Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Bí Ọkùnrin àti Obìnrin Kan Bá Fẹ́ràn Ara Wọn, Ṣé Ó Yẹ Kí Wọ́n Máa Gbé Pa Pọ̀ Láì Ṣègbéyàwó?

Bí Ọkùnrin àti Obìnrin Kan Bá Fẹ́ràn Ara Wọn, Ṣé Ó Yẹ Kí Wọ́n Máa Gbé Pa Pọ̀ Láì Ṣègbéyàwó?

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ohun tí Bíbélì sọ ṣe kedere, ó ní “Ọlọ́run yóò dá àwọn àgbèrè . . . lẹ́jọ́.” (Hébérù 13:4) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà por·nei′a tí ó túmọ̀ sí “àgbèrè,” tún kan ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó. Nítorí náà, lójú Ọlọ́run kò tọ̀nà kí ọkùnrin àti obìnrin tí kò ṣègbéyàwó máa gbé pa pọ̀, kódà bí wọn bá rò pé àwọn ṣì máa ṣègbéyàwó.

Bí àwọn méjèèjì bá fẹ́ràn ara wọn gan-an ńkọ́? Ọlọ́run ṣì pàṣẹ pé wọn kò gbọ́dọ̀ ní ìbálòpọ̀ kí wọ́n tó ṣègbéyàwó. Ọlọ́run ló dá wa ká lè máa ní ìfẹ́ ara wa. Ìfẹ́ ló gbawájú lára ohun tí Ọlọ́run fi ń ṣèwàhù. (1 Jòhánù 4:8) Nítorí náà, ọ̀rọ̀ wa jẹ Ọlọ́run lógún gan-an ló fi sọ pé ọkùnrin àti obìnrin tó ti ṣègbéyàwó nìkan ló lè ní ìbálòpọ̀.