Ohun Tí Bíbélì Sọ

Bíbélì kò sọ pé Ọlọ́run ló ń fa àwọn àjálù tó ń ṣẹlẹ̀ láyé lónìí. Àwọn ìdájọ́ Ọlọ́run tí Bíbélì sọ̀rọ̀ rẹ̀ yàtọ̀ sí àwọn àjálù.

  1. Ọlọ́run mọ àwọn èèyàn burúkú. Bíbélì sọ pé: “Ènìyàn . . . ń wo ohun tí ó fara hàn sí ojú; ṣùgbọ́n ní ti Jèhófà, ó ń wo ohun tí ọkàn-àyà jẹ́.”—1 Sámúẹ́lì 16:7.

  2. Jèhófà máa ń wo ọkàn ẹnì kọ̀ọ̀kan, àwọn tó bá sì rí i pé wọ́n jẹ́ ẹni burúkú nìkan ló máa ń pa.—Jẹ́nẹ́sísì 18:23-32.

  3. Ọlọ́run máa ń kìlọ̀ ṣáájú, ìyẹn sì ń jẹ́ kí àwọn tó bá ṣègbọràn sí i bọ́ lọ́wọ́ ìyà.

Àmọ́ àjálù kì í kìlọ̀ fún ẹnikẹ́ni, kò sì sí ẹni tí kò lè pa tàbí ṣe lọ́ṣẹ́. Dé ìwọ̀n àyè kan, àwọn èèyàn ló máa ń mú kí àjálù tó ń ṣẹlẹ̀ burú sí i, torí wọ́n ń ba àyíká jẹ́, wọ́n ń kọ́lé síbi tí ìmìtìtì ilẹ̀ wọ́pọ̀ sí àti ibi tí omi ti lè tètè yalé àtàwọn ibi tí ojú ọjọ́ kò ti dára.