Ohun tí Bíbélì sọ

Rárá o. Ọ̀rọ̀ náà, “àtúnwáyé” tàbí ohun tó jẹ mọ́ ọn ò sí nínú Bíbélì rárá. Ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn ló mú káwọn èèyàn gbà pé èèyàn máa ń tún ayé wá. * Àmọ́, Bíbélì fi kọ́ni pé odindi èèyàn kan ni ọkàn kan, torí náà, ọkàn lè kú. (Jẹ́nẹ́sísì 2:7; Ìsíkíẹ́lì 18:4) Téèyàn bá ti kú, ẹni náà ò sí mọ́ nìyẹn.Jẹ́nẹ́sísì 3:19; Oníwàásù 9:5, 6.

Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín àtúnwáyé àti àjíǹde?

Kì í ṣe àìleèkú ọkàn ni Bíbélì fi ń kọ́ni nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde. Tó bá dìgbà àjíǹde, Ọlọ́run máa fi agbára rẹ̀ mú kí àwọn tó ti kú tún wà láàyè. (Mátíù 22:23, 29; Ìṣe 24:15) Ìlérí àjíǹde jẹ́ ká nírètí pé àwọn tó ti kú máa pa dà wá sínú ayé tuntun, wọn ò sì ní kú mọ́.2 Pétérù 3:13; Ìṣípayá 21:3, 4.

Èrò tí kò tọ́ táwọn èèyàn ní pé ọ̀rọ̀ àtúnwáyé wà nínú Bíbélì

Èrò tí kò tọ́: Bíbélì sọ pé ìgbà tí wòlíì Èlíjà tún ayé wá ló di Jòhánù Arinibọmi.

Òótọ́: Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Èmi yóò rán Èlíjà wòlíì sí yín,” Jésù sì sọ pé Jòhánù Arinibọmi ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ sí. (Málákì 4:5, 6; Mátíù 11:13, 14) Àmọ́ èyí ò túmọ̀ sí pé Èlíjà tún ayé wá, ó wá di Jòhánù Arinibọmi. Jòhánù fúnra rẹ̀ sọ pé òun kọ́ ni Èlíjà. (Jòhánù 1:21) Kàkà bẹ́ẹ̀, Jòhánù ṣe iṣẹ́ tó jọ ti Èlíjà, ó kéde iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an pé kí àwọn èèyàn ronú pìwà dà. (1 Àwọn Ọba 18:36, 37; Mátíù 3:1) Jòhánù tún “jẹ́ akin, ó sì lágbára bíi ti wòlíì Èlíjà.”Lúùkù 1:13-17, Bíbélì Good News Translation.

Èrò tí kò tọ́: Bíbélì sọ pé “àtúnbí” ni ẹni tó bá tún ayé wá.

Òótọ́: Bíbélì fi hàn pé ìgbà tẹ́nì kan bá wà láàyè ló máa ń di àtúnbí, kì í ṣe ìgbà tó bá kú. (Jòhánù 1:12, 13) Kì í ṣe ohun tí ẹni náà ti ṣe sílẹ̀ ló sọ ọ́ di àtúnbí, ìbùkún látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló jẹ́, Ọlọ́run sì ń mú kí àwọn tó bá sọ di àtúnbí ní ìrètí ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn.Jòhánù 3:3; 1 Pétérù 1:3, 4.

^ ìpínrọ̀ 3 Ìlú Bábílónì àtijọ́ ni ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn àti àtúnwáyé ti ṣẹ̀ wá. Nígbà tó yá, àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí nílẹ̀ Íńdíà gbé òfin Kámà kalẹ̀. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Britannica Encyclopedia of World Religions sọ pé ohun tí òfin Kámà túmọ̀ sí ni “àṣesílẹ̀-làbọ̀wábá, ìyẹn ni pé téèyàn bá ṣe ohun kan nígbà tó wà láyé báyìí, ó máa jìyà rẹ̀ tó bá tún ayé wá.”—Ojú ìwé 913.