un. Èmi yóò dáàbò bò ó nítorí pé ó ti wá mọ orúkọ mi.”​Sáàmù 91:14.

  • Bíbélì sọ pé: “Àwọn tí a ń pè ní ‘ọlọ́run’ wà, yálà ní ọ̀run tàbí lórí ilẹ̀ ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ ‘ọlọ́run’ àti ọ̀pọ̀ ‘olúwa’ ti wà.” (1 Kọ́ríńtì 8:​5, 6) Síbẹ̀, ó jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo ló wà, ó sì sọ orúkọ rẹ̀, ìyẹn Jèhófà.​—Sáàmù 83:18.

^ ìpínrọ̀ 3 Àwọn Hébérù kan tí wọ́n jẹ́ ọ̀mọ̀wé fara mọ́ kí wọ́n máa kọ orúkọ Ọlọ́run báyìí, “Yahweh”.

^ ìpínrọ̀ 3 “Jáà,” tó jẹ́ ìkékúrú orúkọ Ọlọ́run, fara hàn ní nǹkan bí àádọ́ta [50] ìgbà nínú Bíbélì, títí kan bí wọ́n ṣe lò ó nínú ọ̀rọ̀ náà, “Halelúyà,” tàbí “Alelúyà,” tó túmọ̀ sí “Ẹ yin Jáà.”​—Ìṣípayá 19:1; Bibeli Ìròyìn Ayọ̀; Bíbélì Mímọ́.