Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Kí Nìdí Tí Onírúurú Ẹ̀sìn Kristẹni Fi Wà?

Kí Nìdí Tí Onírúurú Ẹ̀sìn Kristẹni Fi Wà?

Ohun tí Bíbélì sọ

Àwọn èèyàn ti fi àwọn ẹ̀kọ́ Jésù Kristi dá onírúurú ẹ̀sìn “Kristẹni” sílẹ̀. Àmọ́, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìsìn Kristẹni tòótọ́ kan ṣoṣo ló wà. Ẹ jẹ́ ká wo ìdí mẹ́ta tí Bíbélì fi sọ bẹ́ẹ̀.

  1. Jésù sọ pé “òtítọ́,” ni òun fi kọ́ni. Torí náà, àwọn tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ẹ̀sìn Kristẹni gbà pé ìsìn “òtítọ́” làwọn ṣe. (Jòhánù 8:32; 2 Pétérù 2:2; 2 Jòhánù 4; 3 Jòhánù 3) Èyí túmọ̀ sí pé àwọn tó bá ń fi ohun tó ta ko ẹ̀kọ́ Jésù kọ́ni kì í ṣe Kristẹni tòótọ́.

  2. Bíbélì kọ́ni pé kí gbogbo Kristẹni “máa sọ̀rọ̀ ní ìfohùnṣọ̀kan.” (1 Kọ́ríńtì 1:10) Àwọn tó ń ṣe onírúurú ẹ̀sìn Kristẹni kò fohùn ṣọ̀kan lórí àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì, wọn ò sì mọ ohun tó túmọ̀ sí láti jẹ́ Kristẹni. Àmọ́ ìsìn tòótọ́ kan ṣoṣo ló wà.1 Pétérù 2:21.

  3. Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé òun á kọ àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní Kristẹni àmọ́ tí wọn kò pa àwọn òfin òun mọ́. (Mátíù 7:21-23; Lúùkù 6:46) Ọ̀pọ̀ èèyàn ni àwọn aṣáájú ìsìn tó fẹ́ sọ ìsìn tòótọ́ di ìdàkudà máa ṣì lọ́nà torí àǹfààní ara wọn. (Mátíù 7:15) Àmọ́, àwọn míì máa fara mọ ẹ̀sìn àwọn tó kàn pe ara wọn ní Kristẹni torí pé ohun tí wọ́n fẹ́ gbọ́ ni wọ́n ń sọ fún wọn dípò kí wọ́n kọ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́ Bíbélì.2 Tímótì 4:3, 4.

Nínú àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa àlìkámà àti èpò, ó sọ tẹ́lẹ̀ pé ìpẹ̀yìndà ńlá kan (àwọn apẹ̀yìndà) máa wáyé, àwọn kan á gbógun ti ìsìn tòótọ́. (Mátíù 13:24-30, 36-43) Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún la ò fi dá ìsìn tòótọ́ mọ̀ yàtọ̀ sí ìsìn èké. Gẹ́lẹ́ bí Jésù ṣe sọ tẹ́lẹ̀, àwọn apẹ̀yìndà wá gbalẹ̀ gbòde lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì. (Ìṣe 20:29, 30) Bí àwọn apẹ̀yìndà ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn láwọn ẹ̀kọ́ tó ta kora, bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo àwọn tó pe ara wọn ni Kristẹni “yapa kúrò nínú òtítọ́.”2 Tímótì 2:18.

Jésù tún sọ tẹ́lẹ̀ pé tó bá yá ìyàtọ̀ tó ṣe kedere máa wà láàárín àwọn Kristẹni tòótọ́ àti àwọn Kristẹni èké. Àkókò tá a wà yìí ni ohun tí Jésù sọ ṣẹ, ìyẹn ìgbà “ìparí ètò àwọn nǹkan.”Mátíù 13:30, 39.