Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ǹjẹ́ Bíbélì Sọ̀rọ̀ nípa Ìṣẹ́yún?

Ǹjẹ́ Bíbélì Sọ̀rọ̀ nípa Ìṣẹ́yún?

Ohun tí Bíbélì sọ

Ohun mímọ́ ni ẹ̀mí èèyàn jẹ́ lójú Ọlọ́run, ó sì gbà pé èèyàn ni ọlẹ̀ tó wà nínú ilé ọmọ. Nípasẹ̀ ìmísí, Dáfídì Ọba sọ nípa Ọlọ́run pé: “Àní ojú rẹ rí ọlẹ̀ mi.” (Sáàmù 139:16) Ọlọ́run sọ pé òun á fìyà jẹ ẹni tó bá ṣe oyún léṣe. Nítorí náà, lójú Ọlọ́run, ẹní tó bá pa ọmọ inú jẹ̀bi ìpànìyàn.—Ẹ́kísódù 20:13; 21:22, 23.

Nígbà tí ìyá bá fẹ́ bímọ tí ẹ̀mí ìyá àti tọmọ bá wà nínú ewu, tí wọ́n sì gbọ́dọ̀ gba ẹ̀mí ẹnì kan ṣoṣo là, ṣé ọmọ ni kí wọ́n gba ẹ̀mí ẹ̀ là ni àbí ìyá rẹ̀? Nínú ọ̀ràn yìí, tọkọtaya náà ló máa pinnu ẹni tí wọ́n fẹ́ kí wọ́n gba ẹ̀mí rẹ̀ là.